ORIN 32
Dúró Ti Jèhófà!
1. Nígbà kan, a kò mohun táa fẹ́ ṣe.
Ìsìn èké sì ń darí ayé wa.
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run
Mú káyọ̀ kún ọkàn wa.
(ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.
Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.
Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,
Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.
2. A dúró ti Ọlọ́run níṣọ̀kan.
À ń wàásù Ìjọba rẹ̀ fáráyé.
Àkókò tó kí kálukú wọn yàn
Láti wá sin Ọlọ́run.
((ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.
Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.
Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,
Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.
3. A kò bẹ̀rù ohun t’Èṣù lè ṣe
Torí Jèhófà ni agbára wa.
Báwọn ọ̀tá tilẹ̀ pọ̀ jù wá lọ,
Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé.
(ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà; Fi ṣe ayọ̀ rẹ.
Kò ní pa ọ́ tì láé; Máa rìn lọ́nà rẹ̀.
Kéde ìhìn rere ti àlàáfíà,
Pé Jésù Ọmọ rẹ̀ máa mú ‘bùkún wá.
(Tún wo Sm. 94:14; Òwe 3:5, 6; Héb. 13:5.)