ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 42
  • Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Rẹ Jèhófà
    Kọrin sí Jèhófà
  • A Dúpẹ́, Jèhófà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Bá A Ṣe Lè Ṣe Ọ̀nà Wa Ní Rere
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 42

ORIN 42

Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

Bíi Ti Orí Ìwé

(Éfésù 6:18)

  1. 1. Alágbára, Jèhófà Bàbá wa,

    Kórúkọ ńlá rẹ di sísọ di mímọ́.

    Alèwílèṣe, jọ̀ọ́, à ń bẹ̀ ọ́.

    À ń gbàdúrà kí Ìjọba rẹ dé

    Lákòókò tó o ti ṣètò,

    Ká lè rí ìbùkún gbà.

  2. 2. O ṣé tó ò ń bù kún wa lójoojúmọ́.

    Àwọn ẹ̀bùn rere tó ò ńfún wa pọ̀ gan-an.

    Ò ń fún wa níyè àt’ìmọ́lẹ̀.

    Ò ń fún wa lọ́gbọ́n, ìmọ̀ àtòye.

    A ó máa dúpẹ́, a ó yìn ọ́

    Lójoojúmọ́ ayé wa.

  3. 3. Ìpọ́njú pọ̀ gan-an nínú ayé yìí.

    À ń wojú rẹ, jọ̀wọ́ wá tù wá nínú.

    Gbogbo àníyàn wa là ń kó wá.

    Fún wa lókun, má ṣe jẹ́ ká bọ́hùn.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè ṣèfẹ́ rẹ,

    Ká sì mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ.

(Tún wo Sm. 36:9; 50:14; Jòh. 16:33; Jém. 1:5.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́