ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 108
  • Ìfẹ́ Ọlọ́run tí Kì Í Yẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìfẹ́ Ọlọ́run tí Kì Í Yẹ̀
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìfẹ́ Ọlọ́run Tó Dúró Ṣinṣin
    Kọrin sí Jèhófà
  • Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Jẹ́ Adúróṣinṣin
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 108

ORIN 108

Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

Bíi Ti Orí Ìwé

(Àìsáyà 55:1-3)

  1. 1. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.

    Ẹ̀rí fi hàn pó nífẹ̀ẹ́ wa.

    Ó fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo

    Ṣe ìràpadà fáráyé

    Ká lè níyè àìnípẹ̀kun,

    Ká sì láyọ̀ títí ayé.

    (ÈGBÈ)

    Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,

    Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.

    Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.

  2. 2. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.

    Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́rìí sí i.

    Ó gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ‘tẹ́.

    Ó ti sọ ọ́ di ọba lọ́run.

    Ìfẹ́ Ọlọ́run ti wá ṣẹ,

    ’Jọba náà ti fìdí múlẹ̀!

    (ÈGBÈ)

    Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,

    Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.

    Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.

  3. 3. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.

    Kẹ́mìí rẹ̀ mú ká fìfẹ́ hàn,

    Ká sì kọ́ ọlọ́kàn tútù

    Kí wọ́n lè pa òfin Jáà mọ́.

    Ká máa fi ìgboyà wàásù,

    Ká sì níbẹ̀rù Ọlọ́run.

    (ÈGBÈ)

    Gbogbo ẹ̀yin tóùngbẹ ń gbẹ,

    Ẹ wá mumi ‘yè lọ́fẹ̀ẹ́.

    Kẹ́ ẹ mu ún, kọ́kàn yín balẹ̀;

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín.

(Tún wo Sm. 33:5; 57:10; Éfé. 1:7.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́