ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” Payá
    Ilé Ìṣọ́—2012 | June 15
    • Jèhófà Ṣí Àwọn Ohun Tí Ó “Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́” Payá

      “Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.”—ÌṢÍ. 1:1.

      BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?

      Àwọn apá wo lára ère arabarìbì náà ló ṣàpẹẹrẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà?

      Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe àjọṣe tó wà láàárín Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà àti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?

      Báwo ni Dáníẹ́lì àti Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe bí ìṣàkóso àwọn èèyàn ṣe máa dópin?

      1, 2. (a) Kí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti Jòhánù máa jẹ́ ká mọ̀? (b) Kí ni orí mẹ́fà àkọ́kọ́ lára ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?

      TÁ A bá fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù wéra, ó máa jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ ọ̀pọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí àtàwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kí la lè rí kọ́ nínú ìràn tí Jòhánù rí nípa ẹranko ẹhànnà náà, ohun tí Dáníẹ́lì sọ nípa ẹranko bíbanilẹ́rù kan tó ní ìwo mẹ́wàá àti àlàyé tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère arabarìbì náà tá a bá fi wọ́n wéra? Tá a bá sì ní òye tó ṣe kedere nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, kí ni wọ́n máa sún wa láti ṣe?

      2 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìran tí Jòhánù rí nípa ẹranko ẹhànnà náà. (Ìṣí., orí 13) Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 7, orí mẹ́fà àkọ́kọ́ lára ẹranko náà dúró fún Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù. Gbogbo wọn pátá ló fi hàn pé àwọn kórìíra irú ọmọ obìnrin náà. (Jẹ́n. 3:15) Róòmù, tó dúró fún ìkẹfà lára àwọn orí náà, ló ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Jòhánù kọ ìran tó rí sílẹ̀. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ìkeje lára àwọn orí náà máa gba ipò Róòmù. Agbára ayé wo ni èyí máa jẹ́, kí ló sì máa ṣe sí irú ọmọ obìnrin náà?

      ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ ÀTI ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ DI ALÁGBÁRA

      3. Kí ni ẹranko oníwo mẹ́wàá tí ń bani lẹ́rù náà dúró fún, kí sì ni àwọn ìwo mẹ́wàá náà ṣàpẹẹrẹ?

      3 A lè dá ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà tí ìwé Ìṣípayá orí 13 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ̀ tá a bá fi ìran tí Jòhánù rí wéra pẹ̀lú ìran tí Dáníẹ́lì rí nípa ẹranko oníwo mẹ́wàá tí ń bani lẹ́rù.a (Ka Dáníẹ́lì 7:7, 8, 23, 24.) Ẹranko tí Dáníẹ́lì rí dúró fún Agbára Ayé Róòmù. (Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 12 sí 13.) Nígbà tó di ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Kristẹni, Ilẹ̀ Ọba Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwo mẹ́wàá tó hù jáde ní orí ẹranko tí ń bani lẹ́rù yẹn dúró fún àwọn ìjọba tó jáde wá látinú Ilẹ̀ Ọba Róòmù.

      4, 5. (a) Kí ni ìwo kékeré náà ṣe? (b) Kí ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà dúró fún?

      4 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn ìwo, tàbí àwọn ìjọba tó hù jáde láti orí ẹranko rírorò náà lọ́nà àkànṣe. Ìwo mìíràn “ọ̀kan tí ó kéré,” fa mẹ́ta lára àwọn ìwo náà tu. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ nígbà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń gbókèèrè ṣàkóso, di alágbára. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò lágbára kankan títí di ọ̀rúndún kẹtàdínlógún [17] Sànmánì Kristẹni. Àwọn ẹkùn ilẹ̀ mẹ́ta mìíràn tó jẹ́ abẹnugan lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù ìgbàanì ni, Sípéènì, Netherlands àti Faransé. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mú àwọn alágbára yìí kúrò lọ́kọ̀ọ̀kan, ní ti pé ó gbé wọn kúrò ní àwọn ipò ọlá tí wọ́n wà. Nígbà tó fi máa di ìdajì ọ̀rúndún kejìdínlógún [18], ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìjọba tó lágbára jù lọ lágbàáyé. Àmọ́, kò tíì di ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà.

      5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì di alágbára, àwọn ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí ní Amẹ́ríkà ti Àríwá yapa kúrò lára rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láyè láti di alágbára, síbẹ̀ àwọn ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ṣì ń dáàbò bò ó. Nígbà tí ọjọ́ Olúwa fi máa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti di ilẹ̀ ọba tó gbòòrò jù lọ nínú ìtàn, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sì ti di orílẹ̀-èdè tó láwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé.b Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bí ìkeje lára orí ẹranko náà ṣe fara hàn nìyẹn gẹ́gẹ́ bí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Kí ni orí yìí ṣe sí irú ọmọ obìnrin náà?

      6. Kí ni ìkeje lára orí ẹranko náà ṣe sí àwọn èèyàn Ọlọ́run?

      6 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀, ìkeje lára orí ẹranko náà gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi. (Mát. 25:40) Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà wíwàníhìn-ín òun, àwọn àṣẹ́kù lára irú ọmọ náà á máa bá iṣẹ́ lọ lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:45-47; Gál. 3:26-29) Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà bá àwọn ẹni mímọ́ yìí jagun. (Ìṣí. 13:3, 7) Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó ṣenúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó fòfin de díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde wọn, ó sì ju àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ sẹ́wọ̀n. Ó wá dà bíi pé ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà ti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró fún àkókò kan. Jèhófà rí ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì yìí tẹ́lẹ̀, ó sì fi han Jòhánù. Ọlọ́run tún sọ fún Jòhánù pé a máa mú apá kejì lára irú ọmọ yìí sọjí kí wọ́n lè tún bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò tẹ̀mí lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ìṣí. 11:3, 7-11) Ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní fi hàn pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé lóòótọ́.

      AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÒUN AMẸ́RÍKÀ ÀTI ẸSẸ̀ TÓ JẸ́ ÀDÀPỌ̀ IRIN ÀTI AMỌ̀

      7. Ọ̀nà wo ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà àti ère arabarìbì náà gbà jọra?

      7 Ọ̀nà wo ni ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà àti ère arabarìbì náà gbà jọra? Inú Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti jáde wa, níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ara ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti jáde wá, a lè sọ pé, ará Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni Amẹ́ríkà náà ti jáde wá. Ẹsẹ̀ ère náà wá ńkọ́? A ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. (Ka Dáníẹ́lì 2:41-43.) Àpèjúwe yìí bọ́ sí àkókò kan náà pẹ̀lú àkókò tí ìkeje lára orí ẹranko náà, ìyẹn Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, máa di alágbára. Bí irin tí wọ́n dà pọ̀ mọ́ amọ̀ kò ṣe lè lágbára bí ojúlówó irin, bẹ́ẹ̀ náà ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà kò ṣe lágbára tó agbára ayé Róòmù tó ti jáde wá. Kí ló fà á?

      8, 9. (a) Báwo ni agbára ayé keje ṣe lo agbára tó le bí irin? (b) Kí ni amọ̀ tó wà ní ẹsẹ̀ ère náà dúró fún?

      8 Nígbà míì, ìkeje lára orí ẹranko náà máa ń fi hàn pé òun ní agbára tó le bí irin. Bí àpẹẹrẹ, ó fi hàn pé òun jẹ́ alágbára nígbà tó borí nínú Ogun Àgbáyé Kìíní. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ó tún hàn gbangba pé ìkeje lára orí ẹranko náà ní agbára tó le bí irin.c Lẹ́yìn ogun yẹn, àwọn ìgbà míì wà tí ìkeje lára orí ẹranko náà ti lo agbára rẹ̀ tó le bí irin. Àmọ́, àtìgbà tó ti di agbára ayé ni irin náà ti dà pọ̀ mọ́ amọ̀.

      9 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń wá ọ̀nà láti lóye ohun tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún. Ìwé Dáníẹ́lì 2:41 ṣàpèjúwe ẹsẹ̀ tó jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀ náà pé ó jẹ́ “ìjọba” kan ṣoṣo. Torí náà, amọ̀ náà dúró fún àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn yìí ni kò jẹ́ kó le bí irin gẹ́gẹ́ bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Bíbélì sọ pé amọ̀ náà jẹ́ “ọmọ aráyé,” tàbí àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù. (Dán. 2:43) Lábẹ́ ìṣàkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, àwọn èèyàn máa ń dìde láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn nípasẹ̀ ìpolongo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn tó ń jà fún òmìnira. Àwọn ará ìlú tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù kò jẹ́ kí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà lè lo agbára tó le bí irin. Bákan náà, àwọn èròǹgbà tó ta ko ti ìjọba àti èsì ìbò tó sún mọ́ ti àwọn tí ìjọba bọ́ sí lọ́wọ́ kì í jẹ́ kí àwọn aṣáájú tó gbajúmọ̀ pàápàá lè lo àṣẹ tí wọ́n ní láti ṣe àwọn ohun tí ìjọba wọn fẹ́ gbé ṣe. Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìjọba náà yóò ní agbára lápá kan, yóò sì jẹ́ èyí tí ó gbẹgẹ́ lápá kan.”—Dán. 2:42; 2 Tím. 3:1-3.

      10, 11. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “ẹsẹ̀” ère náà lọ́jọ́ iwájú? (b) Ibo la lè parí èrò sí nípa iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà?

      10 Àjọṣe tímọ́tímọ́ ṣì wà láàárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà títí di àkókò wa yìí, wọ́n sábà máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ tí ọ̀ràn kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ère arabarìbì náà àti ẹranko ẹhànnà náà fi hàn pé, kò sí agbára ayé míì tó máa rọ́pò Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà tó kẹ́yìn yìí kò lágbára bíi Róòmù tí àwọn ẹsẹ̀ ère náà tó jẹ́ irin ṣàpẹẹrẹ, síbẹ̀ kò ní fúnra rẹ̀ kógbá wọlé.

      11 Ǹjẹ́ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà ní ìtumọ̀ pàtàkì kankan? Gbé èyí yẹ̀ wò: Nínú àwọn ìran míì, Dáníẹ́lì sọ àwọn iye kan pàtó, bí àpẹẹrẹ, ó sọ iye àwọn ìwo tó wà ní orí onírúurú àwọn ẹranko tó rí. Àwọn iye yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Dáníẹ́lì ń ṣàpèjúwe ère náà, kò sọ iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀. Torí náà, iye ọmọ ìka ẹsẹ̀ ère náà kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí iye àwọn apá, ọwọ́, ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tí ère náà ní kò ti ṣe pàtàkì. Àmọ́ Dáníẹ́lì dìídì sọ pé ẹsẹ̀ ère náà jẹ́ àdàpọ̀ irin àti amọ̀. Nínú àpèjúwe tó ṣe, a lè parí èrò sí pé Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ni yóò máa ṣàkóso ayé nígbà tí “òkúta” tó dúró fún Ìjọba Ọlọ́run bá kọlu ẹsẹ̀ ère náà.—Dán. 2:45.

      AGBÁRA AYÉ GẸ̀Ẹ́SÌ ÒUN AMẸ́RÍKÀ ÀTI ẸRANKO ẸHÀNNÀ ONÍWO MÉJÌ

      12, 13. Kí ni ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà dúró fún, kí ló sì ṣe?

      12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdàpọ̀ irin àti amọ̀ ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, síbẹ̀ ìran tí Jésù fi han Jòhánù jẹ́ ká rí i pé agbára ayé yìí á máa bá a nìṣó láti máa kó ipa pàtàkì láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Lọ́nà wo? Jòhánù rí ìran ẹranko ẹhànnà oníwo méjì kan tó ń sọ̀rọ̀ bíi dírágónì. Kí ni ẹranko abàmì yìí ṣàpẹẹrẹ? Ìwo méjì ló ní, torí náà orílẹ̀-èdè méjì tó para pọ̀ di agbára ayé kan ṣoṣo ni. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà náà ni ẹranko tí Jòhánù rí yìí, àmọ́ ó ń ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.—Ka Ìṣípayá 13:11-15.

      13 Ẹranko ẹhànnà yìí ń gbé yíyá ère ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù kọ́kọ́ rí lárugẹ. Jòhánù kọ̀wé pé, ère ẹranko ẹhànnà náà ti wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí, síbẹ̀ ó máa tó gòkè wá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ sí àjọ kan tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń gbé lárugẹ nìyẹn, ète tí wọ́n fi dá àjọ yìí sílẹ̀ ni láti mú kí ìjọba ayé wà ní ìṣọ̀kan, kó sì máa ṣojú fún wọn.d Ẹ̀yìn Ogun Àgbáyé Kìíní ni wọ́n dá àjọ yìí sílẹ̀, orúkọ rẹ̀ nígbà yẹn ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àmọ́ àjọ yìí kógbá sílé nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Nígbà ogun yẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run kéde pé ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Ìṣípayá, ère ẹranko ẹhànnà náà máa pa dà gòkè wá. Ó sì jáde wá lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.—Ìṣí. 17:8.

