ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kó lè kọ́ wọn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀

      ORÍ 116

      Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn

      MÁTÍÙ 26:20 MÁÀKÙ 14:17 LÚÙKÙ 22:14-18 JÒHÁNÙ 13:1-17

      • JÉSÙ ÀTÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ JẸ ÌRÉKỌJÁ TÓ KẸ́YÌN

      • Ó KỌ́ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ LẸ́MÌÍ ÌRẸ̀LẸ̀ BÓ ṢE FỌ ẸSẸ̀ WỌN

      Pétérù àti Jòhánù ti dé Jerúsálẹ́mù bí Jésù ṣe sọ fún wọn, kí wọ́n lè ṣètò Ìrékọjá. Ìgbà tó yá ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù wá bá wọn níbẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀sán. Àmọ́, oòrùn ti ń rọjú díẹ̀díẹ̀ kí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó sọ̀ kalẹ̀ látorí Òkè Ólífì. Jésù ò sì pa dà síbẹ̀ mọ́ títí tó fi kú, àfìgbà tó jíǹde.

      Kò pẹ́ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi dé Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì forí lé ibi tí wọ́n ti fẹ́ jẹ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n gòkè lọ sí yàrá ńlá tó wà lókè. Wọ́n rí i pé gbogbo ètò ti tò fún wọn láti jẹun láwọn nìkan. Jésù ti ń fojú sọ́nà fún àsìkò yìí, torí ó sọ pé: “Ó wù mí gan-an pé kí n jẹ Ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà.”—Lúùkù 22:15.

      Ó pẹ́ tó ti jẹ́ àṣà àwọn Júù pé kí wọ́n máa gbé ife wáìnì láàárín ara wọn tí wọ́n bá ń jẹ Ìrékọjá. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ náà lọ́jọ́ yẹn, nígbà tí Jésù gba ife wáìnì kan, ó sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ gbé e yí ká láàárín ara yín, torí mò ń sọ fún yín, láti ìsinsìnyí lọ, mi ò tún ní mu àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́ títí Ìjọba Ọlọ́run fi máa dé.” (Lúùkù 22:17, 18) Ó dájú pé ọjọ́ ikú ẹ̀ ti sún mọ́lé.

      Bí wọ́n ṣe ń jẹ Ìrékọjá yẹn, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ṣẹlẹ̀. Jésù dìde, ó bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì mú aṣọ ìnura kan. Ó wá bu omi sínú abọ́ kan tó wà nítòsí. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà yẹn ni pé ẹni tó bá gbàlejò máa rán ìránṣẹ́ ẹ̀ pé kó fọ ẹsẹ̀ àwọn àlejò. (Lúùkù 7:44) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹni tó gbà wọ́n lálejò ò sí níbẹ̀, torí náà, Jésù ló ṣe iṣẹ́ yìí. Kò séyìí tí ò lè ṣiṣẹ́ yẹn nínú àwọn àpọ́sítélì, àmọ́ kò sẹ́ni tó dìde nínú wọn. Ṣé kì í ṣe torí pé wọ́n ṣì ní ara wọn sínú? Èyí ó wù kó jẹ́, ojú tì wọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí Jésù ń fọ ẹsẹ̀ wọn.

      Nígbà tí Jésù dé ọ̀dọ̀ Pétérù, kò fẹ́ gbà, ó ní: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù wá sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ, o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.” Ni Pétérù bá fi gbogbo ẹnu dáhùn pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” Àmọ́ ó yà á lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.”—Jòhánù 13:8-10.

      Gbogbo wọn ni Jésù fọ ẹsẹ̀ wọn, títí kan Júdásì Ìsìkáríọ́tù. Lẹ́yìn náà, Jésù wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ pa dà, ó sì jókòó sídìí tábìlì, ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn. Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín. Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:12-17.

      Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ fún wọn pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀! Wọ́n rí i pé kò yẹ káwọn máa wá ire ara wọn ṣáájú ti ẹlòmíì tàbí kí wọ́n ka ara wọn sí pàtàkì jù, kí wọ́n sì máa retí káwọn míì sìn wọ́n. Dípò ìyẹn, ṣe ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kì í ṣe pé kí wọ́n máa fọ ẹsẹ̀ àwọn èèyàn àmọ́ kí wọ́n ṣe tán láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ran àwọn míì lọ́wọ́, kí wọ́n má sì máa wo ojú kí wọ́n tó ṣe oore.

      • Nígbà Ìrékọjá yẹn, kí ni Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó fi hàn pé ọjọ́ ikú rẹ̀ ti sún mọ́lé?

      • Kí nìdí tó fi yani lẹ́nu pé Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?

      • Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà tó fọ ẹsẹ̀ wọn?

  • Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá

      ORÍ 117

      Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

      MÁTÍÙ 26:21-29 MÁÀKÙ 14:18-25 LÚÙKÙ 22:19-23 JÒHÁNÙ 13:18-30

      • Ọ̀DÀLẸ̀ NI JÚDÁSÌ

      • JÉSÙ DÁ OÚNJẸ ALẸ́ OLÚWA SÍLẸ̀

      Ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ṣáájú àsìkò yẹn ni Jésù ti kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó fọ ẹsẹ̀ wọn. Ní báyìí, bóyá lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Ìrékọjá tán, ó mẹ́nu ba àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Dáfídì sọ, ó ní: “Ẹni tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo fọkàn tán, ẹni tí a jọ ń jẹun, ti jìn mí lẹ́sẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”—Sáàmù 41:9; Jòhánù 13:18, 21.

      Làwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bá ń wo ara wọn, wọ́n sì ń bi í pé: “Olúwa, èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” Kódà Júdásì Ìsìkáríọ́tù náà béèrè. Torí pé Jòhánù ló jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù, Pétérù ní kí Jòhánù bi Jésù pé ta ló máa dà á. Jòhánù wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”—Mátíù 26:22; Jòhánù 13:25.

      Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.” Jésù wá mú búrẹ́dì nínú abọ́ tó wà lórí tábìlì, ó sì nà án sí Júdásì. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́ gbé! Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.” (Jòhánù 13:26; Mátíù 26:24) Ni Sátánì bá wọnú Júdásì. Ó ṣe tán, èrò burúkú ti wà lọ́kàn ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó wá túbọ̀ fi ara ẹ̀ fún Èṣù láti ṣe ohun tó fẹ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di “ọmọ ìparun.”—Jòhánù 6:64, 70; 12:4; 17:12.

      Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” Torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó máa ń wà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù rò pé ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé: “‘Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà’ tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan.” (Jòhánù 13:27-30) Àmọ́ ṣe ni Júdásì lọ wá bó ṣe máa da Jésù.

      Lálẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, Jésù dá ètò oúnjẹ alẹ́ tuntun kan sílẹ̀ bíi ti ayẹyẹ Ìrékọjá. Ó mú búrẹ́dì kan, ó gbàdúrà, ó bù ú, ó sì fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kí wọ́n jẹ ẹ́. Ó wá sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi, tí a máa fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Àwọn àpọ́sítélì yẹn gbé búrẹ́dì náà yí ká láàárín ara wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́.

      Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù mú ife wáìnì kan, ó gbàdúrà, ó sì gbé e fún wọn kí wọ́n gbé e yí ká láàárín ara wọn. Gbogbo wọn mu wáìnì náà, Jésù wá sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá, tí a máa dà jáde nítorí yín.”—Lúùkù 22:20.

      Ṣe ni Jésù fi ohun tó ṣe yẹn sọ báwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á ṣe máa rántí ikú rẹ̀ lọ́dọọdún ní Nísàn 14. Èyí á sì máa rán wọn létí ohun tí Jésù àti Baba rẹ̀ ṣe kí àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ohun tó ṣe yẹn ju ohun tí Ìrékọjá ṣe fáwọn Júù lọ, gbogbo èèyàn ló kàn, tí wọ́n bá ṣáà ti nígbàgbọ́ wọ́n máa gba òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

      Jésù sọ pé wọ́n ‘máa da ẹ̀jẹ̀ òun jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn, kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’ Àwọn àpọ́sítélì Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn èèyàn míì wà lára àwọn tó máa rí ìdáríjì gbà. Àwọn ló máa wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba Baba rẹ̀.—Mátíù 26:28, 29.

      • Àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì wo ni Jésù mẹ́nu bà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣàlàyé rẹ̀?

      • Kí ni Jésù sọ fún Júdásì pé kó ṣe, àmọ́ kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù rò pé ó ń sọ?

