ORIN 33
Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 55)
1. “Gbọ́ àdúrà mi,” Jèhófà.
Má fojú pa mọ́ fún mi.
Wo bínú mi ṣe bà jẹ́ tó;
Jọ̀ọ́, fi mí lọ́kàn balẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ
Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.
Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ
Torí pé olóòótọ́ ni.
2. Tí mo bá lè fò bí ẹyẹ,
Màá fò ré kọjá ewu.
Kémi lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀tá
Tí ó ń lépa ẹ̀mí mi.
(ÈGBÈ)
Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ
Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.
Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ
Torí pé olóòótọ́ ni.
3. Ọlọ́run máa ń tù wá nínú,
Ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀.
Yóò máa bá wa gbé ẹrù wa
Torí ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.
(ÈGBÈ)
Ju gbogbo ẹrù ‘nira rẹ
Sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.
Ààbò rẹ̀ máa wà lórí rẹ
Torí pé olóòótọ́ ni.