Èé Ṣe Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Nífẹ̀ẹ́ Sí Ìbẹ́mìílò?
Ìbẹ́mìílò ni wọ́n túmọ̀ sí “ìgbàgbọ́ pé nǹkan kan tó jẹ́ ẹ̀mí nínú ara ènìyàn máa ń la ikú já, ó sì lè bá àwọn alààyè sọ̀rọ̀, ó sì sábà máa ń jẹ́ nípasẹ̀ ẹni kan.”
NÍ ỌDÚN 1998, ìwé kan tó ṣàlàyé bí èèyàn ṣe lè bá òkú sọ̀rọ̀ wọ́pọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tó fi jẹ́ pé kíákíá lo di ìwé tó tà jù lọ tí wọ́n máa ń sọ nínú ìwé ìròyìn New York Times.
Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn ní Moscow, àwọn òṣèlú àti oníṣòwò tí wọ́n ń sanwó gegere láti ṣèwádìí ń sáré lọ bá àwọn arínúróde àti ẹgbẹ́ abẹ́mìílò.
Ní Brazil, omilẹgbẹ èèyàn ló máa ń wo àwọn eré onítàn tí ń fi ìbẹ́mìílò hàn lórí tẹlifíṣọ̀n.
Ní ti ọ̀pọ̀ èèyàn ní Áfíríkà tàbí ní Éṣíà, ṣe ni ìbẹ́mìílò wọ́pọ̀ bí ìgbà tí èèyàn bá ń gba pààrọ̀ lọ́jà.
Kí Ló Dé Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Yí sí Ìbẹ́mìílò
Ọ̀pọ̀ ń yí sí ìbẹ́mìílò láti wá ìtùnú lẹ́yìn tí èèyàn wọn bá kú. Nípasẹ̀ àwọn oṣó, wọ́n lè rí ìsọfúnni àkànṣe gbà tó dà bíi pé látọ̀dọ̀ ẹni tó kú náà ló ti wá. Nítorí ìyẹn, irú àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yẹn sábà máa ń gbà pé èèyàn àwọn tó kú ṣì wà láàyè, àti pé bíbá òkú sọ̀rọ̀ yóò ran àwọn lọ́wọ́ láti lè fara da àdánù àwọn.
Àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ ìbẹ́mìílò nítorí pé wọ́n sọ fún wọn pé àwọn ẹ̀mí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìwòsàn sí àìlera wọn, láti bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́, láti ṣàṣeyọrí nínú eré ìfẹ́ wọn, láti yanjú ìṣòro inú ìgbéyàwó, tàbí láti rí iṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ló sì wà tó jẹ́ pé ṣíṣòfíntótó ni wọ́n bá débi ìbẹ́mìílò.
Ṣùgbọ́n o, ìdí mìíràn tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn fi ń yí sí ìbẹ́mìílò jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ògbógi kan nínú iṣẹ́ yìí ṣe sọ, nítorí pé wọ́n ti kọ́ wọn pé ìbẹ́mìílò jẹ́ “àfikún ìjọsìn” tó wà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìsìn Kristẹni.” Bí ọ̀ràn ìsìn ṣe rí ní Brazil jẹ́ àpẹẹrẹ ohun táa ń sọ yìí.
Ilẹ̀ Brazil ni àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì ti pọ̀ jù lọ láyé yìí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Sol Biderman ṣe sọ, “àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ojúlówó oníṣọ́ọ̀ṣì ló máa ń tan àbẹ́là nídìí pẹpẹ tó ju ẹyọ kan lọ, tí wọ́n sì máa ń rò pé kò sí ìyàtọ̀ kankan níbẹ̀.” Ní tòótọ́, Veja, ìyẹn ìwé ìròyìn tó ń jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Brazil, sọ pé ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò ní Brazil ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó ti batisí, tó máa ń lọ sí Máàsì déédéé. Èyí tó tún wá pabanbarì níbẹ̀ ni pé, kódà àwọn àlùfáà kan ń lọ sípàdé àwọn abẹ́mìílò, a wá lè rí ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ fi ń ronú pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba kíkàn sí àwọn ẹ̀mí láti rí ìtùnú àti ìtọ́sọ́nà. Ṣùgbọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ló rí?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Onírúurú Àṣà Ìbẹ́mìílò
Bíbá ẹ̀mí lò lè jẹ́ lílọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ oṣó, bíbéèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú, tàbí kíkíyèsí àwọn àmì àpẹẹrẹ. Àṣà ìbẹ́mìílò kan tó wọ́pọ̀ ni iṣẹ́ wíwò, ìyẹn ni gbígbìyànjú láti wádìí nípa ọjọ́ ọ̀la tàbí nípa ohun tí èèyàn kò mọ̀ nípasẹ̀ ìrànwọ́ àwọn ẹ̀mí. Àwọn oríṣi iṣẹ́ wíwò tó wà ni, ìwòràwọ̀, wíwo kírísítálì, títúmọ̀ àlá, wíwo àtẹ́lẹwọ́ láti fi sọ àsọtẹ́lẹ̀, àti lílo káàdì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire.