Lẹ́tà Pàtàkì Sáwọn Òbí Wọn
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin méjì láti Sípéènì kọ lẹ́tà ìmọrírì sáwọn òbí wọn. Díẹ̀ nìyí lára ohun tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà náà:
Sí ẹ̀yin òbí wa ọ̀wọ́n, Pepe àti Vicenta:
Ibo ni ká ti bẹ̀rẹ̀ ná? Ọ̀rọ̀ pọ̀ táa fẹ́ sọ, ó sì ṣòro láti kọ ọ́ sílẹ̀ ní ṣókí. A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọdún mẹ́tàdínlógún àti mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìwàláàyè wa, àwọn ọdún tó kún fún ìtọ́jú àti ìfẹ́.
Ìgbà gbogbo la mọ èrò yín àti àwọn òfin yín. Tẹ́lẹ̀, nígbà mí-ìn a ò mọ̀dí táa fi ní láti délé níye aago kan pàtó, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, táa rí bí ìgbésí ayé àwọn ọ̀dọ́ yòókù ti dà, àwọn ọ̀dọ́ tí kò lófin ìgbà tó yẹ kí wọ́n wọlé, a wá mọ̀ pé òfin wọ̀nyẹn ti dáàbò bò wá.
Àpẹẹrẹ yín ti ṣíṣàì pa ìpàdé Kristẹni kankan jẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àyàfi tí ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàásù pẹ̀lú yín lọ́jọọjọ́ Sunday ti ràn wá lọ́wọ́. Lárààárọ̀ Sunday a ò kí ń ṣẹ̀ṣẹ̀ béèrè bóyá a máa jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá. A mọ̀ dájú pé a máa lọ!
Ẹ tún tọ́ wa pé ká máa ṣaájò àlejò. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló dé bá wa lálejò, gbogbo ipá yín lẹ sì máa ń sà láti tẹ́ wọn lọ́rùn. Láti kékeré la ti ń fojú wa rí ẹ̀mí yìí, inú wa sì dùn pé a ní àwọn òbí àtàtà.
Kò sẹ́lòmíràn tó mọ̀ wá tàbí tó lóye wa jù yín lọ. Ẹ̀yin lọ̀rẹ́ kòríkòsùn wa, ọ̀rẹ́ táa fi gbogbo ọkàn tán.
Paríparí rẹ̀, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín. Ẹ̀yin lòbí wa, a ò sì lè fi ẹlòmí-ìn pààrọ̀ yín. Bó bá ṣe pé lọ́nà kan ṣá, ó ṣeé ṣe láti tún òbí wa yàn ká sì tún ayé wá ni, láìsí àní-àní, ẹ̀yin la ó yàn, irú ìgbésí ayé táa ti gbé la ó sì tún gbé.
Pẹ̀lú ìfẹnukonu onífẹ̀ẹ́, àwa ọmọbìnrin yín,
ESMERALDA ÀTI YOLANDA