      • Ohun tuntun wo ni Jésù dá sílẹ̀, kí ni nǹkan náà sì wà fún?

  • Wọ́n Jiyàn Nípa Ẹni Tó Tóbi Jù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Àwọn àpọ́sítélì ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn

      ORÍ 118

      Wọ́n Jiyàn Nípa Ẹni Tó Tóbi Jù

      Mátíù 26:31-35 Máàkù 14:27-31 Lúùkù 22:24-38 Jòhánù 13:31-38

      • JÉSÙ FÚN ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀ NÍMỌ̀RÀN PÉ KÍ WỌ́N MÁ ṢE MÁA WÁ IPÒ ỌLÁ

      • JÉSÙ SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ PÉTÉRÙ MÁA SẸ́ ÒUN

      • ÌFẸ́ NI WỌ́N Á FI DÁ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ MỌ̀

      Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó fọ ẹsẹ̀ wọn. Ohun tó sọ yẹn bọ́ sákòókò gan-an ni. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó yẹ kí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe máa ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn ṣì ń jẹ wọ́n lọ́kàn. (Máàkù 9:33, 34; 10:35-37) Ọ̀rọ̀ yẹn tún fa wàhálà láàárín wọn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn.

      Àwọn àpọ́sítélì náà “bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tí wọ́n kà sí ẹni tó tóbi jù nínú wọn.” (Lúùkù 22:24) Ẹ wo bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe máa bá Jésù nígbà tó rí i tí wọ́n ń bá ara wọn jiyàn láìnídìí! Kí ni Jésù wá ṣe?

      Dípò kí Jésù láálí wọn, ṣe ló fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, wọ́n sì máa ń pe àwọn tó ní àṣẹ lórí wọn ní Olóore. Àmọ́ kò yẹ kí ẹ̀yin ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Torí ta ló tóbi jù, ṣé ẹni tó ń jẹun ni àbí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá?” Jésù wá rán wọn létí àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tó ti fi lẹ́lẹ̀ fún wọn, ó ní: “Àmọ́ mo wà láàárín yín bí ẹni tó ń gbé oúnjẹ wá.”—Lúùkù 22:25-27.

      Láìka pé àwọn àpọ́sítélì yìí jẹ́ aláìpé, wọ́n dúró ti Jésù gbágbáágbá nígbà ìṣòro. Torí náà, Jésù sọ pé: “Mo . . . bá yín dá májẹ̀mú fún ìjọba kan, bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú.” (Lúùkù 22:29) Gbogbo ọkàn làwọn ọkùnrin yìí fi ń tẹ̀ lé Jésù. Torí náà, Jésù fi dá wọn lójú pé òun máa dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú wọn, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti wà nínú Ìjọba rẹ̀, kí wọ́n sì bá a jọba.

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì nírú ìrètí yìí, áláìpé ṣì ni wọ́n. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Sátánì ti béèrè pé òun fẹ́ gba gbogbo yín, kó lè kù yín bí àlìkámà,” tó máa ń fọ́n ká tí wọ́n bá kù ú. (Lúùkù 22:31) Ó tún kìlọ̀ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi lóru òní, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn inú agbo sì máa tú ká.’ ”—Mátíù 26:31; Sekaráyà 13:7.

      Gbogbo ẹnu ni Pétérù fi sọ pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ, ó dájú pé èmi ò ní kọsẹ̀ láé!” (Mátíù 26:33) Jésù wá sọ fún Pétérù pé ó máa sẹ́ òun kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Mo ti bá yín bẹ̀bẹ̀, kí ìgbàgbọ́ yín má bàa yẹ̀; ní ti ìwọ, gbàrà tí o bá pa dà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) Síbẹ̀ Pétérù fi ìdánilójú sọ fún Jésù pé: “Àní tó bá tiẹ̀ gba pé kí n kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, ó dájú pé mi ò ní sẹ́ ọ.” (Mátíù 26:35) Àwọn tó kù sì sọ ohun kan náà.

      Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìgbà díẹ̀ sí i ni màá fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ máa wá mi; bí mo sì ṣe sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ,’ mò ń sọ fún ẹ̀yin náà báyìí.” Ó wá fi kún un pé: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—Jòhánù 13:33-35.

      Bí Pétérù ṣe gbọ́ tí Jésù sọ pé òun ò ní pẹ́ lọ, ó béèrè pé: “Olúwa, ibo lò ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “O ò lè tẹ̀ lé mi lọ síbi tí mò ń lọ báyìí, àmọ́ o máa tẹ̀ lé mi tó bá yá.” Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló dé tí mi ò lè tẹ̀ lé ọ báyìí? Màá fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”—Jòhánù 13:36, 37.

      Jésù rán wọn létí ìgbà tó rán wọn lọ sí agbègbè Gálílì láti lọ wàásù, tó sì ní kí wọ́n má ṣe mú àmùrè tí wọ́n ń kó owó sí tàbí àpò oúnjẹ dání. (Mátíù 10:5, 9, 10) Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ ò ṣaláìní nǹkan kan, àbí ẹ ṣaláìní?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Rárá!” Àmọ́, ṣé bí wọ́n á ṣe máa ṣe lọ nìyẹn? Jésù fún wọn ní ìtọ́ni míì, ó ní: “Kí ẹni tó ní àpò owó gbé e, bẹ́ẹ̀ náà ni àpò oúnjẹ, kí ẹni tí kò bá ní idà ta aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, kó sì ra ọ̀kan. Torí mò ń sọ fún yín pé ohun tó wà ní àkọsílẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe sí mi délẹ̀délẹ̀, pé, ‘A kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Torí èyí ń ṣẹ sí mi lára.”—Lúùkù 22:35-37.

      Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, ó ń tọ́ka sí bí wọ́n ṣe máa kan òun mọ́gi pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú tàbí àwọn arúfin. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa kojú inúnibíni tó lágbára. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn rò pé àwọn ti ṣe tán láti kojú inúnibíni èyíkéyìí, wọ́n wá sọ pé: “Olúwa, wò ó! idà méjì nìyí.” Jésù wá dá wọn lóhùn pé: “Ó ti tó.” (Lúùkù 22:38) Bí wọ́n ṣe ní idà méjì yẹn máa jẹ́ kí Jésù lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan láìpẹ́ sígbà yẹn.

      • Kí làwọn àpọ́sítélì ń jiyàn lé lórí, báwo sì ni Jésù ṣe yanjú ẹ̀?

      • Àǹfààní wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ máa rí nínú májẹ̀mú tí Jésù bá wọn dá?

      • Kí ni Jésù sọ nígbà tí Pétérù fi ìdánilójú dá a lóhùn?

  • Jésù Ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù wà nínú yàrá tó wà lókè pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá

      ORÍ 119

      Jésù Ni Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

      JÒHÁNÙ 14:1-31

      • JÉSÙ FẸ́ LỌ PÈSÈ IBI KAN SÍLẸ̀ DE ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀

      • Ó ṢÈLÉRÍ OLÙRÀNLỌ́WỌ́ KAN FÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀

      • BABA TÓBI JU JÉSÙ LỌ

      Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ò tíì kúrò nínú yàrá tó wà lókè níbi tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Jésù wá gbà wọ́n níyànjú, ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú èmi náà.”—Jòhánù 13:36; 14:1.

      Jésù ò fẹ́ káwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ yẹn máa ṣàníyàn nígbà tóun bá lọ, torí náà ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùgbé ló wà. . . . Tí mo bá lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, màá tún pa dà wá, màá sì gbà yín sílé sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ̀yin náà lè wà ní ibi tí mo wà.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ yẹn ò yé wọn, wọn ò mọ̀ pé ọ̀run ni Jésù sọ pé òun ń lọ. Ni Tọ́másì bá béèrè pé: “Olúwa, a ò mọ ibi tó ò ń lọ. Báwo la ṣe fẹ́ mọ ọ̀nà ibẹ̀?”—Jòhánù 14:2-5.

      Jésù dá a lóhùn pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà wọ ilé Baba Jésù tó wà lọ́run ni pé kéèyàn gba Jésù gbọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, kéèyàn sì máa ṣe bíi ti Jésù. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6.

