MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Wàásù Lójú Àtakò
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun táwọn alátakò ń fẹ́ ni pé kí wọ́n dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Àmọ́, tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin lójú àtakò tó le koko, ìyẹn máa fògo fún Jèhófà.
Ẹ WO FÍDÍÒ A GBỌ́RỌ̀ LÁTẸNU ARÁKÙNRIN DMITRIY MIKHAYLOV, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni wọ́n ṣe ṣenúnibíni sí Arákùnrin Mikhaylov?
Báwo ni Jèhófà ṣe ran Arákùnrin Mikhaylov lọ́wọ́ láti fara dà á?
Báwo ni Jèhófà ṣe lo inúnibíni tí wọ́n ṣe sí Arákùnrin Mikhaylov láti jẹ́ káwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù gbọ́ ìwàásù?