ORIN 149
Orin Ìṣẹ́gun
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ kọrin ìyìn sí Jèhófà Bàbá wa lọ́run.
Ó pa Ọba Fáráò, àtàwọn ‘mọ ogun rẹ̀.
Olódùmarè;
Kò sí ẹni tó lè dojú kọ ọ́.
Jèhófà lokọ rẹ̀;
Òun ni ajagunṣẹ́gun.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Ọba ayérayé,
Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ,
Nígbà tó o bá pàwọn ọ̀tá rẹ run,
Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́.
2. Gbogbo ìjọba, ti kóra jọ, wọ́n sì ńta ko Jáà.
Bí wọ́n ṣe lágbára tó,
Ìtìjú yóò bá wọn.
Bíi ti Fáráò,
Wọ́n máa pa run l’Ámágẹ́dọ́nì.
Gbogbo wa yóò gbà pé
Jèhófà lorúkọ rẹ.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Ọba ayérayé,
Gbogbo ayé máa rí agbára rẹ,
Nígbà tóo bá pàwọn ọ̀tá rẹ run,
Wàá sọrúkọ rẹ di mímọ́.
(Tún wo Sm. 2:2, 9; 92:8; Mál. 3:6; Ìfi. 16:16.)