ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 9/8 ojú ìwé 4-5
  • Ṣé Ohun Tó Hàn Sí Ojúyòójú Nìkan Lò Ń Rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ohun Tó Hàn Sí Ojúyòójú Nìkan Lò Ń Rí?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Ìṣẹ̀dá
  • Ọlọ́run Ha Bìkítà Nípa Wa Ní Ti Gidi Bí?
  • Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bi A Ṣe Lè Mọ̀ Pe Ọlọrun kan Wà
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ẹ̀mí Mímọ́ Ni Ọlọ́run Lò Nígbà Ìṣẹ̀dá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kan Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́
    Jí!—2013
Jí!—2000
g00 9/8 ojú ìwé 4-5

Ṣé Ohun Tó Hàn Sí Ojúyòójú Nìkan Lò Ń Rí?

ÀWỌN awakọ̀ kì í rí gbogbo ohun tó wà láyìíká ọkọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá fi dígí sí ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀ wọn, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti rí ọkọ̀ tí ń bọ̀, wọ́n á sì lè yẹra fún jàǹbá. Bákan náà ni kò ti ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rí Ẹlẹ́dàá tí kò ṣeé fojúyòójú rí ní ti gidi. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tí a fi lè mọ̀ pé irú Ẹni bẹ́ẹ̀ wà?

Òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ ọ̀nà tí a lè gbà fòye mọ ohun tí a kò lè fojú rí. Ó kọ̀wé pé: “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.”—Róòmù 1:20.

Ro ìyẹn wò ná. Ǹjẹ́ o rí i pé àwọn nǹkan tó wà ní àyíká wa fi hàn pé làákàyè tó ga ju tèèyàn lọ ni a fi dá wọn? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ń mú kí o lè fi “oju ọkàn” rẹ rí i pé ẹnì kan wà tí ó tóbi lọ́lá ju ènìyàn lọ? Jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.—Éfésù 1:18, Bibeli Mimọ.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Ìṣẹ̀dá

Ǹjẹ́ ẹnú yà ọ́ nígbà tí o wo bí òfuurufú tó kún fún ìràwọ̀ ní alẹ́ ọjọ́ kan tí òṣùpá kò yọ ti lẹ́wà tó, tí o sì rí ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá kan wà? Ẹnì kan tó bojú wòkè láyé ọjọ́hun sọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” Ọkùnrin yìí tún ronú jinlẹ̀, ó ní: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?”—Sáàmù 8:3, 4; 19:1.

Ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti ṣe kàyéfì nípa àwọn ìṣẹ̀dá tó jẹ́ àgbàyanu gidigidi débi pé ènìyàn kò lè ṣẹ̀dá irú wọn. Ìlà kan nínú ewì kan tó gbajúmọ̀ wí pé: “Ọlọ́run nìkan ló lè ṣẹ̀dá igi.” Ṣùgbọ́n o, ṣíṣẹ̀dá ọmọ tún jẹ́ àgbàyanu ju ìyẹn lọ fíìfíì, èyí sì máa ń wáyé láìjẹ́ pé òbí pinnu bí a óò ṣe ṣẹ̀dá ọmọ náà. Nígbà tí àtọ̀ láti ara bàbá bá dà pọ̀ pẹ̀lú ẹyin kan lára ìyá, kíákíá ni ìwéwèé kan yóò wáyé nínú ásíìdì DNA ti sẹ́ẹ̀lì tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti mú ọmọ kan jáde. Wọ́n sọ pé, “bí a bá ní ká kọ ìsọfúnni tó wà nínú ásíìdì DNA sílẹ̀, yóò kún inú ẹgbẹ̀rún ìwé tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ẹgbẹ̀ta ojú ewé.”

Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ṣì nìyẹn o. Sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ yẹn yóò pín sí méjì, lẹ́yìn náà yóò di mẹ́rin, yóò tún di mẹ́jọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn nǹkan bí igba ó lé àádọ́rin [270] ọjọ́, wọ́n á bí ọmọ kan tó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún sẹ́ẹ̀lì lára, tí wọ́n jẹ́ oríṣiríṣi lọ́nà tó ju igba lọ. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ yẹn ní ìsọfúnni nínú láti mú gbogbo sẹ́ẹ̀lì wọ̀nyẹn jáde lónírúurú, kí ó sì mú wọn jáde lákòókò gan-an tó yẹ! Èyí ha sún ọ láti yin Ẹlẹ́dàá wa bí? Kíyè sí ọ̀rọ̀ ìyìn tí onísáàmù náà sọ nígbà tó kọ̀wé pé: “Ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣe àwọn kíndìnrín mi; ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi. Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:13-16.

Àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ “ohun ìyanu” wọ̀nyí máa ń ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. Dókítà James H. Hutton, tó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ Oníṣègùn tẹ́lẹ̀ rí ní ìlú Chicago àti Ìpínlẹ̀ Illinois, sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun pé sẹ́ẹ̀lì ní “agbára àràmàǹdà láti ta àtaré ìsọfúnni sí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó gba ipò rẹ̀ kí wọ́n lè mú ohun tó bá yẹ jáde. Ó jẹ́ àgbàyanu gidigidi pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wa tí ń ṣèwádìí lè mọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ó dájú pé Ọlọ́run Onílàákàyè ló pète àwọn nǹkan mérìíyìírí yìí.”

Dókítà Hutton ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Nínú ẹ̀ka ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tèmi, ìyẹn ìmọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà ara sínú ẹ̀jẹ̀, ẹ̀kọ́ nípa bí àwọn èròjà ara ṣe ń tú sínú ẹ̀jẹ̀, àti àwọn àrùn tó máa ń kọ lu àwọn ẹṣẹ́ wọ̀nyí túbọ̀ jẹ́ kó dá mi lójú pé Ọlọ́run Alágbára ló ṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ohun àgbàyanu dídíjú yìí, tó sì mú kí wọ́n máa ṣiṣẹ́.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lójú tèmi, ríronú nípa àwọn ohun àgbàyanu yìí dà bíi pé ó túbọ̀ jẹ́ ìdí tí a fi ní láti gbà gbọ́ pé alágbára gbogbo, tó sì mọ ohun gbogbo ló pète àgbáyé yìí, tó mú kí ó máa wà, tó sì ń bójú tó o.”

Lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Dókítà Hutton béèrè pé: “Ṣé Òun ni Ọlọ́run náà tó máa ń kíyè sí i nígbà tí ológoṣẹ́ kọ̀ọ̀kan bá jábọ́?” Ó dáhùn pé: “Bákan ṣáá, mo ṣiyè méjì nípa ìyẹn. N kò sì gbà gbọ́ pé Ó máa ń pe àfiyèsí rárá sí ìgbòkègbodò mi ojoojúmọ́ tí kò já mọ́ nǹkankan bákan ṣáá.”

Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ fi ń gbà pé “ohun ìyanu” ìṣẹ̀dá fi làákàyè hàn ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ṣiyèméjì nípa pé Ọlọ́run gidi kan wà tó ń ṣàníyàn nípa aráyé?

Ọlọ́run Ha Bìkítà Nípa Wa Ní Ti Gidi Bí?

Ọ̀pọ̀ máa ń ronú pé, bí Ọlọ́run bá wà, kò ní jẹ́ kí ìyà ńláǹlà máa jẹ àwọn ènìyàn. Ìbéèrè tí àwọn kan sábà máa ń béèrè ni pé, “Ibo ni Ọlọ́run wà nígbà tí a nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?” Ìjìyà tí ẹnì kan tí ó la ìpakúpa tí ìjọba Násì pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn já nígbà Ogun Àgbáyé Kejì fojú rí kó ẹ̀dùn ọkàn bá a tó bẹ́ẹ̀ tó fi sọ pé: “Ká ní pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti fi ahọ́n lá ọkàn mi ni, wàá rí i pé á ṣekú pa ọ́.”

Nítorí náà, ìṣòro ńlá gbáà ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó bojú wòkè ní ayé ọjọ́hun tí a mẹ́nu kan ṣáájú yẹn ṣe sọ, ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dàá kan wà máa ń fara hàn gbangba nígbà tí a bá ṣàyẹ̀wò bí àwọn nǹkan ṣe wà létòlétò àti bí a ṣe dá wọn lọ́nà àgbàyanu. Síbẹ̀, bí Òun bá jẹ́ Ọlọ́run tó ń bìkítà nípa wa, báwo ni Ó ṣe lè fàyè gba irú ìjìyà ńláǹlà bẹ́ẹ̀? Bí a bá fẹ́ lóye èyí, tí a sì fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tó yẹ, a gbọ́dọ̀ rí ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè pàtàkì yẹn. Ibo wá la ti lè rí i?

A rọ̀ ọ́ pé kí o gba ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Ní ojú ewé kejìlélọ́gbọ̀n nínú ìwé ìròyìn Jí! yìí, wàá rí i bí o ṣe lè béèrè fún ẹ̀dà kan. A ronú pé fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn apá tó sọ pé, “Idi Ti Ọlọrun Ti Fi Fayegba Ijiya” àti “Ki Ni ti Jẹ Abajade Ìṣọ̀tẹ̀?” yóò fún ọ́ ní àwọn ìdáhùn tó tẹ́ ọ lọ́rùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́