Ìrèké—Àràbà Ni Láàárín Àwọn Koríko
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ
KÍ NI yóò ṣẹlẹ̀ tí kò bá sí ṣúgà mọ́? Àsọdùn ni pé ayé ò ní yí mọ́—ṣùgbọ́n lọ́nà tó gbàfiyèsí, ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni a máa yí padà bí kò bá sí ṣúgà mọ́. Òótọ́ ni, ní apá ibi púpọ̀ jù lọ lágbàáyé lónìí, ṣúgà jíjẹ ti wá di apá kan ìgbésí ayé ojoojúmọ́, èyí sì ti wá sọ ṣúgà ṣíṣe di òwò tó kárí ayé.
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, láti Cuba títí dé Íńdíà àti láti Brazil títí dé Áfíríkà, ló ń dáko ìrèké. Ní gidi, nígbà kan, ṣúgà ṣíṣe wọ́pọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí òwò tó tóbi jù lọ tó sì mówó wọlé jù lọ. A lè sọ pé ṣàṣà làwọn ohun ọ̀gbìn tó nípa lórí ayé tó ìrèké.
Ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa ohun ọ̀gbìn àgbàyanu yìí? Ó dáa nígbà náà, tẹ̀ lé wa ká lọ sí àgbègbè kan ní Queensland, ní Ọsirélíà, níbi tí wọ́n ti ń dáko ìrèké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrèké tó ń ti àgbègbè yìí jáde kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀nà tó pójú owó tí wọ́n ń gbà dáko níbẹ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi í ṣe nǹkan ló mú kí ibẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọ́n ti ń kó ògidì ṣúgà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè jù lọ lágbàáyé.
Ṣíṣèbẹ̀wò sí Àgbègbè Tí Ìrèké Wà
Ooru ń mú, ilẹ̀ ibẹ̀ sì ní ọ̀rinrin. Oòrùn tó mú ganrínganrín ń pa oko ìrèké kan tí àwọn ìrèké inú rẹ̀ ti gbó dáadáa. Ẹ̀rọ ńlá kan tó jọ ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń kórè àlìkámà rọra ń lọ láàárín oko àwọn ìrèké gíga náà, ó ń bẹ́ àwọn ìrèké náà, bó ti ń bẹ́ wọn ló ń dà wọ́n sínú ọkọ̀ ọlọ́mọlanke kan tó ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Láìpẹ́, omi ṣúgà bẹ̀rẹ̀ sí jáde lára àwọn ìrèké tí wọ́n ń fún, òórùn ọ̀rinrin, dídùn, sì ń fẹ́ yẹ́ẹ́ nínú atẹ́gùn. Inú oko ni omi ṣíṣeyebíye tó ń jáde láti inú koríko àgbàyanu náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ títí tó fi wá dénú àwo ṣúgà lórí tábìlì rẹ.
Nígbà kan tí kò tíì pẹ́ púpọ̀, àdá ni wọn fi máa ń bẹ́ àwọn ìrèké náà níhìn-ín ní Ọsirélíà pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára, wọ́n ṣì ń ṣe bẹ́ẹ̀ dọ̀la ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè níbi tí wọ́n ti ń kórè ìrèké. Fojú inú wo bí ì bá ṣe rí. Àwọn òṣìṣẹ́ ń fi àdá bẹ́ ìrèké. Ọ̀wọ́ àwọn tí ń làágùn yọ̀bọ̀ bí wọ́n ti ń bẹ́ ìrèké rọra ń bá iṣẹ́ lọ láàárín oko ìrèké náà. Bí ìgbà tí àwọn sójà tò lọ́nà tó bára jọ, àwọn òṣìṣẹ́ náà fọwọ́ kan kó àwọn ìrèké bíi mélòó kan tó hù láti ìdí kan náà, wọ́n sì fagbára tì wọ́n sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kí wọ́n lè rí gbòǹgbò tí gbogbo wọn ti jáde wá. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ́ wọn fàì! fàì! Bí àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣe ń fi gbogbo agbára gbé àdá wọn ni wọ́n ń bẹ́ àwọn igi ìrèké náà délẹ̀. Bí wọ́n bá ti nà wọ́n gbọọrọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, wọ́n á bọ́ sídìí ìdìpọ̀ àwọn ìrèké mìíràn. Jákèjádò ayé, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe é lọ́nà yìí mọ́, nítorí pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti ń lo ẹ̀rọ nísinsìnyí.
