ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 28
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2015 | September
    • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 28

      Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 28

      Orin 73 àti Àdúrà

      Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

      cl orí 31 ìpínrọ̀ 1 sí 12 (30 min.)

      Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

      Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 23-25 (8 min.)

      No. 1: 2 Àwọn Ọba 23:​8-15 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

      No. 2: Ibo Ni Èṣù Ti Wá?​—wp13 2/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)

      No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Yẹra fún “Ìṣègbè”?​—Ják. 2:​1-4 (5 min.)

      Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

      ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”​—Ìṣe 20:24.

      Orin 93

      10 min: Pọ́ọ̀lù Àtàwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Rẹ̀ Jẹ́rìí Kúnnákúnná ní Ìlú Fílípì. Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 16:​11-15. Ẹ jíròrò bí ìtàn yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

      20 min: “Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn tó ti múra sílẹ̀ dáadáa. Akéde náà ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọ ẹnì kan, ó sì jíròrò ìpínrọ̀ kan pẹ̀lú ẹni náà.

      Orin 114 àti Àdúrà

  • Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2015 | September
    • 1. Báwo la ṣe ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀?

      1 Bá a ṣe sọ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù July, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ni ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! A kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe àyọkà àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìwé yìí torí kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè rí i pé inú Bíbélì ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ti wá ní tààràtà. Ọ̀pọ̀ ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ la ṣe lọ́nà tí àwọn tó ń kà á fi lè lóye rẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Àmọ́, a ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwa la máa fi kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fún àwọn èèyàn ní ìwé yìí, ó yẹ ká fi bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ han ẹni tá a bá fún lọ́nà táá fi máa wù ú láti mọ ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì.​—Mát. 13:44.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́