ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 104
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tí mi ò fi lè pọkàn pọ̀?
  • Bó o ṣe lè túbọ̀ pọkàn pọ̀
  • Ṣé Mo Ti Sọ Àwọn Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?
    Jí!—2011
  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlóde Lè Ṣe fún Ìrònú Ẹ?
    Jí!—2021
  • Ṣé Mi Ò Ti Sọ Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?
    Jí!—2021
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 104
Ọmọbìnrin kan ń mú àwọn ohun tó fojú inú wò pé ó máa pín ọkàn òun níyà kúrò níbi tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ohun náà dúró fún orin, fídíò, àtẹ̀jíṣẹ́ àti àwòrán.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?

  • Kí nìdí tí mi ò fi lè pọkàn pọ̀?

  • Bó o ṣe lè túbọ̀ pọkàn pọ̀

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí nìdí tí mi ò fi lè pọkàn pọ̀?

“Mi ò lè ka ìwé tó pọ̀ bí mo ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kìí tiẹ̀ wù mí láti ka ìpínrọ̀ tó gùn mọ́.”​—⁠Elaine.

“Tí mo bá kíyè sí i pé fídíò tí mò ń wò kò yára tó, mo máa ń jẹ́ kí fídíò náà yára kí n lè tètè wò ó tán.”​—⁠Miranda.

“Tí mo bá tiẹ̀ ń pọkàn pọ̀ sórí ohun pàtàkì kan, àmọ́ tí fóònù mi lọ kú, gbogbo nǹkan tó máa gbà mí lọ́kàn ni pé, ‘Ta ló ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi?’”—Jane.

Ṣe ẹ̀rọ ìgbàlódé lè mú kó ṣòro láti pọkàn pọ̀? Àwọn kan sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni. Nicholas Carr tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti agbaninímọ̀ràn nílé iṣẹ́ kọ̀wé pé: “Bá a ṣe ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọ wa a ṣe máa ro tibi ro tọ̀hún, ìyẹn ni pé ọpọlọ wa á bẹ̀rẹ̀ sí yára ronú lórí ìsọfúnni lọ́nà tó já fáfá gan-an, àmọ́ a ò ní lè pọkàn pọ̀ sí i.”a

Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa apá mẹ́ta tó ṣeé ṣe kí ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣàkóbá fún bó o ṣe ń pọkàn pọ̀.

  • Tó o bá ń sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Maria sọ pé: “Nígbà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń bára wọn sọ̀rọ̀ lójúkojú, wọ́n sábà máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí gbá géèmù, wọ́n tiẹ̀ lè máa wo ìkànnì àjọlò tó wà lórí fóònù wọn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ ẹni tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀.”

  • Tó o bá wà ní kíláàsì. Ìwé Digital Kids sọ pé: “Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ kíláàsì ni wọ́n sábà máa ń lo ẹ̀rọ náà láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ka ìsọfúnni lórí íńtánẹ̀ẹ̀tì tàbí kí wọ́n wo ìsọfúnni tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ilé ìwé wọn.”

  • Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Chris tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún (22) sọ pé: “Ó ṣòro gan-an fún mi láti gbójú kúrò lórí fóònù mi ní gbogbo ìgbà tí nǹkan bá wọlé sórí ẹ̀.” Tó o bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé, wákàtí kan tó yẹ kó o lò fún iṣẹ́ àṣetiléwá lè di wákàtí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn rẹ níyà.

Kókó ibẹ̀: Ó máa ṣòro láti pọkàn pọ̀ tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn ẹ níyà kó sì máa darí ẹ.

Ọmọkùnrin kan ṣubú lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tó gbéra.

Ẹni tí kò pọkàn pọ̀ dà bí ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ya ẹhànnà, ibikíbi tó bá wù ú ló máa gbé ẹ lọ

Bó o ṣe lè túbọ̀ pọkàn pọ̀

  • Tó o bá ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’ (Fílípì 2:⁠4) Máa fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè fi hàn pé o gba tàwọn ẹlòmíì rò. Máa wo ojú ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, má sì jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn ẹ níyà.