Ní pàtàkì, àgbègbè etíkun ni ìrèké wà ní Ọsirélíà, ó jẹ́ ilẹ̀ tóóró tó gùn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún [2,100] kìlómítà, tó fi jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ Òkìtì Iyanrìn Etíkun Ńlá tó gbajúmọ̀ náà. (Wo àpilẹ̀kọ “Ṣíṣèbẹ̀wò sí Òkìtì Iyanrìn Etíkun Ńlá Náà,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde June 8, 1991, Gẹ̀ẹ́sì) Ooru tó máa ń mú tí ojú ọjọ́ sì máa ń ní ọ̀rinrin jálẹ̀ ọdún ń jẹ́ kí ìrèké ṣe dáadáa níhìn-ín, àti pé látinú àwọn oko kéékèèké tí ìdílé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [6,500] àgbẹ̀ tó ń gbìn ín ń dá, tó wà káàkiri etíkun bí àwọn èso àjàrà tó ṣù jọ lórí igi àjàrà ni wọ́n ti ń rí owó ìgbọ́bùkátà wọn.
Lẹ́yìn tí a wakọ̀ jìnnà, a rí ìlú tí wọ́n ti ń ṣe ṣúgà náà, Bundaberg, ní etíkun àárín gbùngbùn Queensland. Bí a ti ń lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kékeré kan, a rí ohun tó yà wá lẹ́nu gan-an, a rí oko ìrèké tó lọ salalu tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́! Oríṣiríṣi àwọ̀ ni wọn ní! Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan oko ìrèké táa rí ṣe gbó sí yàtọ̀ síra, nítorí náà, wọ́n dà bí aṣọ àlẹ̀pọ̀ tó ní àwọ̀ aláràbarà tí ń tàn yòò, tó jẹ́ àwọ̀ ewé àti àwọ̀ wúrà, tí àwọn àgbègbè tí wọn ò gbin nǹkan kan sí lọ́dún yìí tàbí tó jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ro sì ní àwọ̀ ilẹ̀ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.
Oṣù July ló máa ń tutù jù láàárín ọdún, sáà tí wọ́n máa ń bẹ́ ìrèké tí wọ́n sì máa ń fún un ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Yóò máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí di December bí ohun ọ̀gbìn náà ti ń gbó sí i ní onírúurú ìpele rẹ̀. Ní báyìí, a fẹ́ bẹ ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe ṣúgà wò kí a lè rí ohun tí wọ́n ń fi àwọn ìrèké tí wọ́n bẹ́ náà ṣe. Ṣùgbọ́n wọ́n dámọ̀ràn pé ká tó lọ síbẹ̀, ká kọ́kọ́ mọ nǹkan kan nípa ìrèké fúnra rẹ̀. Nítorí náà, a pinnu láti kọ́kọ́ yà ní ibùdó kan tó wà ní àgbègbè náà tí wọ́n ti ń fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàyẹ̀wò nípa ṣúgà. Níbi tí a ń wí yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣẹ̀dá àwọn oríṣi ìrèké tuntun kan, wọ́n sì ń ṣèwádìí láti mú kí ọ̀gbìn ìrèké àti ohun tí wọ́n fi ń ṣe sunwọ̀n sí i.
Ibi Tó ti Wá àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Gbìn Ín
Ní ibùdó tí wọ́n ti ń ṣèwádìí nípa ṣúgà náà, inú onímọ̀ nípa iṣẹ́ ọ̀gbìn kan, tó ṣèèyàn dáadáa dùn láti kọ́ wa ní ohun kan nípa ìrèké fúnra rẹ̀, ó sì ṣàlàyé nípa bó ṣe ń hù. Látilẹ̀ wá, inú igbó kìjikìji ni wọ́n ti máa ń rí ìrèké ní ìhà Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà àti New Guinea, àràbà ni lára àwọn ẹ̀yà koríko, ó jẹ́ ọ̀kan lára onírúurú koríko bíi koríko orí pápá, ọkà oníyangan, àti ọparun. Gbogbo àwọn ohun ọ̀gbìn yìí máa ń ṣẹ̀dá ṣúgà nínú ewé wọn nípasẹ̀ ìlànà photosynthesis. Síbẹ̀, ìrèké yàtọ̀ ní tiẹ̀, ní ti pé òun máa ń ṣe èyí tó pọ̀ gan-an, á wá pa ṣúgà náà mọ́ bíi omi dídùn nínú igi rẹ̀.
Wọ́n mọ oko ìrèké dá gan-an ní Íńdíà láyé àtijọ́. Níbẹ̀, ní ọdún 327 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn akọ̀wé tó wà lára àwọn ọmọ ogun Alẹkisáńdà Ńlá tó gbógun ṣàkọsílẹ̀ pé àwọn ará ibẹ̀ “jẹ esùsú àgbàyanu kan, tí oyin ń jáde nínú rẹ̀ láìjẹ́ pé kòkòrò oyin ló ṣe é.” Bí iṣẹ́ ìwádìí àti ìdàgbàsókè ṣe ń pọ̀ sí i láàárín ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún, gbígbin ìrèké wá yára gbilẹ̀. Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún oríṣiríṣi ìrèké ló wà, ó sì lé ní ọgọ́rin orílẹ̀-èdè tó ń mú nǹkan bíi bílíọ̀nù tọ́ọ̀nù rẹ̀ jáde lọ́dọọdún.
Ní apá ibi púpọ̀ jù lọ lágbàáyé, ó máa ń gba iṣẹ́ takuntakun láti gbìn ín. Wọ́n á gé àwọn ìrèké tó ti gbó sí kéékèèké tó gùn ní nǹkan bí ogójì sẹ̀ǹtímítà, wọ́n á wá gbìn wọ́n sí poro ebè, wọ́n á sì fi nǹkan bíi mítà kan ààbọ̀ jìnnà síra. Igi mẹ́jọ sí méjìlá ló máa ń wà ní ìdí kọ̀ọ̀kan bó ti ń dàgbà, ó sì máa ń gba oṣù méjìlá sí oṣù mẹ́rìndínlógún kí ó tó gbó. Ẹ̀rù lè máa bani nígbà tí a bá ń rìn láàárín pápá ìrèké tó ti gbó. Àwọn ìrèké àti ewé rẹ̀ tó rí pàǹpà-pàǹpà máa ń ga tó mítà mẹ́rin. Ṣé atẹ́gùn ló ń rúgbó níbẹ̀ yẹn, ṣé kì í ṣe ejò tàbí eku ṣá? Kójú máà ríbi, ẹsẹ̀ loògùn ẹ̀, ó jọ pé ó tó àkókò wàyí ká wá jáde sí gbangba!
Wọ́n ń ṣe ìwádìí láti wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà gbógun ti àwọn kòkòrò ìrèké àti àrùn tó máa ń kọ lù ú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò kẹ́sẹ járí nínú gbogbo rẹ̀, púpọ̀ lára rẹ̀ ló yọrí sí rere. Fún àpẹẹrẹ, ní ọdún 1935, nínú ìsapá láti mú àwọn ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn ayọnilẹ́nu tó ń jẹ ìrèké kúrò, àwọn aláṣẹ kó àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí ń gbé àárín ìrèké ní Hawaii wá sí àríwá Queensland. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ, nítorí pé àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà fẹ́ràn oríṣi oúnjẹ mìíràn tó pọ̀ rẹpẹtẹ níbẹ̀ ju àwọn ọ̀bọ̀n-ùnbọn-ùn tó ń jẹ ìrèké lọ, wọ́n bímọ jọ rẹpẹtẹ, làwọn alára bá di ọ̀gágun kòkòrò ayọnilẹ́nu jákèjádò ìhà àríwá ìlà oòrùn Ọsirélíà.
Ṣé Pé Ẹ Ń Sun Wọ́n Kí Ẹ Tó Bẹ́ Wọn?
Nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú lọ́jọ́ yẹn, ó yà wá lẹ́nu bí a ti ń wòran àgbẹ̀ kan níbẹ̀ tó finá sí oko ìrèké rẹ̀ tí àwọn ìrèké inú rẹ̀ ti gbó. Ní ìṣẹ́jú akàn, pápá kékeré náà ti ń jóná, ọwọ́ iná náà sì le gan-an. Sísun àwọn ìrèké náà yóò jẹ́ kí àwọn ewé tí kò wúlò àti àwọn ohun mìíràn tó lè ṣèdíwọ́ nígbà tí wọ́n bá ń bẹ́ wọn àti ìgbà tí wọ́n bá ń fún wọn kúrò níbẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, àwọn èèyàn púpọ̀ ti ń yí sí ọ̀nà bíbẹ́ ìrèké wọn láìkọ́kọ́ sun ún lọ́nà tó gbàfiyèsí yìí. Wọ́n ń pe irú ìlànà yẹn ní bíbẹ́ ìrèké ní tútù. Kì í ṣe pé ó ń mú kí ṣúgà tí wọ́n ń rí pọ̀ sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń jẹ́ kí ewé lè wà nílẹ̀ láti dáàbò bò ó, èyí tí yóò wá wúlò fún gbígbógun ti ọ̀gbàrá àti èpò.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbin ìrèké lónìí, àdá ni wọ́n ṣì fi ń bẹ́ ohun ọ̀gbìn yìí, ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ sí i ti ń lo àwọn ẹ̀rọ ràgàjì-ràgàjì tí wọ́n fi ń bẹ́ ìrèké. Bí àwọn ẹ̀rọ ńláńlá wọ̀nyí ṣe ń gba àárín àwọn ìrèké gíga kọjá ni wọ́n ń gé àwọn ewé àti ibi tí kò wúlò dànù lára àwọn ìrèké náà, wọ́n á wá gé wọn sí kéékèèké fúnra wọn, ó di ilé ẹ̀rọ tí wọ́n ti ń fi wọ́n ṣe ṣúgà. Nígbà tí ẹnì kan tó ń fi tagbáratagbára bẹ́ ìrèké ti lè fi àdá bẹ́ ìpíndọ́gba tọ́ọ̀nù márùn-ún lóòjọ́, àwọn ẹ̀rọ tí ń bẹ́ ìrèké lè fìrọ̀rùn bẹ́ iye tí ó tó ọ̀ọ́dúnrún tọ́ọ̀nù lóòjọ́. Wọ́n lè máa bẹ́ ìrèké nínú oko lọ́dọọdún fún ọdún mélòó kan kí ìwọ̀n ṣúgà tó ń mú jáde tó lọ sílẹ̀, tí wọ́n á sì wá gbin òmíràn dípò rẹ̀.
Gbàrà tí wọ́n bá ti bẹ́ ìrèké náà, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n yára ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀, nítorí pé ìwọ̀n ṣúgà tó wà nínú ìrèké tí wọ́n ti bẹ́ máa ń yára dín kù. Láti mú kí kíkó wọn lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lórí wọn yá, wọ́n ní àwọn ọkọ̀ ojú irin ọlọ́mọlanke tí kò fẹ̀ tí wọ́n fi ń kẹ́rù, tí ojú irin tí wọ́n ń gbà jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún [4,100] kìlómítà, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè tí wọ́n ti ń gbin ìrèké ní Queensland. Àwọn ọkọ̀ ojú irin eléèédú, tí wọ́n kéré tí wọ́n ń gba ojú irin tóóró náà ní àwọ̀ mèremère tó dùn ún wò bí wọ́n ṣe ń kọjá ní àgbègbè àrọko náà, tí wọ́n ń fa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọlanke ìkẹ́rù tí ìrèké kún inú wọn dẹ́múdẹ́mú.
Gbígba Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ṣúgà Kọjá
Ìrírí tó gbádùn mọ́ni ló jẹ́ láti ṣèbẹ̀wò sí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ṣúgà. Ohun tí a kọ́kọ́ rí ni àwọn ọmọlanke tí wọ́n tò tẹ̀ léra wọn, tí wọn ò tíì kó ìrèké inú wọn kúrò. Àwọn ẹ̀rọ ràgàjì-ràgàjì tí wọ́n fi ń la ìrèké àti ẹ̀rọ ìlọǹkan ń lọ àwọn ìrèké náà, wọ́n sì ń fún omi ṣúgà jáde nínú igi rẹ̀. Àwọn ṣákítì tó ṣẹ́ kù, tàbí èèpo rẹ̀ ni wọ́n máa ń sá gbẹ tí wọ́n sì ń fi dáná láti pèsè agbára iná ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe ṣúgà náà. Èyí tó bá ṣẹ́kù ni wọn yóò lọ tà fún àwọn tó ń ṣe bébà àti ohun ìkọ́lé.