      Fílípì ń fọkàn sí ohun tí Jésù sọ, torí náà ó sọ pé: “Olúwa, fi Baba hàn wá, ìyẹn sì máa tó wa.” Ó jọ pé ṣe ló ń wu Fílípì láti rí àmì ńlá kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, irú èyí tí Mósè, Èlíjà àti Àìsáyà rí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun táwọn àpọ́sítélì yìí rí ju ohun táwọn wòlíì yẹn rí lọ. Kí wọ́n lè mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, Jésù sọ pé: “Fílípì, pẹ̀lú bó ṣe pẹ́ tó tí mo ti wà pẹ̀lú yín, ṣé o ò tíì mọ̀ mí ni? Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” Jésù gbé ìwà Baba rẹ̀ yọ gẹ́lẹ́; torí náà bí wọ́n ṣe ń rí Jésù, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n rí Baba rẹ̀. Àmọ́ o, Baba tóbi ju Ọmọ lọ, ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Kì í ṣe èrò ara mi ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín.” (Jòhánù 14:8-10) Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń jẹ́ káwọn àpọ́sítélì yẹn rí i pé ọ̀dọ̀ Baba ni ohun tóun fi ń kọ́ni ti wá.

      Àwọn àpọ́sítélì yẹn ti rí bí Jésù ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu àti bó ṣe ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi náà máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; ó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” (Jòhánù 14:12) Jésù ò sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ju èyí tóun ṣe lọ. Àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé àsìkò tí wọ́n máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa pọ̀ ju tòun lọ, wọ́n máa wàásù dé ibi tó jìnnà gan-an, àwọn tí wọ́n máa wàásù fún sì máa pọ̀ ju tòun lọ.

      Bí Jésù ò tiẹ̀ sí láàárín wọn mọ́, kò ní pa wọ́n tì, torí ó ṣèlérí fún wọn pé: “Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, màá ṣe é.” Àmọ́ ó tún sọ pé: “Màá béèrè lọ́wọ́ Baba, ó sì máa fún yín ní olùrànlọ́wọ́ míì tó máa wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́.” (Jòhánù 14:14, 16, 17) Ẹ̀mí mímọ́ ni olùrànlọ́wọ́ míì tí Jésù ń sọ, ó sì fi dá wọn lójú pé wọ́n máa gba ẹ̀mí mímọ́ yìí. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni wọ́n sì gbà á.

      Jésù wá sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé ò ní rí mi mọ́, àmọ́ ẹ máa rí mi, torí pé mo wà láàyè, ẹ sì máa wà láàyè.” (Jòhánù 14:19) Kì í ṣe pé Jésù máa fara hàn wọ́n lẹ́yìn tó bá jíǹde nìkan ni, kódà tó bá yá, ó máa jí àwọn náà dìde sí ọ̀run, wọ́n sì máa di ẹ̀dá ẹ̀mí.

      Lẹ́yìn náà, Jésù sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan fún wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tó bá ní àwọn àṣẹ mi, tó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi. Lọ́wọ́ kejì, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ mi, Baba mi máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi náà máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, màá sì fi ara mi hàn án kedere.” Ni ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì tó ń jẹ́ Júdásì, tí wọ́n tún ń pè ní Tádéọ́sì bá bi í pé: “Olúwa, kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi jẹ́ pé àwa lo fẹ́ fi ara rẹ hàn kedere sí, tí kì í ṣe ayé?” Jésù dá a lóhùn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, ó máa pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ . . . Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ mi kì í pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́.” (Jòhánù 14:21-24) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé Jésù ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, àmọ́ àwọn èèyàn tó wà láyé ò mọ̀.

      Ní báyìí tí Jésù ti fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀, báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa rántí gbogbo ohun tó ti kọ́ wọn? Jésù ṣàlàyé pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, tí Baba máa rán ní orúkọ mi, máa kọ́ yín ní gbogbo nǹkan, ó sì máa rán yín létí gbogbo ohun tí mo sọ fún yín.” Àwọn àpọ́sítélì ti rí bí ẹ̀mí mímọ́ yìí ṣe lágbára tó, torí náà ọkàn wọn balẹ̀. Jésù wá fi kún un pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín; mo fún yín ní àlàáfíà mi. . . . Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín, kí ìbẹ̀rù má sì mú kí ọkàn yín dà rú.” (Jòhánù 14:26, 27) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rí i pé ó yẹ káwọn fọkàn balẹ̀ torí àwọn ṣì máa gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Baba Jésù, á sì dáàbò bò àwọn.

      Wọ́n máa tó rí ẹ̀rí pé Ọlọ́run máa dáàbò bò wọ́n. Jésù sọ pé: “Alákòóso ayé ń bọ̀, kò sì ní agbára kankan lórí mi.” (Jòhánù 14:30) Èṣù ráyè wọnú Júdásì, ó sì rí Júdásì lò. Àmọ́ kò sí èrò burúkú kankan lọ́kàn Jésù tí Sátánì lè lò láti mú kó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì ni Èṣù ò lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti jí Jésù dìde. Kí nìdí tí kò fi lè ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù sọ ìdí, ó ní: “Ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.” Ó dá Jésù lójú pé Baba òun máa jí òun dìde.—Jòhánù 14:31.

      • Ibo ni Jésù ń lọ, kí ló sì sọ tó fọkàn Tọ́másì balẹ̀ nípa béèyàn ṣe lè débẹ̀?

      • Kí ni Fílípì fẹ́ kí Jésù fi han òun?

      • Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó ju èyí tí Jésù ṣe lọ?

      • Kí nìdí tó fi fini lọ́kàn balẹ̀ pé Baba tóbi ju Jésù lọ?

  • Béèyàn Ṣe Lè Dà Bí Ẹ̀ka Tó Ń So Èso, Kó sì Di Ọ̀rẹ́ Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń kúrò ní yàrá tó wà ní òkè

      ORÍ 120

      Béèyàn Ṣe Lè Dà Bí Ẹ̀ka Tó Ń So Èso, Kó sì Di Ọ̀rẹ́ Jésù

      JÒHÁNÙ 15:1-27

      • ÀJÀRÀ TÒÓTỌ́ ÀTI Ẹ̀KA RẸ̀

      • BÉÈYÀN ṢE LÈ DÚRÓ NÍNÚ ÌFẸ́ JÉSÙ

      Ó ti ṣe díẹ̀ tí Jésù ti ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn, ó sì ń fìfẹ́ báwọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Ilẹ̀ ti ṣú báyìí, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n ti wà ní àárín òru. Jésù wá sọ àpèjúwe kan fún wọn kó lè fún wọn níṣìírí, ó sọ pé:

      “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni ẹni tó ń dáko.” (Jòhánù 15:1) Àpèjúwe yìí jọ ohun táwọn wòlíì Jèhófà sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, wọ́n pe orílẹ̀-èdè náà ní ọgbà àjàrà Jèhófà. (Jeremáyà 2:21; Hósíà 10:1, 2) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà fẹ́ pa orílẹ̀-èdè yẹn tì. (Mátíù 23:37, 38) Torí náà Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ ètò tuntun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun dà bí ọgbà àjàrà, àtìgbà tí Baba sì ti fẹ̀mí yan òun lọ́dún 29 S.K. ni Baba ti ń bójú tó o. Àmọ́, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun nìkan kọ́ ni ọgbà àjàrà yẹn dúró fún, ó sọ pé:

      “[Baba mi] ń mú gbogbo ẹ̀ka tí kì í so èso nínú mi kúrò, ó sì ń wẹ gbogbo èyí tó ń so èso mọ́, kó lè so èso púpọ̀ sí i. . . . Bí ẹ̀ka ò ṣe lè dá so èso àfi tó bá dúró lára àjàrà, ẹ̀yin náà ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, àfi tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi. Èmi ni àjàrà náà; ẹ̀yin ni ẹ̀ka.”—Jòhánù 15:2-5.

      Jésù ti ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ pé tí òun bá lọ, òun máa rán olùrànlọ́wọ́ kan sí wọn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Ní ọjọ́ mọ́kànléláàádọ́ta (51) lẹ́yìn náà, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó wà níbi tí wọ́n kóra jọ sí, wọ́n di ẹ̀ka igi àjàrà. Gbogbo “ẹ̀ka” igi àjàrà yẹn ló sì gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù. Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan?

      Jésù ṣàlàyé pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni yìí ń so èso púpọ̀; torí láìsí èmi, ẹ ò lè ṣe ohunkóhun.” “Ẹ̀ka” yìí dúró fún àwọn tó ń fi òótọ́ inú tẹ̀ lé Jésù, wọ́n máa so èso tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n lè sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ẹnì kan ò bá wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù, tí kò sì so èso? Jésù ṣàlàyé pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, a máa sọ ọ́ nù.” Lẹ́yìn náà, Jésù wá sọ pé: “Tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí àwọn ọ̀rọ̀ mi sì wà nínú yín, ẹ béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, ó sì máa rí bẹ́ẹ̀ fún yín.”—Jòhánù 15:5-7.