      14. Ọ̀nà wo ni ère ẹranko ẹhànnà náà gbà jẹ́ “ọba kẹjọ”?

      14 Jòhánù pe ère ẹranko náà ní “ọba kẹjọ.” Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìwé Ìṣípayá kò ṣàfihàn rẹ̀ pé ó jẹ́ ìkẹjọ lára orí ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù kọ́kọ́ rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ère ẹranko yẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ yẹn ló fún un ní agbára, ní pàtàkì jù lọ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò alátìlẹyìn rẹ̀. (Ìṣí. 17:10, 11) Àmọ́ ó gba àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba kó lè ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan tó máa kan gbogbo ayé.

      ÈRE ẸRANKO ẸHÀNNÀ NÁÀ PA AṢẸ́WÓ NÁÀ RUN

      15, 16. Kí ni aṣẹ́wó náà ṣàpẹẹrẹ, kí ló sì ti ṣẹlẹ̀ sí ìtìlẹyìn tó ń rí látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?

      15 Jòhánù sọ pé òun rí aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ kan tó jókòó lórí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan, ìyẹn ère ẹranko ẹhànnà náà. Ó ní orúkọ náà “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣí. 17:1-6) Ó bá a mu gan-an pé aṣẹ́wó yìí dúró fún gbogbo ẹ̀sìn èké, èyí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ òléwájú nínú wọn. Àwọn ètò ẹ̀sìn ti ṣètìlẹ́yìn fún ère ẹranko ẹhànnà náà, wọ́n sì ti gbìyànjú láti nípa lórí rẹ̀.

      16 Àmọ́ ṣá o, ní ọjọ́ Olúwa, Bábílónì Ńlá ti fojú ara rẹ̀ rí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tí ìwé Ìṣípayá fi wé omi, tí wọ́n ń gbẹ táútáú. (Ìṣí. 16:12; 17:15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ère ẹranko náà kọ́kọ́ fara hàn, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tó jẹ́ apá pàtàkì nínú Bábílónì Ńlá, ló pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn kò ka àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn sí mọ́, wọn kò sì tì wọ́n lẹ́yìn mọ́. Kódà ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ìsìn ń dá kún rògbòdìyàn tàbí pé ìsìn gan-an ló ń dá a sílẹ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n jẹ́ abẹnugan àtàwọn ajìjàgbara nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ń wá bí wọ́n ṣe máa fi òpin sí ipa tí ẹ̀sìn ń ní lórí àwọn èèyàn.

      17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké láìpẹ́, kí sì nìdí?

      17 Àmọ́, kì í ṣe pé ńṣe ni ẹ̀sìn èké máa bẹ̀rẹ̀ sí í pòórá díẹ̀díẹ̀ o. Aṣẹ́wó yìí á ṣì máa ní ipa tó lágbára lórí àwọn ọba, á máa gbìyànjú láti mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí òun fẹ́, títí tí Ọlọ́run yóò fi fi ohun kan sọ́kàn àwọn tó wà nípò àṣẹ. (Ka Ìṣípayá 17:16, 17.) Láìpẹ́, Jèhófà máa mú kí àwọn olóṣèlú inú ayé Sátánì, tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣojú fún, dojú ìjà kọ ẹ̀sìn èké. Wọn kò ní jẹ́ kó nípa lórí àwọn mọ́, wọ́n á sì ba àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ jẹ́. Ní nǹkan bí ogún tàbí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jọ ohun tí kò lè wáyé. Àmọ́ lóde òní, aṣẹ́wó náà ti ń mì bí ẹni tó fẹ́ já bọ́ lẹ́yìn ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà. Àmọ́, ìyẹn kò fi hàn pé ńṣe ló máa rọra já bọ́ lórí rẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, òjijì ló máa já bọ́, tó sì máa pa run.—Ìṣí. 18:7, 8, 15-19.

      ÀWỌN ẸRANKO NÁÀ PA RUN

      18. (a) Kí ni ẹranko ẹhànnà náà máa ṣe, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? (b) Àwọn ìjọba wo ni Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa pa run? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 17.)

      18 Lẹ́yìn tí ẹ̀sìn èké bá ti pa run, Sátánì á mú kí ẹranko ẹhànnà náà, ìyẹn ètò ìṣèlú Sátánì ti ilẹ̀ ayé, kọjú ìjà sí Ìjọba Ọlọ́run. Níwọ̀n bí kò ti ní ṣeé ṣe fún àwọn ọba ilẹ̀ ayé láti dé ọ̀run, wọ́n á wá kọjú ìbínú wọn sí àwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ló máa yọrí sí ogun Ọlọ́run. (Ìṣí. 16:13-16; 17:12-14) Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe apá kan lára ogun àjàkẹ́yìn yìí. (Ka Dáníẹ́lì 2:44.) Ẹranko ẹhànnà tí Ìṣípayá 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ère rẹ̀ àti ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà, máa ṣègbé.

      19. Kí ló yẹ kó dá wa lójú, kí ló sì yẹ ká máa ṣe báyìí?

      19 Àkókò tí ìkeje lára orí ẹranko ẹhànnà náà ń ṣàkóso la wà yìí. Kò sí orí míì tó máa yọ lára ẹranko yìí mọ́ kó tó pa run. Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló máa wà lójú ọpọ́n nígbà tí ẹ̀sìn èké bá pa run. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì àti ti Jòhánù ti ní ìmúṣẹ gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí. Ó dá wa lójú pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ìparun ẹ̀sìn èké àti ogun Amágẹ́dọ́nì fi máa dé. Ọlọ́run ti ṣí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí payá fún wa kí wọ́n tó wáyé. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a máa fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ìkìlọ̀ yìí? (2 Pét. 1:19) Àkókò nìyí fún wa láti dúró síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà ká sì máa ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn.—Ìṣí. 14:6, 7.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2012 | June 15
    • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

      Ìgbà wo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà di agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?

      ▪ Ère gàgàrà tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti amọ̀ tí Nebukadinésárì Ọba rí kò dúró fún gbogbo àwọn agbára ayé. (Dán. 2:31-45) Àwọn márùn-ún tó ṣàkóso láti ìgbà ayé Dáníẹ́lì tí wọ́n sì ní ipa tó ṣe gúnmọ́ lórí ọ̀ràn àwọn èèyàn Ọlọ́run nìkan ló dúró fún.

      Àpèjúwe tí Dáníẹ́lì ṣe nípa ère náà fi hàn pé ńṣe ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà máa jáde wá látinú Róòmù, kì í ṣe pé ó máa ṣẹ́gun Róòmù. Dáníẹ́lì rí i pé irin tó wà ní ojúgun ère náà ló dé ibi ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀. (Irin náà dà pọ̀ mọ́ amọ̀ ní ibi ẹsẹ̀ àti àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀.)a Èyí fi hàn pé ńṣe ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà máa ti inú ojúgun tó jẹ́ irin náà jáde wá. Ìtàn jẹ́rìí sí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ apá kan Ilẹ̀ Ọba Róòmù tẹ́lẹ̀ rí bẹ̀rẹ̀ sí í mókè. Nígbà tó yá, Amẹ́ríkà náà di orílẹ̀-èdè tí a kò lè kóyán rẹ̀ kéré. Àmọ́, agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kò tíì fara hàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kò tíì jọ gbé ohun pàtàkì kankan ṣe títí di ìgbà yẹn, àfi ní ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní.

      Ní àkókò yẹn, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni “àwọn ọmọ ìjọba náà” ti ń fi ìtara wàásù jù lọ, oríléeṣẹ́ wọn sì wà ní ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York. (Mát. 13:36-43) Àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń fi ìtara wàásù ní àwọn orílẹ̀-èdè tí Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso lé lórí. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Amẹ́ríkà pawọ́ pọ̀ láti bá àwọn olóṣèlú tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn méjèèjì jagun. Nítorí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó túbọ̀ gbilẹ̀ lákòókò ogun, àwọn ìjọba wọ̀nyí ṣe àtakò sí àwọn tí wọ́n jẹ́ apá kan irú ọmọ “obìnrin” Ọlọ́run, wọ́n fòfin de àwọn ìwé tí wọ́n ń tẹ̀, wọ́n sì ju àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù sẹ́wọ̀n.—Ìṣí. 12:17.

      Nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ó hàn kedere pé kì í ṣe apá ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í mókè ni agbára ayé keje bọ́ sí ipò ìṣàkóso. Kàkà bẹ́ẹ̀, èyí ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa.b

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́