ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 7/8 ojú ìwé 17-29
  • Ìtàn Odò Méjì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtàn Odò Méjì
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tí Ọ̀làjú ti Bẹ̀rẹ̀ Láyé Ọjọ́un
  • Odò Méjì àti Ẹ̀sìn Méjì
  • Báwo Làwọn Odò Náà Ṣe Wà Lónìí?
  • “Kí Àwọn Odò Pàápàá Pàtẹ́wọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Ibi Tí Ìṣòro Náà Ti Le Jù
    Jí!—1997
Jí!—2000
g00 7/8 ojú ìwé 17-29

Ìtàn Odò Méjì

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ

Àwọn odò méjì tó jẹ́ ipa ọ̀nà ìgbẹ́mìíró pàtàkì ní kọ́ńtínẹ́ǹtì Íńdíà ń pèsè ohun ìgbẹ́mìíró fún ẹgbàágbèje èèyàn. Orísun wọn kò jìnnà síra, ó sì wà ní àgbègbè tí òkìtì yìnyín ti ń ṣàn láàárín àwọn òkè tó ga jù lọ lágbàáyé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣàn gba ibi tí ó ré kọjá ẹgbàá ó lé irínwó kìlómítà, ní pàtàkì, wọ́n gba àárín orílẹ̀-èdè méjì kọjá. Wọ́n ṣàn wọnú òkun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn odò náà jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ọ̀làjú ayé àtijọ́. Ẹ̀sìn méjì pàtàkì ni wọ́n fi perí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn èèyàn mọyì ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nítorí àwọn ẹ̀bùn tó ń tinú wọn wá, wọ́n sì ń jọ́sìn ọ̀kan lára wọn, títí di òní olónìí. Kí lorúkọ wọn? Odò Indus àti Ganges ni, Ganga la mọ èyí èkejì sí níhìn-ín ní Íńdíà.

NÍTORÍ pé aráyé nílò omi láti lè máa wà láàyè nìṣó kí nǹkan sì máa gún régé fún wọn, àyíká àwọn odò ni ọ̀làjú ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Níwọ̀n bí a ti máa ń sọ̀rọ̀ odò bí òòṣà àti abo ọlọ́run nígbà mìíràn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìtàn àròsọ ló kún inú àwọn àkọsílẹ̀ tó wà látètèkọ́ṣe. Bí ọ̀ràn ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn nípa ìtàn odò Indus àti Ganga, tí wọ́n tún mọ̀ sí Ganga Ma (Yèyé Ganga) ní Íńdíà.

Lójú àwọn Híńdù àti àwọn Búdà, àwọn òrìṣà ló ń gbé ní Òkè Kailash tó ga ní mítà ẹgbàáta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́rìnlá, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń gbé inú Adágún Manasarovar. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìgbàgbọ́ wọn ni pé odò ńláńlá mẹ́rin náà ṣàn wá látẹnu àwọn ẹranko. Odò Indus ni odò kìnnìún, odò Ganga sì ni odò ọ̀kín.

Àwọn ará Tibet kò gba àwọn àjèjì tó wá ṣàwárí láyè. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1811, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan, tó ń ṣiṣẹ́ abẹ fún àwọn ẹranko, tí Ilé Iṣẹ́ Ìlà Oòrùn Íńdíà gbà, rìnrìn àjò káàkiri ìlú náà láìjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni. Ó ní odò kankan kò ṣàn jáde láti inú Manasarovar, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn odò kéékèèké ṣàn wọnú rẹ̀ láti inú àwọn òkè. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ni wọ́n tó rí orísun odò Indus àti Ganga. Orísun odò Indus wà ní Tibet, ní àríwá òkè Himalaya, inú òkìtì yìnyín tó ń ṣàn sì ni orísun odò Ganga níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Himalaya ní àríwá Íńdíà.

Ibi Tí Ọ̀làjú ti Bẹ̀rẹ̀ Láyé Ọjọ́un

Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn tó ń gbé kọ́ńtínẹ́ǹtì kékeré ti Íńdíà látètèkọ́ṣe rìnrìn àjò gba ìlà oòrùn lọ sí Àfonífojì Indus. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwókù àwọn ohun ọ̀làjú tó gbayì ní àwọn àgbègbè bí Harappa àti Mohenjo-Daro. Ní àwọn ẹ̀wádún tó ṣáájú ní ọ̀rúndún ogún, àwọn àwárí wọ̀nyí yí èrò náà padà pé òpè àti alákòóká ni àwọn ẹ̀yà tó kọ́kọ́ tẹ̀dó sí Íńdíà. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn, ọgbọọgba ni ipò Ọ̀làjú ilẹ̀ Indus àti ti Mesopotámíà wà, tí kò bá tiẹ̀ lajú ju Mesopotámíà lọ. A rí ẹ̀rí bí wọ́n ṣe to àwọn ilé tó wà ní òpópó wọn lẹ́sẹẹsẹ àti ní sẹpẹ́, àwọn ilé àwòṣífìlà àti àwọn ilé gbígbé, ètò tó gbámúṣé fún dída ìdọ̀tí àti ohun ẹ̀gbin nù, àwọn àká ńláńlá, àwọn tẹ́ńpìlì, àti àwọn ibi ìlúwẹ̀ẹ́ tó wà fún ṣíṣe ètùtù, gbogbo ìwọ̀nyí ló tọ́ka pé ó jẹ́ ìlú ìgbàlódé, tó sì lajú. Àwọn àmì tún wà pé wọ́n ń ṣòwò pẹ̀lú Mesopotámíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, odò Indus ni wọ́n ń gbà dé Òkun Arébíà láti àárín ìlú tó jẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà sí ibẹ̀.

Ní gbogbo ọ̀rúndún tó ti kọjá, ó jọ pé àwọn àjálù, yálà àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ni tàbí àkúnya odò ńláńlá, ti sọ ọ̀làjú bíi ti ìgbàlódé tí Àfonífojì Indus ní di yẹpẹrẹ. Èyí kò sì jẹ́ kí wọ́n lè fi bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún yíya táwọn ẹ̀yà alákòóká, tí wọ́n sábà máa ń pè ní ẹ̀yà Aryan, ń ya wọ ibẹ̀ láti Àárín Gbùngbùn Éṣíà. Wọ́n lé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olùgbé ìlú náà kúrò nítòsí odò náà, tó fi di pé àwọn àṣà àtijọ́ tí wọ́n ti ń ṣe láyìíká odò Indus wá kóra lọ sí ìhà gúúsù Íńdíà, níbi tí ìran àwọn Dravidia wà lónìí gẹ́gẹ́ bí àwùjọ pàtàkì lára àwọn ẹ̀yà Íńdíà.

Àwọn ẹ̀yà Aryan kan gba Íńdíà lọ sí ìlà oòrùn, wọ́n sì tẹ̀dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ganga. Nípa bẹ́ẹ̀, láwọn apá ibi tàwọn Aryan wà nínú kọ́ńtínẹ́ǹtì kékeré náà, wọ́n gbé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn aláìlẹ́gbẹ́ lárugẹ ní àríwá Íńdíà, èyí tó ní í ṣe, ní pàtàkì, pẹ̀lú Odò Ganga, bẹ́ẹ̀ ló ṣì wà dòní.

Odò Méjì àti Ẹ̀sìn Méjì

Ìwádìí àwọn awalẹ̀pìtàn fi hàn pé àwọn ohun kan dọ́gba nínú ẹ̀sìn táwọn ará Àfonífojì Indus ń ṣe àti tàwọn ará Mesopotámíà. Wọ́n rí àwọn ohun ìrántí ẹ̀sìn Híńdù, èyí táwọn èèyàn ti lérò tipẹ́tipẹ́ pé ó jẹ́ ẹ̀sìn àwọn ará Aryan, nínú àwókù àwọn ìlú Indus. Àpapọ̀ àwọn òòṣà àti ìgbàgbọ́ ìgbà ìwáṣẹ̀ àwọn Aryan ló para pọ̀ dọ̀kan, tó sì mú ẹ̀sìn Híńdù wáyé. Ńṣe làwọn ará Aryan kọ́kọ́ ń júbà fún Indus, ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ṣí lọ sí ìlà oòrùn tí wọ́n sì tẹ̀dó sí tòsí odò Ganga, ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ òun náà. Lẹ́yìn tí àwọn ọ̀rúndún mélòó kan kọjá, àwọn ìlú bíi Haridwar, Allahabad, àti Varanasi di èyí tó dìde ní tòsí odò Ganga. Orí ẹ̀sìn Híńdù ni wọ́n dá lé. Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn onísìn ló ń rọ́ lọ sí àwọn ìlú náà láti lọ wẹ̀ nínú odò Ganga, tí wọ́n kà sí èyí tó ń múni lára dá, tó sì ń wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù.

Nígbà tí ẹ̀sìn Híńdù pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú odò Indus, ẹ̀sìn Búdà ṣẹ̀ wá láti ìtòsí odò Ganga. Ní Sarnath, ní tòsí Varanasi, ni Siddhārtha Gautama, ẹni tí wọ́n ń pè ní Búdà, ti kọ́kọ́ wàásù fáwọn èèyàn. A gbọ́ pé ó wẹ odò Ganga já níbi tó ti fẹ̀ jù, nígbà tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin.