      Ìgbà méjì ni Jésù ti bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa pa àwọn àṣẹ òun mọ́, ó tún wá mẹ́nu bà á lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 14:15, 21) Jésù ṣàlàyé nǹkan pàtàkì tí wọ́n á máa ṣe tó máa fi hàn pé wọ́n ń pa àṣẹ òun mọ́, ó ní: “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ máa dúró nínú ìfẹ́ mi, bí mo ṣe pa àwọn àṣẹ Baba mọ́ gẹ́lẹ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” Àmọ́, wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣe kọjá kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín, tí ẹ bá ń ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.”—Jòhánù 15:10-14.

      Ní wákàtí díẹ̀ sí i, Jésù máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú òun, torí ó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wọn. Ó yẹ kí àpẹẹrẹ Jésù mú kó máa wu àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi ẹ̀mí ara wọn lélẹ̀ nítorí àwọn míì. Jésù sì ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé ìfẹ́ ló máa jẹ́ káwọn èèyàn dá wọn mọ̀, ó ní: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—Jòhánù 13:35.

      Ó yẹ káwọn àpọ́sítélì yẹn ronú lórí bí Jésù ṣe pè wọ́n ní “ọ̀rẹ́.” Jésù sọ ohun tó mú kó pè wọ́n bẹ́ẹ̀, ó ní: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.” Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn fún wọn láti ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jésù, kí wọ́n sì mọ ohun tí Baba rẹ̀ sọ fún un! Àmọ́ kí wọ́n lé máa gbádùn irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ “máa so èso.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ń so èso? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.”—Jòhánù 15:15, 16.

      Tí ìfẹ́ bá wà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó dúró fún “ẹ̀ka” yẹn, ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti fara da ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jésù wá kìlọ̀ fún wọn pé ayé máa kórìíra wọn, àmọ́ ó sọ ohun kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín. Tí ẹ bá jẹ́ apá kan ayé, ayé máa nífẹ̀ẹ́ ohun tó jẹ́ tirẹ̀. Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.”—Jòhánù 15:18, 19.

      Jésù ṣàlàyé ìdí tí ayé fi máa kórìíra wọn, ó ní: “Wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ Ẹni tó rán mi.” Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn tó kórìíra òun jẹ̀bi torí pé wọn ò ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tóun ṣe, ó ní: “Ká ní mi ò ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹnì kankan ò ṣe rí láàárín wọn ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan; àmọ́ ní báyìí wọ́n ti rí mi, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi.” Bí wọ́n ṣe kórìíra Jésù yìí mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ.—Jòhánù 15:21, 24, 25; Sáàmù 35:19; 69:4.

      Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún ṣèlérí pé òun máa rán olùrànlọ́wọ́ kan sí wọn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ẹ̀mí mímọ́ yìí wà fún, òun ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa so èso, kí wọ́n sì máa “jẹ́rìí” nípa Jésù.—Jòhánù 15:27.

      • Nínú àpèjúwe Jésù, ta ni ẹni tó ń dáko, ta ni àjàrà, àwọn wo sì ni ẹ̀ka àjàrà náà?

      • Èso wo ni Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀ka náà máa so?

      • Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jésù, kí ló sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí ayé bá kórìíra wọn?

  • “Ẹ Mọ́kàn Le! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ọkàn àwọn àpọ́sítélì ò balẹ̀ nígbà tí Jésù fún wọn ní ìkìlọ̀ kan

      ORÍ 121

      “Ẹ Mọ́kàn Le! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”

      JÒHÁNÙ 16:1-33

      • LÁÌPẸ́, ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ Ò NÍ RÍ JÉSÙ MỌ́

      • ÌBÀNÚJẸ́ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ MÁA TÓ DI AYỌ̀

      Ara àwọn àpọ́sítélì Jésù ti wà lọ́nà láti kúrò ní yàrá òkè níbi tí wọ́n ti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. Lẹ́yìn tí Jésù fún wọn níṣìírí, ó sọ fún wọn pé: “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀.” Kí nìdí tó fi fún wọn ní ìkìlọ̀ yìí? Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù. Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run.”—Jòhánù 16:1, 2.

      Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ yẹn mú kí ẹ̀rù bà wọ́n. Lóòótọ́ Jésù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé ayé máa kórìíra wọn, àmọ́ kò sọ fún wọn rí pé wọ́n máa pa wọ́n. Kí nìdí tí kò fi sọ fún wọn? Jésù sọ pé: “Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín.” (Jòhánù 16:4) Ṣe ló ń múra wọn sílẹ̀ torí láìpẹ́ kò ní sí lọ́dọ̀ wọn mọ́. Bó ṣe sọ fún wọn yẹn ò ní jẹ́ kó bá wọn lójijì, wọn ò sì ní kọsẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

      Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi; síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’ ” Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n ti ní kí Jésù sọ ibi tó ń lọ fún àwọn. (Jòhánù 13:36; 14:5; 16:5) Àmọ́ ní báyìí tí Jésù sọ pé wọ́n máa kojú inúnibíni, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tójú wọn máa rí lọ́jọ́ iwájú, ìrònú sì sorí wọn kodò. Wọn ò tiẹ̀ rántí béèrè nípa irú ògo tí Jésù máa ní nígbà tó bá dé ọ̀run tàbí bí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i ṣe máa kan àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. Jésù wá sọ pé: “Torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.”—Jòhánù 16:6.

      Lẹ́yìn náà, Jésù ṣàlàyé pé: “Torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín.” (Jòhánù 16:7) Ó dìgbà tí Jésù bá kú, tó sì lọ sọ́run káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó lè gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí fún wọn, ó sì dájú pé kò síbi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà láyé tí ẹ̀mí mímọ́ ò ti lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

      Ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí “máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́.” (Jòhánù 16:8) Ó máa hàn pé àwọn èèyàn kọ̀ láti nígbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe ń lọ sí ọ̀run máa jẹ́ kó hàn kedere pé olóòótọ́ ni, ìyẹn á sì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ kí Ọlọ́run mú ìdájọ́ tó lágbára wá sórí Sátánì tó jẹ́ “alákòóso ayé yìí.”—Jòhánù 16:11.

      Jésù wá sọ pé: “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù bá tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí wọn, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye “gbogbo òtítọ́,” ìyẹn á sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa fí òtítọ́ yẹn sílò nígbèésí ayé wọn.—Jòhánù 16:12, 13.

      Ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn ìyẹn tún da gbogbo ọ̀rọ̀ rú mọ́ àwọn àpọ́sítélì yẹn lójú, ó sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.” Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí láàárín ara wọn. Jésù rí i pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ béèrè lọ́wọ́ òun, torí náà ó ṣàlàyé fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.” (Jòhánù 16:16, 20) Nígbà tí wọ́n pa Jésù, ṣe ni inú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń dùn, àmọ́ ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣọ̀fọ̀ ní tiwọn. Ẹ̀dùn ọkàn wọn yẹn wá pa dà di ayọ̀ nígbà tí Ọlọ́run jí Jésù dìde. Ayọ̀ yìí sì wá pọ̀ sí i nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí wọn nígbà tó yá.

      Jésù fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì yẹn wé ìgbà tí obìnrin kan bá ń rọbí, ó sọ pé: “Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí èèyàn kan sí ayé.” Jésù wá fún wọn níṣìírí, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn, ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́.”—Jòhánù 16:21, 22.

      Títí dìgbà tí Jésù fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, àwọn àpọ́sítélì yẹn ò béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù rí. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Kì í ṣe pé Baba ò ní dá wọn lóhùn tí wọ́n bá béèrè. Torí Jésù sọ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi . . . bí aṣojú Ọlọ́run.”—Jòhánù 16:26, 27.

      Ohun tí Jésù sọ yẹn mú kí ara tu àwọn àpọ́sítélì yẹn, ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.” Àmọ́ àdánwò tó ń bọ̀ láìpẹ́ máa jẹ́ kó hàn bóyá ohun tí wọ́n sọ yẹn dá wọn lójú lóòótọ́. Jésù wá ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: “Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.” Síbẹ̀, ó fi dá wọn lójú pé: “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi. Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:30-33) Kì í ṣe pé Jésù máa pa wọ́n tì. Ó dá a lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣẹ́gun ayé bí òun náà ṣe ṣẹ́gun ayé, ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ tọkàntọkàn láìka pé Sátánì àti ayé tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ máa gbìyànjú láti ba ìṣòtítọ́ wọn jẹ́.

