ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 52-59
“Ju Ẹrù Ìnira Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà”
Dáfídì kojú ọ̀pọ̀ àdánwò tó le koko nígbèésí ayé rẹ̀. Nígbà tó kọ Sáàmù 55, ó ti kojú àwọn ìṣòro bí . . .
Ọ̀rọ̀ Kòbákùngbé
Inúnibíni
Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Lágbára
Àjálù
Àìsàn
Ìwà Ọ̀dàlẹ̀
Kódà nígbà tó dà bíi pé ẹrù ìnira yẹn kọjá agbára Dáfídì, ó ṣì fara dà á. Ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti fún àwọn tó nírú ìṣòro yìí ni: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”
Báwo la ṣe lè fi ohun tí ẹsẹ yìí sọ sílò lóde òní?
Ká máa sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ìṣòro èyíkéyìí tàbí àníyàn ọkàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà
Ká máa wá ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ètò rẹ̀
Ká máa ṣe ohun tá a bá lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì