ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 8/8 ojú ìwé 14-16
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—2000
Jí!—2000
g00 8/8 ojú ìwé 14-16

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 16. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Ta ni àpọ́sítélì Jòhánù rí “ní àárín àwọn ọ̀pá fìtílà,” tó ń fi iṣẹ́ rán an sí àwọn ìjọ méje? (Ìṣípayá 1:13)

2. Kí ni Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé kí a ṣe dípò jíjẹ́ kí “ibi ṣẹ́gun” wa? (Róòmù 12:21)

3. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì”? (Mátíù 5:41)

4. Kí ni Pétérù gba àwọn Kristẹni aya níyànjú láti máa fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ dípò irun dídì àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà? (1 Pétérù 3:3, 4)

5. Kí ni Aísáyà pe Ábúráhámù, èyí tó túmọ̀ sí pé òun ni ẹ̀dá ènìyàn tí í ṣe bàbá fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (Aísáyà 51:1)

6. Kí ló dé tí Dáfídì fi kọ̀ láti mu omi tí àwọn jagunjagun mẹ́ta bù wá fún un láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà tó wà nínú hòrò Ádúlámù? (2 Sámúẹ́lì 23:15-17)

7. Kí ni Bátí-ṣébà ń ṣe nígbà tí Dáfídì kọ́kọ́ rí i? (2 Sámúẹ́lì 11:2)

8. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé a fi kọ lẹ́tà sára ọkàn-àyà àwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì dípò yíǹkì? (2 Kọ́ríńtì 3:3)

9. Kí ni Jèhófà fi palẹ̀ àwọn eéṣú tó fi ṣe ìyọnu kẹjọ mọ́ kúrò nílẹ̀, tí kò fi ṣẹ́ ku ìkankan ní Íjíbítì? (Ẹ́kísódù 10:19)

10. Èé ṣe tí Jèhófà fi pa Sọ́ọ̀lù? (1 Kíróníkà 10:13)

11. Ìlú tí etíkun wà wo ni Pọ́ọ̀lù ti tinú ọkọ̀ kan bọ́ sí òmíràn nígbà tí wọ́n ń mú un lọ sí Róòmù bí ẹlẹ́wọ̀n? (Ìṣe 27:5)

12. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òún bìkítà nípa àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba ní Ísírẹ́lì ìgbàanì? (Ẹ́kísódù 22:22-24; Diutarónómì 24:17-21)

13. Orúkọ wo ni wọ́n pe pápá tí àwọn àlùfáà fi owó tí Júdásì dà sínú tẹ́ńpìlì rà? (Mátíù 27:3-8; Ìṣe 1:19)

14. Èé ṣe tí Pétérù fi bá Símónì wí gidigidi nítorí pé ó fi owó lọ̀ wọ́n kí wọ́n lè fún un ní agbára tí yóò fi máa fún àwọn ènìyàn ní ẹ̀mí mímọ́? (Ìṣe 8:20, 21)

15. Ẹni ọdún mélòó ni Sárà nígbà tó bí Ísákì? (Jẹ́nẹ́sísì 17:17)

16. Orílẹ̀-èdè wo ni Elimélékì àti Náómì, aya rẹ̀, kó lọ nítorí ìyàn, tí ọmọ rẹ̀ Málónì ti fẹ́ Rúùtù? (Rúùtù 1:1-4)

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Jésù Kristi, ẹni tí Jòhánù ṣàpèjúwe bí “ẹnì kan tí ó dà bí ọmọ ènìyàn”

2. “Máa fi ire ṣẹ́gun ibi”

3. Ó fi ṣàpèjúwe pé ó yẹ kí a gbà láti ṣe ohun tó bófin mu láìjanpata

4. “Aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù”

5. “Àpáta tí a ti gbẹ́ yín jáde”

6. Nítorí pé ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ wọn, tí wọ́n fi wewu kí wọ́n tó rí i bù wá

7. Ó ń wẹ̀

8. “Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè”

9. Ẹ̀fúùfù ìwọ̀ oòrùn líle gan-an ló gbá wọn sínú Òkun Pupa

10. Ó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà nítorí kò tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ àti nítorí wíwádìí nǹkan lọ́wọ́ abẹ́mìílò

11. Máírà ní Líkíà

12. Ó pèsè fún ire àti ohun ìgbẹ́mìíró wọn

13. Ákélídámà, tàbí “Pápá Ẹ̀jẹ̀”

14. Ó fi èrò tí kò tọ́ hàn nípa gbígbìyànjú láti ra “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run,” ọkàn-àyà rẹ̀ “kò [sì] tọ́ lójú Ọlọ́run”

15. Ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni

16. Móábù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́