ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 108
  • Ṣó Di Dandan Kéèyàn Púpọ̀ Mọ̀ Mí Lórí Ìkànnì Àjọlò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Di Dandan Kéèyàn Púpọ̀ Mọ̀ Mí Lórí Ìkànnì Àjọlò?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀?
  • “Òkìkí orí ahọ́n”
  • Ṣé ó di dandan káwọn èèyàn púpọ̀ mọ̀ ẹ́, kí wọ́n sì gba tìẹ lórí ìkànnì àjọlò?
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Ṣọ̀rẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Jẹ́ Gbajúmọ̀?
    Jí!—2012
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Kíyè Sára Tó Bá Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Jí!—2014
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 108
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń wo fóònù ẹ̀. Àwọn márùndínláàádọ́rùn-ún (85) ló tẹ àmì pé àwọn fẹ́ràn fọ́tò tó gbé sórí ìkànnì àjọlò.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÈÈRÈ PÉ

Ṣó Di Dandan Kéèyàn Púpọ̀ Mọ̀ Mí Lórí Ìkànnì Àjọlò?

Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Elaine sọ pé: “Tí mo bá rí iye àwọn ọ̀rẹ́ táwọn ọmọ ilé ìwé mi ní lórí ìkànnì àjọlò, mo máa ń ronú pé, ‘Èé, àwọn eléyìí mà mọ̀ọ̀yàn o!’ Kí n má párọ́, mo máa ń jowú wọn.”

Ṣé ó ti ṣèwọ náà báyìí rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ewu tó wà níbẹ̀ tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn púpọ̀ mọ̀ ẹ́ lórí ìkànnì àjọlò.

  • Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀?

  • “Òkìkí orí ahọ́n”

  • Ṣé ó di dandan káwọn èèyàn púpọ̀ mọ̀ ẹ́, kí wọ́n sì gba tìẹ lórí ìkànnì àjọlò?

  • Ṣọ́ra fún “dídọ́gbọ́n gbéra ga”

Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀?

Ní Òwe 22:1, Bíbélì sọ pé “orúkọ rere ló yẹ kéèyàn yàn dípò ọ̀pọ̀ ọrọ̀.” Torí náà, kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn fẹ́ lórúkọ rere tàbí kó fẹ́ káwọn èèyàn gba tiẹ̀ pàápàá.

Àmọ́ nígbà míì, torí pé ó wù ẹ́ gan-an káwọn èèyàn gba tìẹ, o lè má láyọ̀ àyàfi tó o bá dẹni táyé ń fẹ́ lórí ìkànnì àjọlò. Ǹjẹ́ ewu kankan tiẹ̀ wà níbẹ̀? Onya tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni:

“Mo ti rí i táwọn èèyàn kan ń ṣe àwọn nǹkan tí kò bọ́gbọ́n mu, irú bíi kẹ́nì kan bẹ́ láti àjà kejì ilé ìwé mi sílẹ̀ torí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀.”

Àwọn kan tún máa ń gbé fídíò àwọn erékéré tí wọ́n ń ṣe sórí ìkànnì àjọlò torí káwọn ojúgbà wọn lè gba tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń gbé fídíò ara wọn níbi tí wọ́n ti ń jẹ ọṣẹ ìfọṣọ tàbí àwọn oògùn tó lè pa wọ́n lára sórí ìkànnì àjọlò. Àwọn nǹkan tí kò yẹ kí ẹnikẹ́ni dán wò rárá!

Bíbélì sọ pé: “Ẹ máṣe fi . . . ogo asan ṣe ohunkóhun.”—Fílípì 2:3, Bibeli Mimọ.

Rò ó wò ná:

  • Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà gan-an káwọn èèyàn púpọ̀ mọ̀ ẹ́ lórí ìkànnì àjọlò?

  • Ṣé o lè fi ẹ̀mí tàbí ìlera ẹ wewu torí káwọn èèyàn lè gba tìẹ?

    Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

    Leianna.

    “Tó bá ti di pé gbogbo ohun tó bá gbà lo gbọ́dọ̀ fún un, tó fi mọ́ bó o ṣe ń sọ̀rọ̀, bó o ṣe ń múra àti bó o ṣe ń ṣe àwọn nǹkan míì kó o lè di gbajúmọ̀ lórí ìkànnì àjọlò, ewu ti wà níbẹ̀ o. Òkìkí ò tó nǹkan tẹ́nì kan á torí ẹ̀ ba ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ jẹ́ tàbí táá torí ẹ̀ fọwọ́ rọ́ ohun tó gbà gbọ́ sẹ́yìn.”​—Leianna.

“Òkìkí orí ahọ́n”

Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń fẹ̀mí ara wọn wewu torí káwọn èèyàn púpọ̀ lè gba tiwọn. Erica tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún (22) sọ ọgbọ́n míì táwọn èèyàn máa ń dá:

“Ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú làwọn èèyàn kan máa ń gbé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé wọn sórí ìkànnì àjọlò, ìyẹn á wá jẹ́ kó dà bíi pé wọ́n ní àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ gan-an tí wọ́n jọ máa ń wà pa pọ̀ ní gbogbo ìgbà. Àwọn èèyàn á wá rò pé àwọn èèyàn púpọ̀ gba tiwọn.”

Cara tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sọ pé irọ́ làwọn míì máa ń pa ní tiwọn:

“Mo ti rí ibi táwọn kan ti gbé fọ́tò pé wọ́n wà ní patí sórí ìkànnì àjọlò àmọ́ tó jẹ́ ilé ni wọ́n wà.”

Matthew tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún (22) sọ pé òun ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí:

“Mo gbé fọ́tò pé mo wà lórí òkè kan tí wọ́n ń pè ní Mount Everest sórí ìkànnì àjọlò, kẹ́ ẹ sì máa wò ó mi ò dé ilẹ̀ Éṣíà rí!”

Bíbélì sọ pé: “Ó ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

Rò ó wò ná:

  • Ṣé ìwọ náà máa ń tan àwọn èèyàn jẹ lórí ìkànnì àjọlò torí kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gba tìẹ?

  • Ṣé àwọn fọ́tò tàbí ọ̀rọ̀ tó o máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò máa ń sọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an?

    Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

    Hannah.

    “Àwọn èèyàn kan kò kọ ohun tó máa ná wọn káwọn èèyàn lè gba tiwọn. Àmọ́ kí lo fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ẹ́ mọ́, ṣé bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń múra lọ́nà tí kò bójú mu ni àbí bó o ṣe ń fi àwọn ohun tó o ní yangàn? Àbí ìwà dáadáa tó o ní àti ìfẹ́ tòótọ́ tó o ní sáwọn èèyàn? Inú èèyàn máa ń dùn táwọn míì bá gba tiwa, àmọ́ ó máa dáa káwọn èèyàn gba tiwa torí ohun tó ṣe é fi yangàn.”​—Hannah.

Ṣé ó di dandan káwọn èèyàn púpọ̀ mọ̀ ẹ́, kí wọ́n sì gba tìẹ lórí ìkànnì àjọlò?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé táwọn bá fẹ́ lókìkí lórí ìkànnì àjọlò, àfi káwọn láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀, tó máa tẹ àwọn àmì tó fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn fọ́tò tàbí fídíò táwọn gbé sórí ìkànnì. Matthew tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé ó máa ń ṣe òun bẹ́ẹ̀:

“Mo máa ń bi àwọn èèyàn pé, ‘Ọ̀rẹ́ mélòó lo ní lórí ìkànnì àjọlò?’ tàbí ‘Tó o bá gbé nǹkan sórí ìkànnì àjọlò, ẹni mélòó ló máa ń sọ pé àwọn fẹ́ràn ẹ̀?’ Mo tún máa ń dọ̀rẹ́ àwọn tí mi ò mọ̀ rí lórí ìkànnì àjọlò lérò pé wọ́n á dọ̀rẹ́ mi, màá sì lọ́rẹ̀ẹ́ púpọ̀. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi kí n di olókìkí dandan, ńṣe ni ìkànnì àjọlò ń koná mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí.”

