Ìgbà Tí Ìfẹ́ Fọ́jú
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SÍPÉÈNÌ
RONÚ nípa bó ṣe máa rí, ká ni o ń wá ìyàwó, o kì í sì í lè ríran jìnnà, tó sì jẹ́ pé alẹ́ nìkan làwọn ọmọge máa ń jáde. Ìṣòro tí akọ àfòpiná tó jẹ́ ọba ń ní nìyẹn. Ṣùgbọ́n kòkòrò ẹlẹ́wà yìí ní àwọn ànímọ́ kan tó sọ òkè ìṣòro rẹ̀ yìí di pẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, mùkúlú ṣì ni ọ̀rẹ́ wa tó wá dẹni tí ń wá ìyàwó yìí, ó sì tóbi gan-an nítorí pé gbogbo oúnjẹ tó bá rí ló ń kó mì. Nípa bẹ́ẹ̀, tó bá fi máa dìgbà ìrúwé tó ń bọ̀, tó ti máa kúrò ní mùkúlú táa fi di àfòpiná tó ń dán yanran, á ti ní oúnjẹ tó pọ̀ tó níkùn táa máa fi gbéra fún àkókò kúkúrú tó máa fi wà láàyè.
Níwọ̀n bí ọ̀ràn oúnjẹ ti kúrò níbẹ̀, ọba àfòpiná lè wá pọkàn pọ̀ sórí ọ̀ràn wíwá ìyàwó. Ká ní kìkì ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ló fi ń wá abo kiri, pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ ì bá já sí, ṣùgbọ́n ọpẹ́lọpẹ́ pé ó máa ń mú ohun èlò ìtanná kan báyìí, tó wúlò fún un, dání.
Ohun ẹlẹgẹ́ méjì tó jọ ewédò wà lorí àfòpiná náà tó rí kóńkó. Ó jọ pé àwọn ọ̀mùnú tín-ínrín méjì yìí ni ohun tó lágbára jù lọ láyé táa lè fi tọpa òórùn. Síwájú sí i, wọ́n máa ń ṣe é kó lè gbọ́ òórùn “ìtasánsán” fífanimọ́ra tó ń ti ara abo àfòpiná wá.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn abo ẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, a kì í sì í tètè rí wọn, òórùn wọn tó lágbára máa ń jẹ́ kí ó mọ̀ pé wọ́n wà nítòsí. Àwọn ohun méjì tó dà bí ìwo lórí akọ àfòpiná ní agbára ìgbóòórùn gan-an débi pé wọ́n lè gbóòórùn abo tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jìnnà tó kìlómítà mọ́kànlá. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo òkè ìṣòro ọlọ́gbẹ̀ẹ́ni wá di pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì pàdé ọlọ́mọge tó ń wá. Táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kòkòrò, ìfẹ́ lè fọ́jú o—pàápàá nínú èyí tí a ń sọ nípa rẹ̀ yìí.
Àwọn àlàyé fífanimọ́ra àti àpilẹ̀ṣe kíkàmàmà bí irú ìyẹn pọ̀ gan-an nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run! Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe.”—Sáàmù 104:24.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
© A. R. Pittaway