ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 74
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Kò Fi Ní Máa Rẹ̀ Mí Jù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Kò Fi Ní Máa Rẹ̀ Mí Jù?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ló máa ń fà á
  • Ìdí tó fi yẹ kó o mọ̀
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Máa Sùn Dáadáa?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?
    Jí!—2010
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 74
Ọ̀dọ́kùnrin kan ní ohun púpọ̀ láti ṣe, ó fẹ́ lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, ó fẹ́ ṣeré ìmárale, ó fẹ́ ṣeré ìnàjú, ó sì fẹ́ ṣiṣẹ́ ilé ìwé

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Kò Fi Ní Máa Rẹ̀ Mí Jù?

Tó bá jẹ́ pé ó sábà máa ń rẹ̀ ẹ́ gan-an, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Kí ló máa ń fà á

  • Ìdí tó fi yẹ kó o mọ̀

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Kí ló máa ń fà á

  • Mo fẹ́ ṣe tibí, mo fẹ́ ṣe tọ̀hún. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Julie sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ pé ká máa ṣe dáadáa ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, ká máa sunwọ̀n sí i, wọ́n tún ní ká ní àfojúsùn tó nítumọ̀, ká sì lé wọn bá. Nǹkan kì í rọrùn fún wa rárá nítorí bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ wa yìí!”

  • Ìmọ̀ ẹ̀rọ. Fóònù àtàwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń lò ti mú kó rọrùn láti mọ nǹkan tó ń lọ lórí ìkànnì, èyí lè mú kọ́wọ́ wa dí nígbà gbogbo, ó sì lè mú kó rẹ̀ wá gan-an.

  • Oorun. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Miranda sọ pé: “Ilé ìwé, iṣẹ́ àti eré ìnàjú ni kì í jẹ́ káwọn míì tètè sùn, wọ́n sì máa ń tètè jí, bó ṣe máa ń rí fún wọn nìyẹn lọ́pọ̀ ìgbà torí kò sóun tí wọ́n lè ṣe sí i.” Irú nǹkan báyìí lè jẹ́ kó rẹni gan-an.

Ìdí tó fi yẹ kó o mọ̀

Bíbélì gbóríyìn fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára. (Òwe 6:​6-8; Róòmù 12:11) Àmọ́ kò fẹ́ ká máa ṣiṣẹ́ bí aago, tó fi jẹ́ pé a ò ní ráyè bójú tó ìlera wa àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.

“Ṣàdédé ni mo rántí pé mi ò tíì jẹun látàárọ̀, ìdí sì ni pé ọwọ́ mi dí gan-an. Mo ti wá rí i báyìí pé tí wọ́n bá ní kí n ṣe iṣẹ́ kan tí mo mọ̀ pé ó máa pa mí lára, ó máa dáa tí mo bá sọ pé mi ò ní lè ṣe é.”​—Ashley.

Ó ní ìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.” (Oníwàásù 9:4) Tó o bá ń lo ara ẹ lálòjù ó lè dà bíi pé o lágbára bíi kìnnìún. Àmọ́ tó o bá ń jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ jù, ó léwu fún ìlera ẹ.

Ohun tó o lè ṣe

  • Sọ pé oò ní lè ṣe é. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ibi tágbára ẹ̀ mọ, kò sì ní máa ṣe nǹkan tó ju agbára ẹ̀ lọ.

    “Ẹni tó sábà máa ń rẹ̀ jù ni ẹni tó máa ń ṣòro fún láti sọ pé mi ò lè ṣe é, tó jẹ́ pé gbogbo nǹkan ní wọ́n máa ń fẹ́ dáwọ́ lé. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Bópẹ́ bóyá ó máa rẹ̀ ẹ́ gan-an.”​—Jordan.

  • Máa sùn dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Oorun ni wọ́n ń pè ní “oúnjẹ ọpọlọ,” àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni kì í sùn tó wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá, iye wákàtí tó sì yẹ kí wọ́n máa fi sùn nìyẹn.

    “Tí mo bá ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe, mi ò kì í ráyè sùn dáadáa. Àmọ́ lọ́jọ́ tí mo bá sùn dáadáa, màá lókun láti ṣiṣẹ́, inú mi sì máa dùn gan-an lọ́jọ́ kejì.”​—Brooklyn.

  • Ṣètò ara rẹ. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣètò ara rẹ pẹ̀lú àkókò rẹ, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá dàgbà.

    “Tó ò bá fẹ́ máa fún ara rẹ ní wàhálà jù, á dáa kó o ṣètò àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ àwọn apá ibi tó yẹ kó o ṣe àtúnṣe sí kó o má bàa rẹ̀ ẹ́ jù.”​—Vanessa

Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Gianna

“Àwọn kan máa ń jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu torí pé wọ́n fẹ́ rí owó púpọ̀. Àmọ́ 1 Tímótì 6:8 sọ pé ká jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn. Ó dáa ká máa rántí pé, kò yẹ ká máa ṣiṣẹ́ jù nítorí pé à ń lé nǹkan tí kò pọn dandan, ká sì jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn.”​​—Gianna.

Waylon

“Mo máa ń kọ ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́sẹ̀ kan sílẹ̀, ìyẹn ló máa ń ràn mí lọ́wọ́. Ohun ni kì í jẹ́ kí ń lè ṣe ju agbára mi lọ. Ká sọ pé mi ò dá ọgbọ́n yẹn ni, ó máa rẹ̀ mí, mi ò sì ní lè ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kí ń ṣe.”​—Waylon.

Kara

“O lè máa ròó pé, inú rẹ kò ní dùn tó o bá sọ fáwọn kan pé oò ní lè ṣe àwọn nǹkan kan. Àmọ́ mo ti wá rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń wáyè sinmi, inú rẹ á máa dùn, kò sì ní máa rẹ̀ ẹ́ ní gbogbo ìgbà.”​—Kara.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́