ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 30
  • Dídúró Gbọn-in Nígbà Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídúró Gbọn-in Nígbà Ìṣòro
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fàwọn Ìṣòro Rẹ Jẹ Ẹ́ Níyà?
    Jí!—2009
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fi Ìṣòro Jẹ Wá Níyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Òkè Ayọnáyèéfín Tẹ́lẹ̀ Rí Di Erékùṣù Tó Pa Rọ́rọ́
    Jí!—2000
  • Ìdí Tí Sísọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn Fi Ń múnú Mi Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 30

Dídúró Gbọn-in Nígbà Ìṣòro

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Wàhálà inú ìdílé, àìlera ara àti àìrówóná wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó lè máa pọ́n ọ lójú. Nígbà míì, ó lè ṣe ọ́ bíi pé o ò lè fara dà á mọ́. Síbẹ̀, o lè dúró gbọn-in nígbà ìṣòro. Gbé àpẹẹrẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò.

Òdòdó Teide máa ń hù lórí òkè kan tó ga tó egbèjìdínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún [3,700] mítà ní erékùṣù Tenerife tí kò jìnnà sí etíkun Àríwá Áfíríkà. Ní erékùṣù ilẹ̀ olóoru náà, ó ṣeé ṣe láti rí i pé òkè Pico de Teide, níbi tí orúkọ òdòdó náà ti jẹ yọ, ga fíofío. Apá òkè rẹ̀ máa ń dà bí èyí tí kò ní ewéko kankan. Àmọ́ tó bá dìgbà ìrúwé, àwọn yìnyín ìgbà òtútù tó ń yòrò máa ń pèsè ìwọ̀nba omi tó tó láti mú káwọn òdòdó tó rọ́kú yìí sọ jí tí wọ́n á sì bu ẹwà kún apá òkè náà pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò fífanimọ́ra. Lóòótọ́, òdòdó yìí lè dà bíi pé kò lágbára lójú, àmọ́ ó máa ń yè, kódà ó tún máa ń rú dáadáa ní àyíká tó jẹ́ aṣálẹ̀ tí kò sì dára fún ohun ọ̀gbìn yìí.

Bíi ti òdòdó Teide, ìwọ náà lè fara da àwọn ipò tí kò bára dé. Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kódà láwọn àkókò tó le koko gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà ìjọba Násì ní ilẹ̀ Jámánì láti rù ú là. Oníròyìn ọmọ ilẹ̀ Sweden náà, Björn Hallström sọ pé: “Ọ̀nà tí wọ́n gbà bá wọn lò burú jáì ju ọ̀nà tí wọ́n gbà bá àwùjọ èyíkéyìí mìíràn lò lọ. Àmọ́, nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún wọn láti fara da ipò náà dáadáa ju àwọn èèyàn èyíkéyìí mìíràn lọ.”

Ipòkípò yòówù kó o bá ara rẹ, Bíbélì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nígbà ìṣòro. Kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó wà lójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́