      • Ìkìlọ̀ wo ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn àpọ́sítélì Jésù?

      • Kí nìdí tí àwọn àpọ́sítélì ò fi béèrè ìbéèrè míì lọ́wọ́ Jésù?

      • Báwo ni Jésù ṣe ṣàpèjúwe bí ẹ̀dùn ọkàn àwọn àpọ́sítélì ṣe máa pa dà di ayọ̀?

  • Àdúrà Tí Jésù Gbà Kẹ́yìn ní Yàrá Tó Wà Lókè
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù gbójú sókè, ó sì ń gbàdúrà lójú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀

      ORÍ 122

      Àdúrà Tí Jésù Gbà Kẹ́yìn ní Yàrá Tó Wà Lókè

      JÒHÁNÙ 17:1-26

      • OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ TẸ́NÌ KAN BÁ MỌ ỌLỌ́RUN ÀTI ỌMỌ RẸ̀

      • ÌṢỌ̀KAN TÓ WÀ LÁÀÁRÍN JÈHÓFÀ, JÉSÙ ÀTÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN

      Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gan-an, ìdí nìyẹn tó fi ń múra ọkàn wọn sílẹ̀ torí pé kò ní pẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ó wá gbójú sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Baba rẹ̀, ó sọ pé: “Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo, bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara, kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:1, 2.

      Kò sí iyèméjì pé Jésù mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa darí ògo sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Jésù tún jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn ni ìyè àìnípẹ̀kun. Torí pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní “àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,” ó máa ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti gbádùn ìbùkún tí ẹbọ ìràpadà rẹ̀ máa mú wá. Síbẹ̀, díẹ̀ làwọn tó máa rí ìbùkún yẹn gbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwọ̀nba àwọn tó bá ṣe ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé e yìí nìkan ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà, Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”—Jòhánù 17:3.

      Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ mọ Baba àti Ọmọ dáadáa, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú wọn. A tún gbọ́dọ̀ máa wo nǹkan bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń wò ó. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn méjèèjì nínú ìwà wa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ gbà pé ó ṣe pàtàkì ká ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, torí pé ìyẹn ló máa mú ká rí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù wá pa dà sórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

      Ó ní: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ayé, ní ti pé mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe. Torí náà, ní báyìí, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:4, 5) Jésù bẹ Jèhófà pé kó jí òun dìde, kó sì jẹ́ kóun tún pa dà ní irú ògo tóun ní nígbà tóun wà lọ́run.

      Síbẹ̀, Jésù ò gbàgbé àṣeyọrí tó ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó gbàdúrà pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé. Ìwọ lo ni wọ́n, o sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Jòhánù 17:6) Kì í ṣe pé Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run nìkan ni. Ó tún ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò.

      Àwọn àpọ́sítélì yẹn ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọ́n ti mọ ohun tí Jésù wá ṣe láyé, Jésù sì ti kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Síbẹ̀, Jésù ò jẹ́ káwọn nǹkan tóun ṣe yẹn kó sí òun lórí, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi ni mo ti sọ fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, ó dájú pé wọ́n ti wá mọ̀ pé mo wá bí aṣojú rẹ, wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.”—Jòhánù 17:8.

      Lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ ká rí i pé ìyàtọ̀ máa wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn òun àtàwọn èèyàn tó kù, ó ní: “Mo gbàdúrà nípa wọn; kì í ṣe nípa ayé, àmọ́ nípa àwọn tí o fún mi, torí pé ìwọ lo ni wọ́n . . . Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan. . . . Mo ti dáàbò bò wọ́n, ìkankan nínú wọn ò sì pa run àfi ọmọ ìparun,” ìyẹn Júdásì Ìsìkáríọ́tù tó jẹ́ pé bó ṣe máa da Jésù ló ń bá kiri.—Jòhánù 17:9-12.

      Jésù ṣì ń bá àdúrà tó ń gbà lọ, ó ní: “Ayé ti kórìíra wọn . . . Mi ò ní kí o mú wọn kúrò ní ayé, àmọ́ kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14-16) Inú ayé tí Èṣù ń darí yìí làwọn àpọ́sítélì yẹn àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ń gbé, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí ayé ń ṣe, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù. Kí ló máa mú kíyẹn ṣeé ṣe?

      Ohun tó máa mú kó ṣeé ṣe ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀, kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ láti sin Ọlọ́run. Èyí gba pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àtàwọn nǹkan tí Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ wọn. Jésù gbàdúrà pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Tó bá yá, Ọlọ́run máa mí sí àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì yẹn láti kọ àwọn ìwé táá di apá kan “òtítọ́” tó máa sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di mímọ́.

      Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa gba “òtítọ́” yẹn. Torí náà, Jésù gbàdúrà pé: “Kì í ṣe àwọn yìí nìkan [ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn] ni mò ń gbàdúrà nípa wọn, mo tún ń gbàdúrà nípa àwọn tó máa ní ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn.” Kí ni Jésù ń gbàdúrà pé kó ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ó sọ pé: “Kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa.” (Jòhánù 17:20, 21) Èyí ò túmọ̀ sí pé ẹnì kan ṣoṣo ni Jésù àti Baba rẹ̀. Àmọ́ ọ̀kan ni wọ́n torí pé ohùn wọn máa ń ṣọ̀kan nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Jésù wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun náà máa gbádùn irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀.

      Ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù ti sọ fún Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù pé òun fẹ́ lọ pèsè ibì kan sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run. (Jòhánù 14:2, 3) Jésù wá fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà, ó ní: “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà, kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 17:24) Ohun tó sọ yìí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ti nífẹ̀ẹ́ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo yìí, kódà ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.

      Bí Jésù ṣe ń parí àdúrà yẹn, ó tún pa dà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Baba rẹ̀ àti bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ “òtítọ́” tó bá yá. Ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n, kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”—Jòhánù 17:26.

      • Kí ló túmọ̀ sí láti mọ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀?

      • Báwo ni Jésù ṣe fi orúkọ Ọlọ́run hàn kedere?

      • Báwo ni Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ àtàwọn tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́ ṣe jẹ́ ọ̀kan?

  • Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù lọ gbàdúrà nínú ọgbà Gẹ́tísémánì, àmọ́ ṣe ni Pétérù, Jémí ìsì àti Jòhánù ń sùn

      ORÍ 123

      Jésù Gbàdúrà Nígbà Tí Ẹ̀dùn Ọkàn Bá A

      MÁTÍÙ 26:30, 36-46 MÁÀKÙ 14:26, 32-42 LÚÙKÙ 22:39-46 JÒHÁNÙ 18:1

      • JÉSÙ LỌ SÍNÚ ỌGBÀ GẸ́TÍSÉMÁNÌ

      • ÒÓGÙN RẸ̀ DÀ BÍ Ẹ̀JẸ̀ TÓ Ń KÁN SÍLẸ̀

      Lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, ‘wọ́n kọrin ìyìn, wọ́n sì lọ sí Òkè Ólífì.’ (Máàkù 14:26) Wọ́n lọ sápá ìlà oòrùn, níbi ọgbà kan tí Jésù sábà máa ń lọ, ìyẹn ọgbà Gẹ́tísémánì.

      Ọgbà yìí tura gan-an ni, àwọn igi ólífì sì wà níbẹ̀. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ débẹ̀, Jésù fi mẹ́jọ lára wọn síbì kan, bóyá níbi àbáwọlé ọgbà náà. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jókòó síbí, mo fẹ́ lọ sí ọ̀hún yẹn lọ gbàdúrà.” Jésù wá wọnú ọgbà náà, ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání. Ìdààmú bá a gan-an, ó wá sọ fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi gan-an, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”—Mátíù 26:36-38.

      Jésù wá rìn síwájú díẹ̀, lẹ́yìn náà “ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà.” Kí ló ń bá Ọlọ́run sọ nírú àkókò tó nira yẹn? Ó gbàdúrà pé: “Bàbá, ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.” (Máàkù 14:35, 36) Kí ló ní lọ́kàn ná? Ṣé kò fẹ́ ra àwa èèyàn pa dà mọ́ ni? Rárá o!

      Àtìgbà tí Jésù ti wà lọ́run ló ti ń rí bí ìjọba Róòmù ṣe máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń pa wọ́n nípa ìkà. Ní báyìí tó ti di èèyàn, ó dájú pé ó ti mọ bí ìyà ṣe ń rí lára, ó sì mọ̀ pé ìyà kì í ṣomi ọbẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ló gbà á lọ́kàn, ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ló ń rò. Ẹ̀dùn ọkàn bá a bó ṣe ń rò ó pé wọ́n máa pa òun bí ọ̀daràn, ìyẹn sì lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Baba òun. Ní wákàtí díẹ̀ sígbà yẹn, wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, wọ́n sì máa gbé e kọ́ sórí òpó igi.