Wọ́n á wá yọ ìdọ̀tí tó bá wà nínú omi ṣúgà náà kúrò, tí yóò mú kí èyí tó ṣẹ́kù mọ́. Wọ́n máa ń lo ìdọ̀tí tí wọ́n kó náà, tí wọ́n ń pè ní ẹrẹ̀, bí èròjà tí wọ́n fi ń ṣe ajílẹ̀. Ohun mìíràn tí wọ́n tún máa ń rí yọ lára rẹ̀, ìyẹn oyin inú ṣúgà, ni wọ́n máa ń lò bí oúnjẹ àwọn ẹran ọ̀sìn tàbí kí wọ́n lò ó bí ọ̀kan lára èròjà ìpọntí ṣágo àti ògógóró. Bí ìrèké ṣe wúlò láti fi ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan àti bí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi ṣe ṣúgà ti gbéṣẹ́ tó wúni lórí gan-an ni.
Wọ́n á wá sọ omi náà di àpòpọ̀ kíki tó rí mẹ̀dẹ̀mẹ̀dẹ̀ nípa sísè é kí omi tí kò wúlò lè gbẹ nínú rẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá po ṣúgà dídì tíntìntín mọ́ ọn. Àwọn ṣúgà dídì yìí á wá máa tóbi títí wọ́n á fi tóbi tó ìwọ̀n tí wọ́n fẹ́. Wọ́n á wá kó wọn kúrò nínú àpòpọ̀ náà, wọ́n á sì gbẹ wọ́n. Ohun tó máa jáde á jẹ́ ògidì ṣúgà aláwọ̀ ilẹ̀. Tí wọ́n bá túbọ̀ yọ́ ògidì ṣúgà náà mọ́ dáadáa, yóò wá di ṣúgà funfun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ tí wọ́n máa ń rí lórí tábìlì wọn nígbà oúnjẹ.
Bóyá tíì tàbí kọfí rẹ yóò túbọ̀ dùn sí i lẹ́yìn ìrìn àjò fífani-lọ́kàn-mọ́ra tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tí a rìn lọ sí àgbègbè tí ìrèké wà yìí. Àmọ́ ṣá o, tí o bá ní àìsàn àtọ̀gbẹ, má ṣe jẹ ṣúgà o, o lè wá nǹkan mìíràn lò.
Dájúdájú, agbára ìmọwọ́yípadà àti ọgbọ́n Ẹni tó ṣẹ̀dá ohun ọ̀gbìn àgbàyanu tó ń jẹ́ ìrèké yìí, tó jẹ́ àràbà láàárín àwọn koríko, tó sì tún mú kó máa hù yanturu wú wa lórí!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ohun Ọ̀gbìn Beet Ni Wọ́n Fi Ṣe É Àbí Ìrèké?
Oríṣi ohun ọ̀gbìn méjì pàtàkì ni wọ́n fi ń ṣe ṣúgà lágbàáyé. Àgbègbè ilẹ̀ olóoru ni wọ́n ti sábà ń gbin ìrèké, ó kéré tán, òun ni wọ́n sì ń fi ṣe ìpín márùndínláàádọ́rin nínú gbogbo ṣúgà tí wọ́n ń ṣe lágbàáyé. Ohun ọ̀gbìn beet tí wọ́n fi ń ṣe ṣúgà ni wọ́n fi ń ṣe ìpín márùndínlógójì yòókù jáde, èyí tí wọ́n máa ń gbìn ní àwọn àgbègbè tí ojú ọjọ́ ti tutù, bí Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà. Àwọn ṣúgà náà jọra ní ti kẹ́míkà tí wọ́n fi ṣe wọ́n.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń bẹ́ ìrèké. Katakata ń fa ọmọlanke
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Wọ́n ǹ sun ìrèké kí wọ́n tó bẹ́ ẹ
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Gbogbo àwòrán tó wà lójú ìwé 15-18 jẹ́ ti: Queensland Sugar Corporation