Àwọn fọ́tò: 1. Ọ̀dọ́bìnrin kan ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń wo iye àwọn tó fẹ́ràn ohun tó gbé sórí ìkànnì àjọlò. 2. Ọ̀dọ́bìnrin náà ń jẹ́ ìpápánu. 3. Ọ̀dọ́bìnrin náà fọwọ́ dinú mú, ó sì fajú ro.

Ṣe ni òkìkí orí ìkànnì dà bí ìpápánu—ó lè kọ́kọ́ dùn àmọ́ kì í yó èèyàn

Maria tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sọ pé òun ti rí i pé àwọn kan máa ń fi iye àwọn tó fẹ́ràn ohun táwọn gbé sórí ìkànnì pinnu bí wọ́n ṣe gbayì tó, títí kan iye ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní:

“Táwọn èèyàn ò bá fi bẹ́ẹ̀ tẹ àmì tó fi hàn pé àwọn fẹ́ràn fọ́tò tí ọ̀dọ́bìnrin kan gbé sórí ìkànnì, ńṣe lá máa rò pé òun ò rẹwà. Èrò yẹn ò tọ̀nà rárá, ṣe nirú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kàn ń fìyà jẹra wọn lásán.”

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.”—Gálátíà 5:26.

Rò ó wò ná:

  • Ṣé o máa ń fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò?

  • Ṣé bó o ṣe máa láwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ lórí ìkànnì ló ṣe pàtàkì jù sí ẹ àbí bó o ṣe máa láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹ dénú?

    Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

    Joshua.

    “Tó o bá fẹ́ dẹni táyé ń fẹ́ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ gba tìẹ. Kí wọ́n sì tó lè gba tìẹ, à fi kó o dà bíi wọn. Ìyẹn á wá jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí iye àwọn tó ń gba tìẹ, wàá sì fẹ́ máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ní gbogbo ìgbà. Kò sí ohun tó burú nínú káwọn èèyàn gba tiwa àmọ́ tó bá ti ń di pé gbogbo ohun tó bá gbà la máa ṣe káwọn èèyàn lè gba tiwa, nǹkan míì ti wọ̀ ọ́ nìyẹn o.”​—Joshua.

Ṣọ́ra fún “dídọ́gbọ́n gbéra ga”

Ṣé o ti kíyè sí pé àwọn èèyàn kan máa ń fọgbọ́n sọ àwọn àṣeyọrí wọn àmọ́ wọ́n á máa ráhùn bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ kó lè dà bíi pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

  • “Àtìgbà tí mo ti ra mọ́tò tuntun làwọn èèyàn ti fẹ́ kí n máa fi gbé àwọn!”

  • “Ṣe ni inú kàn ń bí mi báwọn èèyàn ṣe ń sọ pé mi ò sanra tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́!”

Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á máa dọ́gbọ́n ráhùn káwọn èèyàn lè rò pé wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì rèé ṣe ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ gbéra ga.

Ìkìlọ̀: Irú ọ̀nà ìgbéraga bẹ́ẹ̀ máa ń lẹ́yìn torí àwọn èèyàn mọ̀ pé agbéraga lonítọ̀hún ó kàn ń díbọ́n ni. Àwọn èèyàn sábà máa ń kórìíra irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ torí wọ́n gbà pé ó sàn kí wọ́n kúkú gbéra ga ju kí wọ́n máa díbọ́n lọ.

Nígbà míì tó o bá fẹ́ gbé fọ́tò tàbí ohunkóhun sórí ìkànnì àjọlò, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí. Ó ní: “Ẹlòmíì ni kó yìn ọ́, kì í ṣe ẹnu tìrẹ.”—Òwe 27:2.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo lo ṣe lè sá fún ìdẹkùn dídi ẹni táyé ń fẹ́ lórí ìkànnì àjọlò?

  • Jẹ́ kí gbogbo ohun tó o máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò sọ irú ẹni tó o jẹ́ ní ti gidi àti ohun tó o gbà gbọ́.

  • Bó o bá ṣe rí gan-an ni kó o ṣe gbé e sórí ìkànnì, má parọ́.

  • Má ṣe retí pé kí àwọn tó pọ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ, tàbí kí wọ́n tẹ àmì tó fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn àwòrán tàbí fídíò tó o gbé síbẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́