Orin 27
Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà!
1. Ìgbà kan wà tí òye kò yé wa,
Wọ́n ńfi ẹ̀kọ́ ìsìn èké kọ́ wa;
Ayọ̀ ọkàn wa pọ̀ gan-an láti gbọ́
Ìhìn Ìjọba ọ̀run.
(ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà;
Fií ṣe ayọ̀ rẹ.
Òun kò ní ta ọ́ nù;
Rìn ní ìmọ́lẹ̀.
Kéde ìhìn rere
Ti àlááfíà.
Ìṣàkóso Kristi
Yóò máa gbilẹ̀ láé.
2. A ńfi ìdùnnú sin Ọlọ́run wa,
A sì ńtan èso òtítọ́ kiri,
A ńjẹ́ káwọn ará lè máa yin Jáà,
Àti orúkọ ńlá rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà;
Fií ṣe ayọ̀ rẹ.
Òun kò ní ta ọ́ nù;
Rìn ní ìmọ́lẹ̀.
Kéde ìhìn rere
Ti àlááfíà.
Ìṣàkóso Kristi
Yóò máa gbilẹ̀ láé.
3. A kò bẹ̀rù ohun t’Éṣù lè ṣe.
A mọ̀ pé Jèhófà yóò máa ṣọ́ wa.
Bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀ táwa sì kéré,
Ọlọ́run lagbára wa.
(ÈGBÈ)
Dúró ti Jèhófà;
Fií ṣe ayọ̀ rẹ.
Òun kò ní ta ọ́ nù;
Rìn ní ìmọ́lẹ̀.
Kéde ìhìn rere
Ti àlááfíà.
Ìṣàkóso Kristi
Yóò máa gbilẹ̀ láé.
(Tún wo Sm. 94:14; Òwe 3:5, 6; Héb. 13:5.)