ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 6 ojú ìwé 9
  • Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 6 ojú ìwé 9

Ẹ̀KỌ́ 6

Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Jòhánù 10:33-36

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Má kàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan kó o sì bọ́ sórí kókó ọ̀rọ̀ míì. Jẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i kedere bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà ṣe bá kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tán, tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ tó bá kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ mu. Lára ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o tún àwọn ọ̀rọ̀ yẹn pè tàbí kó o béèrè ìbéèrè kan tó máa jẹ́ káwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ dá àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ mọ̀.

    Àwọn àbá

    Tó o bá lo ọ̀rọ̀ míì láti ṣàlàyé kókó pàtàkì tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, rí i dájú pé àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ṣì rí i kedere bí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe tan mọ́ ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí.

  • Tẹnu mọ́ kókó pàtàkì. Tó o bá pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, tó o sì ti sọ ìdí tó o fi fẹ́ kà á, ṣàlàyé bí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe bá ohun tó o sọ yẹn mu.

    Àwọn àbá

    Ṣí Bíbélì rẹ sílẹ̀ bó o ṣe ń ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Èyí á jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè rí i pé ẹsẹ Bíbélì tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán náà lò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

  • Má ṣe àlàyé tí kò pọn dandan. Má ṣe àlàyé tí kò tan mọ́ kókó pàtàkì tí ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kọ́kọ́ ronú nípa ohun tí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yẹn àti bí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó, lẹ́yìn náà kó o wá pinnu bó ṣe yẹ kí àlàyé rẹ pọ̀ tó kí ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí tó lè yé wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́