Báwo Làwọn Odò Náà Ṣe Wà Lónìí?

Omi odò náà kò dára mọ́ lónìí, kò rí bó ṣe rí ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn mọ́, nígbà tí àwọn èèyàn máa ń wọ́ lọ sí bèbè odò Indus àti odò Ganga láti wá ohun ìgbẹ́mìíró. Láti lè máa pèsè fáwọn ará Íńdíà, Pakistan, àti Bangladesh tí wọ́n pọ̀ jaburata, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bójú tó odò náà tìṣọ́ratìṣọ́ra. (Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 16 àti 17.) Ó wá pọn dandan láti máa ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí ó ju àárín orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo lọ tí àwọn odò náà ti ṣàn kọjá. Lára àwọn ohun tí Pakistan ti gbé ṣe ni ètò ìbomirinlẹ̀, wọ́n ṣe Ìsédò Tarbela, èyí tí gígùn rẹ̀ jẹ́ kìlómítà mẹ́ta, tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà mẹ́tàlélógóje. Ó jẹ́ ọ̀kan lára èyí tó tóbi jù lọ lágbàáyé, iyẹ̀pẹ̀ tí wọ́n kó kún ibẹ̀ á gba àyè mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́jọ ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [148,500,000] mítà níbùú lóròó táa bá dà á sílẹ̀. Ìsédò Farakka, tí wọ́n ṣe sí odò Ganga, mú kó dájú pé omi tó pọ̀ tó, tí kò sì dáwọ́ dúró yóò máa wọnú odò náà nítorí àwọn ọkọ̀ òkun tó ń pọ̀ sí i, tí wọ́n ń wọlé nítòsí Etíkun Calcutta.

Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn àwọn odò púpọ̀, ìṣòro pàtàkì ni ọ̀ràn dída ìdọ̀tí sínú odò Ganga jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọdún 1984, ìjọba ilẹ̀ Íńdíà gbé Àjọ Amúṣẹ́ṣe Lórí Ọ̀ràn Odò Ganga dìde, àjọ yìí múra tán láti ṣiṣẹ́ gan-an ni. Wọ́n jíròrò lórí sísọ àwọn ìdọ̀tí di ajílẹ̀ tàbí sísọ ìdọ̀tí di gáàsì, dídarí àwọn omi tí ń ṣàn wọnú odò náà gba ibòmíràn, àti kíkọ́ àwọn ilé iṣẹ́ tí yóò máa ṣàtúnṣe àwọn ìdọ̀tí tó jẹ́ kẹ́míkà.

Síbẹ̀, ohun tó ń ṣèdíwọ́ fún mímú kí àwọn odò tó wà láyé lẹ́wà kí wọ́n sì mọ́ tónítóní gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ ti wá ń le ju agbára àwọn àjọ tí ẹ̀dá ènìyàn gbé kalẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe ìṣòro náà láìpẹ́. Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀, ‘àwọn odò pàápàá yóò pàtẹ́wọ́’ nígbà tí gbogbo ilẹ̀ ayé bá di párádísè.—Sáàmù 98:8.

[Àpótí/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Alagbalúgbú Odò Ńlá Indus

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ odò ló wọ́ jọ di odò Indus, àríyànjiyàn ti pọ̀ lórí ibi tó jẹ́ orísun odò náà gangan. Ṣùgbọ́n ó dájú pé Himalaya ni odò ńlá yìí ti ṣàn wá. Bí odò yìí ti ń ṣàn gba apá àríwá ìwọ̀ oòrùn, tó sì ṣàn wọnú àwọn odò mìíràn, ó ṣàn ní ọ̀ọ́dúnrún ó lé ogún kìlómítà la òkè Tibet tí orí rẹ̀ tẹ́jú kọjá, èyí tó wà ní “ṣóńṣó orí àgbáyé.” Bí odò náà ṣe ń sún mọ́ ààlà Íńdíà lágbègbè Ladakh, ó ṣàn gba àárín àwọn òkè ńláńlá, ó ṣẹ́rí gba ìsàlẹ̀ àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta, ó sì wá di ọ̀nà láàárín àwọn òkè Himalaya àti Karakoram. Ní báyìí, tó ti wà ní agbègbè ìpínlẹ̀ Íńdíà, ó ṣàn sọ̀ kalẹ̀ ní ibi tí ó ga ní ẹgbàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [3,700] mítà nígbà tó fi máa rin ibi tó jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀ta [560] kìlómítà. Nígbà tó ń ṣàn kiri yìí, ó gba ìhà àríwá, lẹ́yìn náà ló wá ṣẹ́rí bìrí gba etí ìhà ìwọ̀ oòrùn Himalaya, níbi tí odò Gilgit ti ṣàn wọnú rẹ̀, èyí tó ń tú jáde láti inú àpáta Hindu Kush. Lẹ́yìn náà, odò náà la Pakistan kọjá lọ sí ìhà gúúsù. Bí odò Indus ṣe ń rá pálá, ló ń jà gùdù gba àárín àwọn òkè ńlá, nígbà tó yá, ó ṣàn dé ibi tó tẹ́jú, ó sì ṣàn gba Punjab kọjá. Orúkọ yìí túmọ̀ sí “Odò Márùn-⁠ún,” nítorí pé odò ńlá márùn-⁠ún ló ṣàn pàdé odó Indus níbẹ̀, ìrísí wọ́n dà bí àwọn ìka ọwọ́ òmìrán tó yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn odò náà sì ni odò Beas, Sutlej, Ravi, Jhelum, àti Chenab, gbogbo wọn sì jọ ṣàn lọ síbi tó parí ìrìn àjò rẹ̀ sí, èyí tó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó dín ọgọ́rùn-⁠ún [2,900] kìlómítà.

Odò Ganga Tó Di Àkúnlẹ̀bọ

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-⁠ún kìlómítà sí ìhà gúúsù orísun odò Indus ní òkè ńlá Himalaya ni odò Ganga ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò tirẹ̀ tó lé ní ẹgbàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [2,500] kìlómítà lọ síbi Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Bengal. Láti ibì kan tí gíga rẹ̀ lé ní ẹgbọ̀nkàndínlógún ó lé àádọ́rin [3,870] mítà, orísun odò náà ń tú jáde láti ibi ìṣàn òkìtì yìnyín kan tó yọ síta tó jọ ẹnu màlúù, wọ́n pè é ní Gaumukh lédè Hindi, òun ló di odò tí wọ́n ń pè ní Bhagirathi. Odò mìíràn tó ń jẹ́ Alaknanda ṣàn wọnú rẹ̀ láti ibì kan tó jẹ́ nǹkan bí igba ó lé mẹ́rìnlá kìlómítà sí orísun rẹ̀, ní Devaprayag. Àwọn odò méjèèjì yìí, papọ̀ pẹ̀lú Mandakini, Dhauliganga, àti Pindar ló wá di odò Ganga.

Bí odò Ganga ti ṣàn gba gúúsù ìlà oòrùn kọjá ní kọ́ńtínẹ́ǹtì kékeré náà, àwọn odò ńláńlá mìíràn tún ṣàn wọnú rẹ̀, àwọn bí odò Yamuna ní ìlú Allahabad ní Íńdíà àti odò Brahmaputra ńlá ní Bangladesh. Nítorí fífẹ̀ tí odò Ganga àti àwọn odò tó ṣàn wọnú rẹ̀ fẹ̀ bí abẹ̀bẹ̀, wọ́n ń pèsè omi fún ìdá mẹ́rin gbogbo ilẹ̀ Íńdíà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lẹ́tù lójú láyìíká odò Ganga. Odò náà ṣàn gba ilẹ̀ tó tóbi tó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì [1,035,000] kìlómítà níbùú lóròó, ó sì ń pèsè fún nǹkan bí ìdá mẹ́ta àwọn olùgbé ilẹ̀ Íńdíà, tí wọ́n ti lé ní bílíọ̀nù kan báyìí, ní ọ̀kan lára àwọn àgbègbè táwọn olùgbé ibẹ̀ pọ̀ jù lọ lágbàáyé. Ó tún fẹ̀ gan-⁠an sí i ní Bangladesh, ńṣe ló dà bí òkun kan láàárín orílẹ̀-èdè, àwọn ọkọ̀ ojú omi sì wà lórí rẹ̀ lóríṣiríṣi. Lẹ́yìn náà ni odò Ganga wá pín sí àwọn odò ńláńlá mélòó kan àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ odò kéékèèké tó mú kó di ọ̀kan lára ẹnu odò tó tóbi jù lọ lágbàáyé.

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Tibet

PAKISTAN

Odò Indus

Odò Jhelum

Odò Chenab

Odò Sutlej

Ìlú Harappa

Ìlú Mohenjo-Daro

ÍŃDÍÀ

Odò Ganga

Odò Yamuna

Odò Brahmaputra

Ìlú Allahabad

Ìlú Varanasi

Ìlú Patna

Ìlú Calcutta

BANGLADESH

NEPAL

BHUTAN

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwọn àwòrán]

Àwọn onísìn Híńdù ń wẹ̀ nínú odò Ganga

[Credit Line]

Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ ti Sean Sprague/⁠⁠Panos Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́