ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 96
  • Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Ọlọ́run Jẹ́ Ìṣúra
    Kọrin sí Jèhófà
  • Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
    Kọrin sí Jèhófà
  • Bù Kún Ìpéjọ Wa
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 96

ORIN 96

Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run

Bíi Ti Orí Ìwé

(Òwe 2:1)

  1. 1. Ìwé kan wà tó ṣeyebíye jù lọ,

    Tó ń mú ‘rètí, ayọ̀, àlàáfíà wá.

    Ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ lágbára gan-an;

    Ó ń lani lóye, ó ń fúnni níyè.

    Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìwé yẹn.

    Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ ọ́.

    Àwọn èèyàn yìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an,

    Ó sì fẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn.

  2. 2. Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bí ‘ṣẹ̀dá ṣe bẹ̀rẹ̀,

    Bí Ọlọ́run ṣe dá àgbáyé yìí.

    Wọ́n sọ bọ́kùnrin pípé náà ṣe dẹ́ṣẹ̀,

    Tó sì pàdánù Párádísè náà.

    Wọ́n sọ̀rọ̀ áńgẹ́lì tó di ọlọ̀tẹ̀,

    Tó ta ko Ọlọ́run, tó fẹ̀sùn kàn án.

    Èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àtikú fún wa,

    Ṣùgbọ́n láìpẹ́, Jèhófà yóò ṣẹ́gun!

  3. 3. Inú wa ń dùn gan-an lákòókò táa wà yìí

    Pé Jèhófà ti fọmọ rẹ̀ jọba.

    Èyí ló ń mú ká wàásù ìhìnrere;

    À ń sọ̀rọ̀ ìbùkún ọjọ́ ‘wájú.

    Ìwé ìṣúra tí Jèhófà fún wa,

    Gbogbo ayé ló máa ṣe láǹfààní.

    Ìwé tó yẹ kí gbogbo wa máa kà ni;

    Ó ń jẹ́ ká ní àlàáfíà Ọlọ́run.

(Tún wo 2 Tím. 3:16; 2 Pét. 1:21.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́