Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MARCH 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 16-17
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 714
Ẹyinjú
Tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʼi·shohnʹ (Di 32:10; Owe 7:2), àti ʽaʹyin (ojú) pa pọ̀, ohun tó túmọ̀ sí ní tààràtà ni “ọkùnrin kékeré inú ojú.” Bákan náà, ọ̀rọ̀ náà bath (ọmọbìnrin) tí wọ́n lò nínú Ìdárò 2:18 túmọ̀ sí “ọmọbìnrin inú ojú.” Ohun tí ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni ẹyinjú. Sáàmù 17:8 lo ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí pa pọ̀ (ʼi·shohnʹ bath-ʽaʹyin) kó lè fi tẹnu mọ́ kókó tó wà níbẹ̀, ohun tí gbólóhùn yìí sì túmọ̀ sí ní tààràtà ni “ọkùnrin kékeré àti ọmọbìnrin inú ojú” (ìyẹn ẹyinjú tàbí “ọmọlójú,” NW). Ohun tó bí ọ̀rọ̀ yìí ni pé, tá a bá ń wo inú ẹyinjú ẹlòmíì, ìrísí wa máa ń kékeré gan-an.
Ẹyinjú gbẹgẹ́ gan-an, kódà tí irun kékeré tàbí ìdọ̀tí bíńtín bá gbọ̀n sí i, àá mọ̀ ọ́n lára. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa tọjú ẹyinjú wa dáadáa, ká sì máa dáàbò bò ó, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, tí ìdọ̀tí bá ń gbọ̀n sí i, ọjú náà lè má ríran dáadáa mọ́ tàbí kó fọ́ pátápátá. Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ẹyinjú tàbí “ọmọlójú” láti ṣàpẹẹrẹ ohun tó yẹ kéèyàn tọ́jú kó sì dáàbò bò. Bó ṣe yẹ ká ka òfin Ọlọ́run sí pàtàkì nìyẹn. (Owe 7:2) Nígbà tí Diutarónómì 32:10 ń sọ bí Jèhófà ṣe ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ̀ pé ó dáàbò bò wọ́n “bí ọmọlójú rẹ̀.” Dáfídì náà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dáàbò bo òun, kó sì tọ́jú òun ‘bí ọmọlójú rẹ̀.’ (Sm 17:8) Ó fẹ́ kí Jèhófà tètè gba òun sílẹ̀ nígbà táwọn ọ̀tá bá gbéjà ko òun. (Fi wé Sek 2:8; níbi tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ba·vathʹ ʽaʹyin, ìyẹn “ẹyinjú.”)—Wo OJÚ.
MARCH 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 18
“Jèhófà Ni . . . Ẹni Tó Ń Gbà Mí Sílẹ̀”
it-2 1161 ¶7
Ohùn
Ọlọ́run máa ń gbọ́ ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó dá àwọn tó ń sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́ lójú pé táwọn bá ké pe Ọlọ́run, á gbọ́ àwọn láìka èdè yòówù káwọn sọ sí. Bákan náà, tẹ́nì kan bá ń gbàdúrà tí ò sì sọ̀rọ̀ síta, Ọlọ́run tó jẹ́ ọba arínúróde máa “gbọ́,” á sì dáhùn. (Sm 66:19; 86:6; 116:1; 1Sa 1:13; Ne 2:4) Ọlọ́run tún máa ń gbọ́ táwọn tí wọ́n ń ni lára bá ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún máa ń gbọ́ ohùn àwọn alátakò rẹ̀, ó sì mọ èrò ọkàn àwọn tó ń gbèrò ibi sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Jẹ 21:17; Sm 55:18, 19; 69:33; 94:9-11; Jer 23:25.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 432 ¶2
Kérúbù
Àwọn kan ronú pé ṣe làwọn kérúbù yìí dà bí àwọn ère tó ní ìyẹ́, tó sì ń banilẹ́rù táwọn abọ̀rìṣà máa ń jọ́sìn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn Júù àtijọ́ gbà pé àwọn kérúbù yìí rí bí èèyàn (Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa èyí). Iṣẹ́ ọ̀nà tó rẹwà gan-an ni wọ́n jẹ́, wọ́n sì ń ṣàpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì tó ń gbé ògo Jèhófà yọ. Kódà, wọ́n ‘rí bí ohun tí Jèhófà fi han Mósè gẹ́lẹ́.’ (Ẹk 25:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ pè wọ́n ní “àwọn kérúbù ológo tí wọ́n ṣíji bo ìbòrí ìpẹ̀tù.” (Heb 9:5) Àwọn kérúbù sábà máa ń wà níbi tí Jèhófà bá wà. Bíbélì sọ pé: “Màá pàdé rẹ níbẹ̀, màá sì bá ọ sọ̀rọ̀ látorí ìbòrí náà. Láti àárín àwọn kérúbù méjì tó wà lórí àpótí Ẹ̀rí náà.” (Ẹk 25:22; Nọ 7:89) Bíbélì tiẹ̀ sọ pé Jèhófà “jókòó lórí [tàbí wà láàárín] àwọn kérúbù.” (1Sa 4:4; 2Sa 6:2; 2Ọb 19:15; 1Kr 13:6; Sm 80:1; 99:1; Ais 37:16) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn kérúbù yìí ni “àwòrán kẹ̀kẹ́ ẹṣin” tí Jèhófà ń gùn (1Kr 28:18), ìyẹ́ wọn sì ń ṣàpẹẹrẹ ààbò àti ìyárakánkán. Abájọ tí Dáfídì fi sọ nínú orin kan tó fi ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń tètè ran òun lọ́wọ́ pé, ó wá bí ẹni tó “gun kérúbù, ó sì ń fò bọ̀ . . . lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.”—2Sa 22:11; Sm 18:10.
MARCH 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 19-21
“Àwọn Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run”
g95 11/8 7 ¶3
Oníṣẹ́ Àrà Táwọn Èèyàn Ò Kà Sí Rárá Lónìí
Tá a bá túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà dá tó yí wa ká, àá túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá wa dunjú. Ìgbà kan wà tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n kíyè sí àwọn òdòdó tó ń hù káàkiri Gálílì. Ó sọ pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú; àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí.” (Mátíù 6:28, 29) Tí Ọlọ́run bá lè mú kí òdòdó lílì lásánlásàn rẹwà tó báyìí, ó dájú pé á pèsè ohun táwa èèyàn nílò.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1073
Hébérù, Kejì
Wọ́n tún máa ń kọ ewì alápá méjì, ìyẹn sì máa ń ṣàrà ọ̀tọ̀. Dípò kí apá kejì ewì náà ṣe àtúnsọ ohun tó wà ní apá àkọ́kọ́ tàbí kó sọ ohun tó yàtọ̀ sí i, ṣe ni apá kejì máa gbé kókó míì jáde táá jẹ́ ká túbọ̀ lóye kókó àkọ́kọ́. Àpẹẹrẹ kan ni Sáàmù 19:7-9:
Òfin Jèhófà pé,
ó ń sọ agbára dọ̀tun.
Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,
ó ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.
Àwọn ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ òdodo,
wọ́n ń mú ọkàn yọ̀;
Àṣẹ Jèhófà mọ́,
ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.
Ìbẹ̀rù Jèhófà mọ́,
ó wà títí láé.
Àwọn ìdájọ́ Jèhófà jẹ́ òótọ́;
òdodo ni wọ́n látòkè délẹ̀.
Kíyè sí i pé apá kejì ewì náà ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye ti àkọ́kọ́, Nípa bẹ́ẹ̀, apá méjèèjì ewì náà gbe ara wọn, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ nítumọ̀. Àwọn apá kejì bí, “ó ń sọ agbára dọ̀tun” àti “ó ń sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n,” ló máa jẹ́ kí ẹni tó ń kà á lóye bí ‘òfin Jèhófà ṣe pé’ àti ìdí tí ‘ìránnilétí Jèhófà fi ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.’ Nínú irú àwọn ewì alápá méjì yìí, apá méjèèjì máa ń jẹ́ kẹ́ni tó ń kà á lè dánu dúró. Bá a bá ṣe ń ka ewì náà lọ, ó máa ṣe kedere pé akójọ ewì alápá méjì kọ̀ọ̀kan jọra.
APRIL 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 29-31
Jèhófà Máa Ń Bá Wa Wí Torí Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
it-1 802 ¶3
Ojú
Oríṣiríṣi ìtumọ̀ ni ọ̀rọ̀ náà ‘fi ojú pa mọ́’ ní, bí wọ́n bá ṣe lò ó ló máa pinnu ohun tó túmọ̀ sí. Tí Bíbélì bá sọ pé Jèhófà fi ọjú rẹ̀ pa mọ́, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kò fi ojúure hàn sẹ́nì kan mọ́ tàbí pé kò fàánú hàn sẹ́nì kan mọ́. Ohun tó máa ń mú kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ ni tí ẹni náà bá ń ṣàìgbọràn, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn. (Job 34:29; Sm 30:5-8; Ais 54:8; 59:2) Nígbà míì, ó lè túmọ̀ sí pé Jèhófà ò tíì fẹ́ gbé ìgbèsẹ̀ tàbí dá ẹnì kan lóhùn títí dìgbà tó máa tó àkókò lójú ẹ̀. (Sm 13:1-3) Nígbà tí Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó ‘gbé ojú rẹ̀ kúrò lára àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun,’ ohun tó ń sọ ni pé kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ òun ji òun.—Sm 51:9; fi wé Sm 10:11.