    “Tó o bá ń bá èèyàn sọ̀rọ̀, gbìyànjú láti má ṣe máa wo fóònù ẹ. Pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ kó o lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún-un.”​—⁠Thomas.

    ÀBÁ: Tó o bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, máa fi fóònù ẹ síbi tó ò ti ní rí i. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, irinṣẹ́ tí kò ní jẹ́ kéèyàn pọkàn nígbà téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ tàbí tó bá ń ṣe nǹkan ni fóònù jẹ́.

  • Tó o bá wà ní kíláàsì. Bíbélì sọ pé: “Ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Tó o bá fi ìlànà yìí sọ́kàn, ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n fún ẹ láyè láti lọ sórí íńtánẹ́ẹ̀tì nínú kíláàsì, má ṣe ka àtẹ̀jíṣẹ́ orí fóònù, má ṣe gbá géèmù tàbí kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tó yẹ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ò ń kọ́.

    “Rí i pé o túbọ̀ ń pọkàn pọ̀ nínú kíláàsì. Máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́. Tó bá ṣeé ṣe, máa jókòó sọ́wọ́ iwájú nínú kíláàsì kó o lè yẹra fún ohun tó lè pín ọkàn ẹ níyà.”​—⁠Karen.

    ÀBÁ: Dípò tí wàá fi máa ṣàkọsílẹ̀ lórí kọ̀ǹpútà, máa ṣàkọsílẹ̀ sórí ìwé. Ìwádìí fi hàn pé ọkàn ẹ ò ní pínyà, wàá sì lè rántí ohun tó o kọ́ dáadáa.

    Ọmọbìnrin kan jókòó lórí tábìlì, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú yàrá rẹ̀. Ó mú báàgì rẹ̀, fóònù àtàwọn ìwé ìròyìn síbi tọ́wọ́ ẹ̀ ò ti lè tó o.
  • Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé: “Ní ọgbọ́n, ní òye.” (Òwe 4:⁠5) Ìkẹ́kọ̀ọ́ ju kéèyàn máa yára ka ìsọfúnni kan kó bàa lè yege ìdánwò, ó gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀ gan-an.

    “Tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń yí ohun fóònù mi walẹ̀ kí n lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mò ń ṣe. Mi ò kí ń wo àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìsọfúnni èyíkéyìí tó bá wọlé. Tí mo bá kíyè sí ohun kan tí kò yẹ kí n gbàgbé, màá kọ ọ́ sílẹ̀.”​—⁠Chris.

    ÀBÁ: Rí i pé àyíká ibi tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀. Jẹ́ kí ibẹ̀ mọ́, kí ẹrù má sì pọ̀ níbẹ̀.

a Látinú ìwé The Shallows​—⁠What the Internet Is Doing to Our Brains.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Katie.

“Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, o lè dà bí ẹni tó kàn tó ń lúwẹ̀ẹ́ lójú omi. Àmọ́ tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ó yẹ kó o dà bí ẹni tó máa ń wẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ omi kó bàa lè rí àwọn ohun tó ṣeyebíye.”—Katie.

Rogelio.

“Téèyàn bá nílera tó dáa, ó máa lè ronú lọ́nà tó já geere. Bí mo ṣe ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ́ kí n túbọ̀ pọkàn pọ̀ dáadáa. Tí mó bá sùn dáadáa, ó tún máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí pé ara mi máa yá gágá lọ́jọ́ kejì, máa sì lè pọkàn pọ̀.”​—⁠Rogelio.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo ni mo ṣe lè kọ́ béèyàn ṣe ń pọkàn pọ̀?

  • Tó o bá ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Máa fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ jẹ ẹ́ lógún, má sì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn ẹ níyà.

  • Tó o bá wà ní kíláàsì. Má ṣe máa wo àtẹ̀jíṣẹ́, má ṣe gbá géèmù tàbí kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tó yẹ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń kọ́.

  • Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Rí i pé kò sí ohun tó lè pín ọkàn ẹ níyà níbi tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kí ibẹ̀ mọ́, kí ẹrù má sì pọ̀ níbẹ̀.

Ẹni tí kò pọkàn pọ̀ dà bí ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ya ẹhànnà, ibikíbi tó bá wù ú ló máa gbé ẹ lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́