Ìrànwọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Ìpáǹle
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
ÀWỌN ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ti fi hàn gbangba pé ṣe ni wọ́n ń tẹ òfin àti àṣẹ lójú lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ní àwọn ìgboro tí wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ du àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Faransé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé tó ń jẹ́ L’Express ti sọ, “láàárín ọdún mẹ́fà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po márùn-ún tí ìwà ipá ní ìgboro fi pọ̀ sí i.” Yàtọ̀ sí ìyẹn, iye àwọn tí kò tíì tójúú bọ́ tí wọ́n ń hùwà ọ̀daràn ti pọ̀ sí i lọ́nà tí ń gba àfiyèsí.
Láfikún sí híhùwà bàsèjẹ́, ìjoògùnyó, jìbìtì, dídáná sun ohun ìní àwọn èèyàn, àti olè jíjà, àwọn ìpáǹle ti ń dójú sọ àwọn aṣojú Orílẹ̀-Èdè ní tààràtà. Lóòrèkóòrè ni wọ́n máa ń fi ìwà ipá kọlu àwọn ọlọ́pàá, àwọn panápaná, àwọn ọlọ́kọ̀ èrò àti àwọn mìíràn.
Èé ṣe tí ìwà ipa fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Àwọn méjì kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ìgbépọ̀ ẹ̀dá ṣàlàyé pé: “Ní àfikún sí fífọ́ tí àwọn ìdílé ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan, ó jẹ́ ìṣọ̀tẹ̀ sí gbogbo ohun tí àwọn aláṣẹ bá ṣe.” Wọ́n tún sọ nípa “ríronú tí [àwọn èwe] ń ronú pé àwọn aláṣẹ kò dá sí ọ̀ràn àwọn mọ́” tí wọn kò sì ní “ìrètí kankan nípa ọjọ́ ọ̀la tó nítumọ̀.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù déédéé nípa ìhìn Bíbélì tó ń fúnni ní ìrètí, ní àwọn ibi tí ìwà ìpáǹle ti gbalé gbòde. Nínú ètò kan tó wáyé lórí tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Faransé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ sí àwọn ìgbèríko àti àwọn àgbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí wọn, táwọn èèyàn kò ti rí ẹ̀tọ́ wọn gbà, àwọn àgbègbè tó jẹ́ pé nígbà mìíràn, ṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn elétò ààbò, àwọn ọlọ́pàá, àti ìjọba ti pa wọ́n tì. Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lọ sọ̀rọ̀ ní àwọn ilé àti àdúgbò wọ̀nyẹn, wọ́n sì máa ń fetí sílẹ̀.” Iṣẹ́ wọn ń ní ipa tó dáa lórí àwọn èèyàn, bí lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí, tó wá láti ọwọ́ ọ̀dọ́ kan tó máa ń ka Jí! ṣe fi hàn.
“Tọkàntọkàn ni mo fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn ìtẹ̀jáde yín. Yàtọ̀ sí pé ẹ ti ran èmi fúnra mi lọ́wọ́, àjọṣe àárín èmi àti àwọn òbí mi ti dán mọ́rán sí i. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni mi, Mùsùlùmí sì làwọn tó bí mi lọ́mọ.
“Ohun tí mo lè sọ ni pé, ẹ ti ṣàṣeyọrí láti gbà mí lọ́wọ́ ìwà ìpáǹle. Nítorí èyí, mo túbọ̀ ń tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀sìn mi, ṣùgbọ́n mo tún máa ń ka Bíbélì. Ọpẹ́lọpẹ́ yín lára mi, ó tún ṣeé ṣe fún mi láti máa bá ilé ẹ̀kọ́ mi nìṣó. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ti fi àwọn ìwé ìròyìn yín, èyí tí mo máa ń yá àwọn kan lóṣooṣù, ran ọ̀pọ̀ tó ń gbé ládùúgbò mi lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà ìpáǹle. Ẹnu mi kò gbọpẹ́ fún ohun tí ẹ ṣe, mo mọrírì rẹ̀ gan-an.”