ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 3
  • Ẹnu Ti Ń Kun Mósè O

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹnu Ti Ń Kun Mósè O
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2004
  • Bawo ni Jesu Kristi Ṣe Jẹ́ Wolii kan bii Mose?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ta Ni Mósè?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 3

Ẹnu Ti Ń Kun Mósè O

Ọ̀PỌ̀ nǹkan làwọn ẹlẹ́sìn Júù, àwọn Kristẹni àtàwọn Mùsùlùmí ò fohùn ṣọ̀kan lé lórí. Síbẹ̀, láìka ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ẹ̀sìn yìí sí, ohun kan wà tí gbogbo wọ́n ní, ìyẹn ni ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkùnrin náà tí ń jẹ́ Mósè. Àwọn Júù kà á sí “ẹni tó ga jù lọ nínú àwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Júù,” àní olùdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Júù. Àwọn Kristẹni gbà pé òun lẹni tá a rán ṣáájú Jésù Kristi. Àwọn Mùsùlùmí sì gbà pé Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànábì tí wọ́n kọ́kọ́ ní, ó sì wà lára àwọn wòlíì títóbi jù lọ.

Nípa bẹ́ẹ̀, Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí ohun tí wọ́n gbélé ayé ṣe nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tẹ́nu àwọn ọ̀mọ̀wé àtàwọn àlùfáà ti ń kun Mósè. Kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn kan ń ṣiyèméjì nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Mósè ṣe àti bó ṣe kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì nìkan ni o, àmọ́ wọ́n tún ń kọminú pé bóyá ló gbáyé rí. Ibi tí ìwé náà, Moses—A Life, látọwọ́ Jonathan Kirsch, parí ọ̀rọ̀ ọ̀hún sí ni pé: “Gbogbo ohun tá a lè sọ nípa Mósè tá a kà nípa rẹ̀ nínú ìtàn ni pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó jọ ọkùnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí ti gbáyé rí nígbà kan àti níbì kan tí a kò mọ̀, nígbà láéláé, a sì lè sọ pé àwọn àlàyé kan téèyàn lè máà fi bẹ́ẹ̀ já kúnra, ṣùgbọ́n tí àwọn ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu ń gbè sí lẹ́yìn bí ọdún ti ń gorí ọdún ló wá sọ Mósè dẹni táráyé mọ̀, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, títí tó fi dẹ́ni tá à ń kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì lónìí.”

Èèyàn lè kọ́kọ́ rò pé òótọ́ díẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ṣàlàyé pé a ti rí lára ohun táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde tó jẹ́rìí sí i pé lóòótọ́ làwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn bíi Jéhù, ọba Ísírẹ́lì, gbáyé rí, ṣùgbọ́n wọn ò tíì rí ẹ̀rí kankan tì í lẹ́yìn pé lóòótọ́ ni Mósè gbáyé rí. Àmọ́ ṣá o, a ò lè tìtorí ìyẹn sọ pé ẹni ìtàn àròsọ lásán ni Mósè. Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ti jiyàn rí pé àwọn èèyàn míì tí Bíbélì dárúkọ, irú bíi Bẹliṣásárì, Ọba Bábílónì àti Ságónì, Ọba Ásíríà, náà ò gbáyé rí, àfìgbà táwọn awalẹ̀pìtàn tó jẹ́rìí sí i.

Òǹkọ̀wé Jonathan Kirsch rán wa létí pé: “Ó ṣòro fáwọn awalẹ̀pìtàn láti ṣàwárí ohunkóhun nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Bíbélì sọ nípa wọn, ìyẹn ló fi jẹ́ pé àìrí ohunkóhun nípa Mósè níbòmíràn yàtọ̀ sí nínú Bíbélì kì í ṣe ohun tó yẹ kó yani lẹ́nu, kò sì tó ohun tá a lè torí ẹ̀ sọ pé kò gbáyé rí.” Gẹ́gẹ́ bí Kirsch ṣe sọ, àwọn kan jiyàn pé kò sí bí Mósè ṣe lè jẹ́ èèyàn inú ìtàn àròsọ kan lásán, níwọ̀n bí “kò ti sẹ́ni tó lè hùmọ̀ . . . , ìtàn ìgbésí ayé kan tó ní àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ tóyẹn, níbi tó ti dà bí ẹni pé ẹni méjì ń bára wọn sọ̀rọ̀, tí gbogbo rẹ̀ sì bára mu délẹ̀.”

Yálà o jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wáyé nígbà ayé Mósè, irú bí ìgbà tí Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀ níbi tí iná ti ń jó lára igi kékeré, ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, àti bí Òkun Pupa ṣe pínyà. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìdí wà tó fi yẹ ká gbà gbọ́ pé èyíkéyìí lára àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Àbí ńṣe ni Mósè wulẹ̀ jẹ́ ẹni ìtàn àròsọ lásán? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí á tú iṣu àwọn ìbéèré fífani mọ́ra yìí désàlẹ̀ ìkòkò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́