ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 4/8 ojú ìwé 3-4
  • Báwo Ni Ìwà Àwọn Èèyàn Ṣe Rí Láyé Ìsinyìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ìwà Àwọn Èèyàn Ṣe Rí Láyé Ìsinyìí?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Nǹkan Dáa Ju Èyí Lọ Láyé Àtijọ́?
  • Ṣé Ilẹ̀ Yúróòpù Lè Ṣọ̀kan Lóòótọ́?
    Jí!—2000
  • Àìláàbò—Ìṣòro Tó Kárí ayé
    Jí!—1998
  • Ìṣọ̀kan Ilẹ̀ Yúróòpù—Ṣe Nǹkan Pàtàkì Ni?
    Jí!—2000
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Fi Gbilẹ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 4/8 ojú ìwé 3-4

Báwo Ni Ìwà Àwọn Èèyàn Ṣe Rí Láyé Ìsinyìí?

Láàárọ̀ ọjọ́ kan ní oṣù April, lọ́dún 1999, ìlú Littleton dà rú, nítòsí Denver, ìpínlẹ̀ Colorado ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì, tí wọ́n wọ ẹ̀wù òjò dúdú já wọ ilé ìwé gíga kan ládùúgbò náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn fún àwọn ọmọ ilé ìwé àti àwọn olùkọ́. Wọ́n tiẹ̀ ju bọ́ǹbù pàápàá. Wọ́n pa ọmọ ilé ìwé méjìlá àti olùkọ́ kan, ó sì lé ní èèyàn ogún tó fara pa yánnayànna. Ohun tí àwọn ọmọ pàpàǹlagi tó ṣiṣẹ́ ibi náà fi kádìí rẹ̀ ni pé wọ́n gbẹ̀mí ara wọn. Ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún péré, wọ́n ní ìkórìíra gidigidi fún àwùjọ àwọn èèyàn kan.

Ó BANI nínú jẹ́ pé àpẹẹrẹ tí a mẹ́nu kàn lókè kò ṣàjèjì. Àwọn ìwé ìròyìn, rédíò, àti tẹlifíṣọ̀n pẹ̀lú ń sọ nípa irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà jákèjádò ayé. Gẹ́gẹ́ bí Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ètò Ẹ̀kọ́ ti Ìjọba Àpapọ̀ ti sọ, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáfà [11,000] ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú la gbọ́ pé ó ṣẹ̀ lọ́dún 1997 tí àwọn èèyàn ti fìbọn ṣe jàǹbá ní àwọn ilé ìwé ní Amẹ́ríkà. Ní ìlú Hamburg, lórílẹ̀-èdè Jámánì, ìròyìn ìwà jàgídíjàgan tí a gbọ́ lọ́dún 1997 fi ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìpín mẹ́rìnlélógójì lára àwọn tí wọ́n fura sí ló jẹ́ ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

Ìwà ìbàjẹ́ wọ́pọ̀ láàárín àwọn òṣèlú àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ìròyìn kan tí Anita Gradin, tó jẹ́ mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, gbé jáde lọ́dún 1998 fi hàn pé wọ́n ṣírò iye tí ìwà ìbàjẹ́ ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ná wọn lọ́dún 1997 sí iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là. Èyí kan fífagi lé jíjáwèé ìlùfin fún ẹni tó gbé ọkọ̀ síbi tí kò yẹ títí dórí fífi jìbìtì gba owó ìrànwọ́ láti fi ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ tàbí àwọn owó ìrànwọ́ mìíràn tó jẹ́ ti Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù. Wọ́n ti fàyè gba àwọn èèyàn láti purọ́ kó owó púpọ̀ jẹ, kí wọ́n sì ṣe fàyàwọ́ àwọn ohun ìjà àti àwọn oògùn apanilọ́bọlọ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn paraku sì fún àwọn òṣìṣẹ́ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ní rìbá kí wọ́n má bàa tú àṣírí wọn. Gbogbo mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ló kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1999.

Bó ti wù kó rí, kì í ṣe àwọn tó rí já jẹ láwùjọ nìkan ló ń hùwà àìṣòótọ́. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, tó dá lórí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láìgbàṣẹ, fi hàn pé nǹkan bí ìpín mẹ́rìndínlógún nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ owó tí ń wọlé lọ́dún fún Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ló wá láti inú iṣẹ́ táwọn òṣìṣẹ́ tí kò forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba ṣe, tí wọn ò sì san owó orí. Wọ́n ní iye táwọn èèyàn ń pa wọlé láìbófinmu ní Rọ́ṣíà tó ìdajì gbogbo owó tó ń wọlé. Síwájú sí i, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Ẹgbẹ́ Àwọn Aṣèwádìí Jìbìtì sọ pé, àwọn ilé iṣẹ́ tó wà ní Amẹ́ríkà ń pàdánù iye tó lé ní irínwó bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún látàrí owó tàbí ẹrù wọn tí àwọn òṣìṣẹ́ ń jí kó.

Ọ̀pọ̀ àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe tí wọ́n ń wọ́nà láti tan àwọn ọmọdé láti máa ṣèṣekúṣe kiri ló ti ń lọ fi ìsọfúnni sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Agbẹnusọ kan fún Àjọ Aṣèrànwọ́ Fọ́mọdé ní Sweden sọ pé, ńṣe lẹ̀rù túbọ̀ ń ba àwọn èèyàn nípa àwọn ìsọfúnni tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè nínú àwọn ọmọdé. Ní Norway, lọ́dún 1997, ẹgbẹ̀sán ó lé mẹ́tàlélọ́gọ́rin [1,883] èèyàn ló ta àjọ yẹn lólobó nípa ibi tí wọ́n ń kó ìsọfúnni arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè nínú ọmọdé sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, iye àwọn tó ta wọ́n lólobó lọ sókè sí nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000]. Púpọ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n ń lò yìí ni wọ́n ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè tí apá ìjọba tàbí àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ kò ti ká ìwà láabi náà.

Ṣé Nǹkan Dáa Ju Èyí Lọ Láyé Àtijọ́?

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀rù ń bà nítorí bí ìwà àwọn èèyàn ṣe burú láyé ìsinyìí lè ronú kan irú ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn láyé àtijọ́, nígbà ayé àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà. Bóyá wọ́n ti gbọ́ ìtàn pé àwọn èèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ gan-an nígbà náà lọ́hùn-ún àti pé àìlábòsí àti àwọn ìwà dáadáa míì jẹ àwọn èèyàn lógún gan-an níbi gbogbo. Àwọn àgbàlagbà lè ti pìtàn fún wọn nípa ìgbà tí àwọn tó tẹpá mọ́ṣẹ́ ń ran ara wọn lọ́wọ́, tí okùn ẹbí lágbára, tí ọkàn àwọn ọ̀dọ́ sì balẹ̀, tí wọ́n sì máa ń lọ ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́ lóko tàbí níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ọwọ́.

Èyí ló wá fa àwọn ìbéèrè náà pé: Ṣé lóòótọ́ ni ìwà àwọn èèyàn dáa ju ti ìsinyìí lọ láyé àtijọ́? Àbí ìrònú pé ayé ìgbà kan dáa ju ti ìsinyìí lọ ló kàn ń dà wá láàmú ni? Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn òpìtàn àti àwọn ọ̀mọ̀ràn nípa àwùjọ ẹ̀dá ṣe dáhùn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Ìtumọ̀ Ìwà

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí a lo ọ̀rọ̀ náà, “ìwà,” lọ́nà tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìlànà ìwà ọmọlúwàbí àti ìwà burúkú tí àwọn èèyàn ń hù. Àìlábòsí, sísọ òtítọ́, àti ọ̀pá-ìdiwọ̀n gíga nípa ìbálòpọ̀ àti àwọn ọ̀ràn mìíràn sì wà lára rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́