      Lẹ́yìn tí Jésù ti gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ àkókò, ó pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta náà, ó sì bá wọn tí wọ́n ń sùn. Ó wá sọ fún Pétérù pé: “Ṣé ẹ ò wá lè ṣọ́nà pẹ̀lú mi fún wákàtí kan péré ni? Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.” Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ó ti rẹ àwọn àpọ́sítélì yẹn àti pé ilẹ̀ ti ṣú. Torí náà, ó sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́, àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”—Mátíù 26:40, 41.

      Lẹ́yìn tí Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ tán, ó tún pa dà lọ gbàdúrà, ó sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó mú “ife yìí” kúrò lórí òun. Dípò táwọn àpọ́sítélì yẹn á fi máa gbàdúrà kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹwò, orí oorun ni Jésù tún bá wọn nígbà tó pa dà sọ́dọ̀ wọn. Kódà nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, “wọn ò mọ èsì tí wọ́n máa fún un.” (Máàkù 14:40) Jésù wá pa dà lọ nígbà kẹta, ó wólẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.

      Ìdààmú bá a gan-an, ó ń ronú nípa bí wọ́n ṣe máa pa òun bí ìgbà tí wọ́n pa ọ̀daràn, tíyẹn sì máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́ Jèhófà ò fi í sílẹ̀, ó gbọ́ àdúrà rẹ̀, kódà ìgbà kan wà tí Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí i kó lè fún un lókun. Síbẹ̀, Jésù ò yéé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Baba rẹ̀, ṣe ló “túbọ̀ ń gbàdúrà taratara.” Ká sòótọ́, onírúurú nǹkan ló máa wà lọ́kàn Jésù. Ohun tó bá ṣe ló máa pinnu bóyá ó máa pa dà wà láàyè lẹ́yìn tí wọ́n bá pa á, ìyẹn ló sì máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹni tó bá gba Ọlọ́run gbọ́. Ìdààmú bá a débi pé ṣe ni ‘òógùn rẹ̀ dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀.’—Lúùkù 22:44.

      Nígbà tí Jésù tún máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́ẹ̀kẹta, orí oorun ló tún bá wọn. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ẹ wò ó! Wákàtí náà ti dé tán tí wọ́n máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.”—Mátíù 26:45, 46.

      ÒÓGÙN RẸ̀ DÀ BÍ Ẹ̀JẸ̀ TÓ Ń KÁN SÍLẸ̀

      Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn ò ṣàlàyé bí òógùn Jésù ṣe “dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Àmọ́ ó lè jẹ́ pé ṣe ni Lúùkù ń ṣàpèjúwe òógùn tó jáde lára Jésù bí ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ ń jáde láti ojú egbò. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Dr. William D. Edwards tún ṣe àlàyé míì nípa ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé The Journal of the American Medical Association (JAMA). Ó sọ pé: “Téèyàn bá ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára, ohun kan tí kì í sábà wáyé (tí wọ́n ń pè ní hematidrosis. . . ) lè ṣẹlẹ̀ sí onítọ̀hún, ẹ̀jẹ̀ lè máa jáde pẹ̀lú òógùn ara rẹ̀ . . . Ohun tó máa ń fà á ni pé tí ẹ̀jẹ̀ bá ti wọnú ibi tí òógùn ti ń jáde, awọ ara máa fẹ́lẹ́, ìyẹn á sì mú kó ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ náà láti jáde.”

      • Ibo ni Jésù mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní yàrá tó wà lókè?

      • Kí làwọn àpọ́sítélì mẹ́ta tó wà pẹ̀lú Jésù ń ṣe nígbà tó ń gbàdúrà?

      • Bí Bíbélì ṣe sọ pé òógùn Jésù dà bí ẹ̀jẹ̀ tó ń kán sílẹ̀, kí nìyẹn jẹ́ ká mọ̀ nípa bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀?

  • Júdásì Da Jésù, Wọ́n sì Fàṣẹ Ọba Mú Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù bá Pétérù wí torí ó fi idà gé etí Málíkọ́sì dà nù; àwọn ọmọ ogun ṣe tán láti mú Jésù

      ORÍ 124

      Júdásì Da Jésù, Wọ́n sì Fàṣẹ Ọba Mú Jésù

      MÁTÍÙ 26:47-56 MÁÀKÙ 14:43-52 LÚÙKÙ 22:47-53 JÒHÁNÙ 18:2-12

      • JÚDÁSÌ DALẸ̀ JÉSÙ NÍNÚ ỌGBÀ GẸ́TÍSÉMÁNÌ

      • PÉTÉRÙ GÉ ETÍ ỌKÙNRIN KAN DÀ NÙ

      • WỌ́N MÚ JÉSÙ

      Ní báyìí, àwọn àlùfáà ti gbà láti san ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà fún Júdásì kó lè fa Jésù lé wọn lọ́wọ́. Ni Júdásì bá kó ọ̀pọ̀ àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí lẹ́yìn, wọ́n ń wá Jésù lọ láàárín òru. Àwọn ọmọ ogun Róòmù àti ọ̀gágun wọn sì ń tẹ̀ lé wọn.

      Ó ṣe kedere pé nígbà tí Jésù ní kí Júdásì kúrò níbi tí wọ́n ti ń jẹ Ìrékọjá, ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà ló lọ. (Jòhánù 13:27) Wọ́n wá kó àwọn aláṣẹ àtàwọn ọmọ ogun jọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé yàrá tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ni Júdásì kọ́kọ́ mú wọn lọ. Àmọ́ ní báyìí, torí pé wọn ò rí Jésù níbẹ̀, Júdásì àtàwọn tó ń tẹ̀ lé e sọdá Àfonífojì Kídírónì, wọ́n sì forí lé ọgbà Gẹ́tísémánì. Ohun ìjà nìkan kọ́ ló wà lọ́wọ́ wọn, wọ́n tún gbé iná dání, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí Jésù mú.

      Bí Júdásì àtàwọn tó ń tẹ̀ lé e ṣe ń gun Òkè Ólífì, ọkàn Júdásì balẹ̀ pé òun mọ ibi tí Jésù máa wà. Torí láàárín ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà yẹn, tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá ń lọ láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sábà máa ń dúró ní ọgbà Gẹ́tísémánì. Àmọ́ ilẹ̀ ti ṣú báyìí, ó sì ṣeé ṣe kí òjìji àwọn igi ólífì tó wà nínú ọgbà yẹn ti mú kí ibi tí Jésù wà ṣókùnkùn. Torí náà, ó lè má rọrùn fáwọn ọmọ ogun yẹn láti dá Jésù mọ̀. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n má rí Jésù rí. Ó dájú pé Júdásì máa ní láti ṣe nǹkan kan kí wọ́n lè dá Jésù mọ̀. Ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un, kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ bí ẹ ṣe ń mú un lọ.”—Máàkù 14:44.

      Bí Júdásì ṣe mú àwọn tó ń tẹ̀ lé e wọnú ọgbà náà ló rí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù, ó wá lọ bá Jésù. Ó sọ pé: “Mo kí ọ o, Rábì!” ó sì rọra fẹnu ko Jésù lẹ́nu. Jésù bi í pé: “Ọ̀gbẹ́ni, kí lo wá ṣe níbí?” (Mátíù 26:49, 50) Jésù fúnra rẹ̀ ló tún dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Júdásì, ṣé o fẹ́ fi ẹnu ko Ọmọ èèyàn lẹ́nu kí o lè dalẹ̀ rẹ̀ ni?” (Lúùkù 22:48) Àmọ́ o, Júdásì ti ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, torí náà Jésù ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ mọ́!

      Jésù wá bọ́ síbi tí ìmọ́lẹ̀ wà, ó sì bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Lára àwọn tó tẹ̀ lé Júdásì sọ pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù fìgboyà sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” (Jòhánù 18:4, 5) Bí Jésù ṣe fìgboyà dáhùn ya àwọn ọkùnrin yìí lẹ́nu, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.

