JẸ́NẸ́SÍSÌ
OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ
1
2
Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje (1-3)
Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé (4)
Ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì (5-25)
Ọlọ́run fi erùpẹ̀ mọ ọkùnrin (7)
Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ (15-17)
Ọlọ́run dá obìnrin (18-25)
3
4
5
6
Àwọn ọmọ Ọlọ́run fẹ́ ìyàwó ní ayé (1-3)
Wọ́n bí àwọn Néfílímù (4)
Ìwà búburú èèyàn ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ (5-8)
Ọlọ́run ní kí Nóà kan áàkì (9-16)
Ọlọ́run kéde pé Ìkún Omi ń bọ̀ (17-22)
7
8
9
Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún aráyé (1-7)
Májẹ̀mú tí Ọlọ́run fi òṣùmàrè dá (8-17)
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà (18-29)
10
Àwọn orílẹ̀-èdè (1-32)
Àtọmọdọ́mọ Jáfẹ́tì (2-5)
Àtọmọdọ́mọ Hámù (6-20)
Àtọmọdọ́mọ Ṣémù (21-31)
11
12
13
Ábúrámù pa dà sí Kénáánì (1-4)
Ábúrámù àti Lọ́ọ̀tì lọ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ (5-13)
Ọlọ́run tún ṣèlérí fún Ábúrámù (14-18)
14
15
16
17
Ábúráhámù yóò di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè (1-8)
Májẹ̀mú nípa ìdádọ̀dọ́ (9-14)
Orúkọ Sáráì yí pa dà sí Sérà (15-17)
Ọlọ́run ṣèlérí pé yóò bí Ísákì (18-27)
18
Áńgẹ́lì mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Ábúráhámù (1-8)
Ó ṣèlérí pé Sérà yóò bímọ; Sérà rẹ́rìn-ín (9-15)
Ábúráhámù ń bẹ̀bẹ̀ torí Sódómù (16-33)
19
Àwọn áńgẹ́lì wá sọ́dọ̀ Lọ́ọ̀tì (1-11)
Wọ́n rọ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọ́n kúrò nílùú (12-22)
Sódómù àti Gòmórà pa run (23-29)
Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ (30-38)
20
21
Wọ́n bí Ísákì (1-7)
Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́ (8, 9)
Ó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ (10-21)
Ábúráhámù bá Ábímélékì dá májẹ̀mú (22-34)
22
23
24
25
Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì (1-6)
Ábúráhámù kú (7-11)
Àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì (12-18)
Wọ́n bí Jékọ́bù àti Ísọ̀ (19-26)
Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ (27-34)
26
Ísákì àti Rèbékà ní Gérárì (1-11)
Wọ́n ń jà torí kànga (12-25)
Ísákì àti Ábímélékì dá májẹ̀mú (26-33)
Àwọn ọmọ Hétì méjì tí Ísọ̀ fẹ́ (34, 35)
27
Jékọ́bù gba ìbùkún lọ́dọ̀ Ísákì (1-29)
Ísọ̀ fẹ́ gba ìbùkún àmọ́ kò ronú pìwà dà (30-40)
Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú (41-46)
28
29
Jékọ́bù pàdé Réṣẹ́lì (1-14)
Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì (15-20)
Jékọ́bù fẹ́ Líà àti Réṣẹ́lì (21-29)
Àwọn ọmọ mẹ́rin tí Líà bí fún Jékọ́bù: Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà (30-35)
30
Bílíhà bí Dánì àti Náfútálì (1-8)
Sílípà bí Gádì àti Áṣérì (9-13)
Líà bí Ísákà àti Sébúlúnì (14-21)
Réṣẹ́lì bí Jósẹ́fù (22-24)
Agbo ẹran Jékọ́bù ń pọ̀ sí i (25-43)
31
Jékọ́bù yọ́ lọ sí Kénáánì (1-18)
Lábánì lé Jékọ́bù bá (19-35)
Jékọ́bù àti Lábánì dá májẹ̀mú (36-55)
32
Àwọn áńgẹ́lì pàdé Jékọ́bù (1, 2)
Jékọ́bù múra láti pàdé Ísọ̀ (3-23)
Jékọ́bù bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì (24-32)
33
34
35
Jékọ́bù mú àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò (1-4)
Jékọ́bù pa dà sí Bẹ́tẹ́lì (5-15)
Réṣẹ́lì bí Bẹ́ńjámínì; Réṣẹ́lì kú (16-20)
Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (21-26)
Ísákì kú (27-29)
36
37
38
39
40
41
Jósẹ́fù túmọ̀ àlá Fáráò (1-36)
Fáráò gbé Jósẹ́fù ga (37-46a)
Jósẹ́fù ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ (46b-57)
42
Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì (1-4)
Jósẹ́fù rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó sì dán wọn wò (5-25)
Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ Jékọ́bù nílé (26-38)
43
Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pa dà sí Íjíbítì; pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì (1-14)
Jósẹ́fù tún rí àwọn arákùnrin rẹ̀ (15-23)
Jósẹ́fù jẹun pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ (24-34)
44
45
46
Jékọ́bù àti agbo ilé rẹ̀ kó lọ sí Íjíbítì (1-7)
Orúkọ àwọn tó ń kó lọ sí Íjíbítì (8-27)
Jósẹ́fù lọ pàdé Jékọ́bù ní Góṣénì (28-34)
47
Jékọ́bù lọ sọ́dọ̀ Fáráò (1-12)
Jósẹ́fù fi ọgbọ́n darí nǹkan (13-26)
Ísírẹ́lì ń gbé ní Góṣénì (27-31)
48
49
50
Jósẹ́fù sin Jékọ́bù sí Kénáánì (1-14)
Jósẹ́fù fi dá àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú pé òun ti dárí jì wọ́n (15-21)
Jósẹ́fù darúgbó, ó sì kú (22-26)