Orin 132
Orin Ìṣẹ́gun
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Kọ orin sí Jáà. Orúkọ rẹ̀ ti wá di gíga.
Àwọn Íjíbítì Ọ̀tá rẹ̀ ṣègbé sókun.
Olódùmarè;
Kò sí Ọlọ́run míì lẹ́yìn rẹ̀.
Jèhófà loókọ rẹ̀;
Ó sì ti jagun ṣẹ́gun.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Ọlọ́run Gíga Jù,
Ìwọ ni lánàá, lónìí, títí láé.
Wàá gbáwọn ọ̀tá rẹ wọlẹ̀ láìpẹ́,
Orúkọ rẹ yóò di mímọ́.
2. Wòó! àwọn ọba Tí kò gba Jèhófà láláṣẹ,
Bí wọ́n tiẹ̀ lágbára
Ju Fáráò lọ, wọ́n gbé.
Ámágẹ́dọ́nì
Ló máa rẹ́yìn gbogbo wọn pátá.
Gbogbo èèyàn yóò mọ
Ẹni tó ńjẹ́ Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, Ọlọ́run Gíga Jù,
Ìwọ ni lánàá, lónìí, títí láé.
Wàá gbáwọn ọ̀tá rẹ wọlẹ̀ láìpẹ́,
Orúkọ rẹ yóò di mímọ́.
(Tún wo Sm. 2:2, 9; 92:8; Mál. 3:6; Ìṣí. 16:16.)