      Dípò tí Jésù ì bá fìyẹn sá mọ́ wọn lọ́wọ́, ṣe ló tún bi wọ́n pé ta ni wọ́n ń wá. Wọ́n ní, “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” Jésù wá fi ohùn pẹ̀lẹ́ dáhùn, ó ní: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Torí náà, tó bá jẹ́ èmi lẹ̀ ń wá, ẹ fi àwọn yìí sílẹ̀.” Kódà lásìkò tó gbẹgẹ́ yìí, Jésù ò gbàgbé ohun tó ti sọ tẹ́lẹ̀, pé òun ò ní pàdánù ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòhánù 6:39; 17:12) Jésù ti dáàbò bo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, kò sì pàdánù ìkankan nínú wọn, àfi Júdásì “ọmọ ìparun.” (Jòhánù 18:7-9) Ìdí nìyẹn tó fi sọ fáwọn tó wá mú un pé kí wọ́n má fọwọ́ kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó jẹ́ olóòótọ́.

      Báwọn ọmọ ogun yẹn ṣe dìde, tí wọ́n ń sún mọ́ Jésù làwọn àpọ́sítélì ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé wọ́n ti fẹ́ mú Jésù lóòótọ́. Ni wọ́n bá bi í pé: “Olúwa, ṣé ká fi idà bá wọn jà?” (Lúùkù 22:49) Kí Jésù tó dá wọn lóhùn, Pétérù ti fa ọ̀kan lára idà méjì tó wà lọ́wọ́ wọn yọ. Ó kọjú sí Málíkọ́sì tó jẹ́ ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.

      Jésù wá fọwọ́ kan etí Málíkọ́sì, ó sì wò ó sàn. Ó fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, ó wá pàṣẹ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, torí gbogbo àwọn tó bá yọ idà máa ṣègbé nípasẹ̀ idà.” Jésù ò sá kí wọ́n má bàa mú òun, torí ó sọ pé: “Báwo ni Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ báyìí ṣe máa ṣẹ?” (Mátíù 26:52, 54) Ó wá fi kún un pé: “Ṣé kò yẹ kí n mu ife tí Baba fún mi ni?” (Jòhánù 18:11) Jésù fẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí òun, kódà, kò kọ̀ kí ẹ̀mí òun lọ sí i.

      Jésù wá bi àwọn tó wá mú un pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè? Ojoojúmọ́ ni mò ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì, tí mò ń kọ́ni, àmọ́ ẹ ò mú mi. Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ohun tí àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ lè ṣẹ.”—Mátíù 26:55, 56.

      Làwọn ọmọ ogun yẹn, ọ̀gágun wọn àtàwọn aláṣẹ àwọn Júù bá mú Jésù, wọ́n sì dè é. Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ṣe ni wọ́n fẹsẹ̀ fẹ. Àmọ́ “ọ̀dọ́kùnrin kan” dúró sáàárín àwọn èèyàn náà kó lè tẹ̀ lé Jésù bí wọ́n ṣe ń mú un lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń jẹ́ Máàkù ni ọ̀dọ́kùnrin yìí. (Máàkù 14:51) Nígbà tó yá, àwọn èèyàn yẹn dá ojú rẹ̀ mọ̀ pé ó wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n sì fẹ́ mú un. Nígbà tí wọ́n fẹ́ gba á mú, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó wọ̀ sílẹ̀ sọ́wọ́ wọn, ó sì sá lọ.

      • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé inú ọgbà Gẹ́tísémánì ni Júdásì wá Jésù lọ?

      • Kí ni Pétérù ṣe kó lè gbèjà Jésù, àmọ́ kí ni Jésù sọ fún un?

      • Kí ni Jésù sọ tó fi hàn pé ó fẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí òun?

      • Nígbà táwọn àpọ́sítélì fi Jésù sílẹ̀, ta ló dúró, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

  • Wọ́n Mú Jésù Lọ Sọ́dọ̀ Ánásì àti Káyáfà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Káyáfà fa aṣọ rẹ̀ ya; àwọn kan gbá Jésù létí, wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́

      ORÍ 125

      Wọ́n Mú Jésù Lọ Sọ́dọ̀ Ánásì àti Káyáfà

      MÁTÍÙ 26:57-68 MÁÀKÙ 14:53-65 LÚÙKÙ 22:54, 63-65 JÒHÁNÙ 18:13, 14, 19-24

      • WỌ́N MÚ JÉSÙ LỌ SỌ́DỌ̀ ÁNÁSÌ TÓ TI FÌGBÀ KAN RÍ JẸ́ ÀLÙFÁÀ ÀGBÀ

      • ÌGBÌMỌ̀ SÀHẸ́NDÌRÌN GBỌ́ ẸJỌ́ KAN LỌ́NÀ TÍ KÒ BÓFIN MU

      Wọ́n de Jésù bí wọ́n ṣe ń de ọ̀daràn, wọ́n wá mú un lọ bá Ánásì. Ánásì yìí ni àlùfáà àgbà nígbà tí Jésù ṣì kéré, ìyẹn nígbà tí Jésù ṣe ohun kan tó ya àwọn olùkọ́ tó wà ní tẹ́ńpìlì lẹ́nu. (Lúùkù 2:42, 47) Nígbà tó yá, wọ́n fi àwọn kan lára àwọn ọmọ Ánásì joyè àlùfáà àgbà, àmọ́ ní báyìí, Káyáfà tó jẹ́ àna rẹ̀ ló wà nípò yẹn.

      Ilé Ánásì ni Jésù wà nígbà tí Káyáfà pe ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn jọ. Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mọ́kànléláàádọ́rin (71) ni, àlùfáà àgbà tó wà lórí oyè lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn tó ti jẹ́ àlùfáà àgbà rí ló sì máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn.

      Ánásì bi Jésù léèrè “nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.” Ohun tí Jésù sọ ò ju pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Gbogbo ìgbà ni mò ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ sí; mi ò sì sọ ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀. Kí ló dé tí ò ń bi mí? Bi àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn.”—Jòhánù 18:19-21.

      Ni ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ tó dúró síbẹ̀ bá fọ́ Jésù létí, ó sì bá a wí, ó ní: “Ṣé bí o ṣe máa dá olórí àlùfáà lóhùn nìyẹn?” Àmọ́ Jésù mọ̀ pé ohun tí òun sọ ò burú, torí náà, ó sọ pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni mo sọ, jẹ́rìí nípa ohun tí kò tọ́ náà; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó tọ́ ni mo sọ, kí ló dé tí o fi gbá mi?” (Jòhánù 18:22, 23) Ánásì wá ní kí wọ́n mú Jésù lọ bá Káyáfà tó jẹ́ àna òun.

      Ní báyìí, ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti pé jọ. Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn ni àlùfáà àgbà tó wà lórí oyè lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn àgbààgbà àtàwọn akọ̀wé òfin. Ilé Káyáfà ni wọ́n pé jọ sí. Lóòótọ́ kò bófin mu láti ṣe irú ìgbẹ́jọ́ yìí lálẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá, síbẹ̀ àwọn èèyàn yẹn hu ìwà burúkú tó wà lọ́kàn wọn.

      Ó dájú pé ọ̀nà èrú ni wọ́n máa gbà ṣèdájọ́ yìí, torí pé lẹ́yìn tí Jésù jí Lásárù dìde, ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ti sọ pé Jésù gbọ́dọ̀ kú. (Jòhánù 11:47-53) Àti pé ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ń wá bí wọ́n ṣe máa mú Jésù, kí wọ́n sì pa á. (Mátíù 26:3, 4) Torí náà, kí wọ́n tiẹ̀ tó gbọ́ ẹjọ́ yẹn ló ti hàn pé ikú lọ̀rọ̀ náà máa já sí!

      Yàtọ̀ sí pé ìgbẹ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí ò bófin mu, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn yòókù tó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ń wá àwọn ẹlẹ́rìí tó máa fẹ̀sùn èké kan Jésù kí wọ́n lè rí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọ́n á fi dá a lẹ́bi. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn wá láti jẹ́rìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn ò bára mu. Nígbà tó yá, àwọn méjì bọ́ síwájú, wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’ ” (Máàkù 14:58) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin yìí ò bára mu délẹ̀délẹ̀.

      Káyáfà wá bi Jésù pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí ń jẹ́ lòdì sí ọ ńkọ́?” (Máàkù 14:60) Jésù ò sọ̀rọ̀ rárá, bí gbogbo àwọn ẹlẹ́rìí tó ń wá ṣe ń fẹ̀sùn èké kàn án, tí ọ̀rọ̀ wọn ò sì bára mu. Ni Káyáfà bá dọ́gbọ́n yí ọ̀rọ̀ yẹn.

      Káyáfà mọ̀ pé àwọn Júù kì í fẹ́ gbọ́ ọ sétí kí ẹnì kan máa pe ara ẹ̀ ní Ọmọ Ọlọ́run. Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé nígbà kan tí Jésù pe Ọlọ́run ní Baba òun, àwọn Júù fẹ́ pa á, torí wọ́n gbà pé ṣe ló “ń sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba.” (Jòhánù 5:17, 18; 10:31-39) Ohun tí Káyáfà mọ̀ yìí wá jẹ́ kó fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ fún Jésù pé: “Mo fi ọ́ sábẹ́ ìbúra níwájú Ọlọ́run alààyè pé kí o sọ fún wa bóyá ìwọ ni Kristi, Ọmọ Ọlọ́run!” (Mátíù 26:63) Lóòótọ́, Jésù máa ń sọ ọ́ ní gbangba pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. (Jòhánù 3:18; 5:25; 11:4) Àmọ́ tó bá sọ ohun tó yàtọ̀ síyẹn níbí, wọ́n máa gbà pé ṣe ló ń sẹ́ pé òun kọ́ ni Ọmọ Ọlọ́run tàbí Kristi. Torí náà, Jésù sọ pé: “Èmi ni; ẹ sì máa rí Ọmọ èèyàn tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ojú ọ̀run.”—Máàkù 14:62.

      Ni Káyáfà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kígbe pé: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì! Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe? Ẹ wò ó! Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. Kí lèrò yín?” Ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn wá dá Jésù lẹ́bi láìtọ́, wọ́n ní: “Ikú ló tọ́ sí i.”—Mátíù 26:65, 66.

      Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jésù ṣe ẹlẹ́yà nìyẹn, wọ́n sì ń gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn kan lára wọn gbá a létí, wọ́n sì tutọ́ sí i lójú. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fi nǹkan bò ó lójú, wọ́n gbá a létí, wọ́n wá ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ní: “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta lẹni tó gbá ọ?” (Lúùkù 22:64) Ẹ wo bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe dẹni yẹ̀yẹ́ lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ ẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́ láàárín òru!

      • Ibo ni wọ́n kọ́kọ́ mú Jésù lọ, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀?

      • Ibo ni ibì kejì tí wọ́n mú Jésù lọ, kí ni Káyáfà sì ṣe tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn fi dájọ́ ikú fún Jésù?

      • Irú ìyà wo ni wọ́n fi jẹ Jésù níbi tí wọ́n ti ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀?

  • Pétérù Sẹ́ Jésù Nílé Káyáfà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù wà lókè, ó ń wo Pétérù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sẹ́ ẹ; àkùkọ wà lẹ́yìn

      ORÍ 126

      Pétérù Sẹ́ Jésù Nílé Káyáfà

      MÁTÍÙ 26:69-75 MÁÀKÙ 14:66-72 LÚÙKÙ 22:54-62 JÒHÁNÙ 18:15-18, 25-27

      • PÉTÉRÙ SẸ́ JÉSÙ

      Nígbà tí wọ́n mú Jésù nínú ọgbà Gẹ́tísémánì, ẹ̀rù ba àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, wọ́n sì sá lọ. Àmọ́ méjì nínú wọn pa dà. Àwọn tó pa dà ni Pétérù “àti ọmọ ẹ̀yìn míì” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àpọ́sítélì Jòhánù. (Jòhánù 18:15; 19:35; 21:24) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń mú Jésù lọ sílé Ánásì ni wọ́n ń yọ́ tẹ̀ lé e. Nígbà tí Ánásì ní kí wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà, Pétérù àti Jòhánù rọra ń tẹ̀ lé wọn bọ̀ lẹ́yìn. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù ikú máa ba àwọn àpọ́sítélì yìí, wọ́n sì lè máa ṣàníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Ọ̀gá wọn.

      Àlùfáà àgbà mọ Jòhánù, torí náà ó rọrùn fún un láti wọnú àgbàlá ilé Káyáfà. Àmọ́ ẹnu ọ̀nà ni Pétérù dúró sí ní tiẹ̀. Nígbà tó yá, Jòhánù pa dà wá bá ìránṣẹ́bìnrin tó ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà náà sọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí Pétérù wọlé.

      Òtútù mú lálẹ́ ọjọ́ yẹn, torí náà, àwọn tó wà nínú àgbàlá yẹn ń yáná. Pétérù jókòó tì wọ́n kóun náà lè yáná, kó sì lè “mọ ibi tọ́rọ̀ yẹn máa já sí” fún Jésù. (Mátíù 26:58) Ìmọ́lẹ̀ iná tí wọ́n dá nínú àgbàlá yẹn wá jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin tó ṣílẹ̀kùn fún Pétérù ríran rí i dáadáa. Ló bá bi í pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” (Jòhánù 18:17) Obìnrin yìí nìkan kọ́ ló dá Pétérù mọ̀, àwọn míì náà wà níbẹ̀, gbogbo wọn ló sì ń fẹ̀sùn kan Pétérù pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni.—Mátíù 26:69, 71-73; Máàkù 14:70.

      Inú bí Pétérù gan-an. Kò fẹ́ kí wọ́n dá òun mọ̀, kódà, ṣe ló rọra ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà. Torí náà, ó sẹ́ pé òun ò mọ Jésù, ó ní: “Mi ò mọ̀ ọ́n, ohun tí ò ń sọ ò sì yé mi.” (Máàkù 14:67, 68) Kódà, ó tún “gégùn-ún, ó sì ń búra,” ohun tó ń sọ ni pé òun ṣe tán láti búra kí wọ́n lè mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ òun, òun ò sì kọ̀ kí ìyà jẹ òun tó bá jẹ́ pé irọ́ lòun pa.—Mátíù 26:74.

      Lákòókò yẹn, wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá ibì kan lókè nínú ilé Káyáfà ni wọ́n wà. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù àtàwọn tó wà nísàlẹ̀ máa rí báwọn èèyàn ṣe ń wọlé, tí wọ́n ń jáde láti wá jẹ́rìí lòdì sí Jésù.

      Torí pé ará Gálílì ni Pétérù, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ ti jẹ́ kó hàn pé irọ́ ló ń pa. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Málíkọ́sì tí Pétérù gé etí rẹ̀ dà nù. Ẹni yẹn wá fẹ̀sùn kan Pétérù pé: “Mo rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọgbà, àbí mi ò rí ọ?” Pétérù tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kẹta, ni àkùkọ bá kọ, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀.—Jòhánù 13:38; 18:26, 27.

      Lásìkò yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bákónì tó wà lókè ni Jésù wà, tó sì ń wo àgbàlá tó wà nísàlẹ̀. Jésù wá yíjú sí Pétérù, ojú àwọn méjèèjì sì ṣe mẹ́rin, ó ká Pétérù lára gan-an. Ẹ wo bó ṣe máa dùn ún tó, nígbà tó rántí ohun tí Jésù sọ ní wákàtí mélòó kan sẹ́yìn àtohun tó tún wá ṣe sí Jésù báyìí. Ó bọ́ síta, ó sì ń sunkún gidigidi.—Lúùkù 22:61, 62.

      Ìyẹn ni pé Pétérù lè sẹ́ Jésù pẹ̀lú bó ṣe fi gbogbo ẹnu sọ pé mìmì kan ò lè mi òun? Pétérù rí i pé ṣe ni wọ́n parọ́ mọ́ Jésù, tí wọ́n sì fẹ̀sùn èké kàn án pé ọ̀daràn paraku ni. Àǹfààní nìyí fún Pétérù láti gbèjà Ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ aláìṣẹ̀, àmọ́ ṣe ló kẹ̀yìn sí Ẹni tó ní “ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun,” tó sì sọ pé òun ò mọ̀ ọ́n rí.—Jòhánù 6:68.

      Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù jẹ́ ká rí i pé tá ò bá múra sílẹ̀ dáadáa, tí àjálù tàbí àdánwò bá dé láìròtẹ́lẹ̀, kódà ẹni tó nígbàgbọ́ tó sì sún mọ́ Ọlọ́run lè juwọ́ sílẹ̀. Torí náà, ó máa dáa kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù jẹ́ ìkìlọ̀ fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run!

      • Báwo ni Pétérù àti Jòhánù ṣe ráyè wọnú àgbàlá ilé Káyáfà?

      • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé nígbà tí Pétérù àti Jòhánù wà nínú àgbàlá náà?

      • Kí ló túmọ̀ sí bí Pétérù ṣe gégùn-ún, tó sì búra?

      • Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù kọ́ wa?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́