Wíwo Ayé
Ìwàásù Dórí Àtẹ
Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti ìlú London sọ pé: “Àdúrà àwọn àlùfáà tíṣẹ́ wọn tó pọ̀ jù kì í jẹ́ kí wọ́n ráyè múra ìwàásù wọn sílẹ̀ ti gbà báyìí o: ìdí ni pé elééridà Ìjọ Áńgílíkà kan ti ní ìkànnì orí íńtánẹ́ẹ̀tì tuntun kan níbi téèyàn ti lè rí onírúurú ìwàásù téèyàn bá ń fẹ́ rà.” Olóòtú ìkànnì orí íńtánẹ́ẹ̀tì náà, Bob Austin, sọ pé: “Àwọn oníwàásù ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè mọ́ láyé ìsinsìnyí, ìyẹn sì ti jẹ́ kí iná ìwàásù máa jó rẹ̀yìn.” Ó ṣèlérí pé òun ní “ojúlówó ìwàásù tó ti wà ní sẹpẹ́,” àwọn ìwàásù yìí sì jẹ́ “amúnironújinlẹ̀, wọ́n ń wọni lọ́kàn ṣinṣin, ẹ̀kọ́ sì pọ̀ nínú wọn.” Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé ó ju “àádọ́ta ìwàásù ‘tí wọ́n ti wà lórí ọ̀pọ̀ àga ìwàásù,’ tí wọ́n sì dá lórí oríṣiríṣi ẹsẹ Bíbélì àtàwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ tó dá lé Bíbélì, tó wà nínú ìkànnì yìí,” ṣùgbọ́n ìwàásù wọ̀nyí ò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó ta kora wọn. Ó sọ pé àwọn ìwàásù tó gùn tó “ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí méjìlá yìí á dùn mọ́ àwọn ọmọ ìjọ nínú,” dọ́là mẹ́tàlá owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà sì nìkọ̀ọ̀kan wọn.
“Ọkọ̀ Gbadé Orí Ọ̀dà”
Ìwé ìròyìn Ìlú Mẹ́síkò náà, Reforma sọ pé: “Ọkọ̀ ti wá lu ìgboro ìlú ńlá ńlá pa báyìí o.” Lọ́dún 1970, láwọn ìlú térò pọ̀ sí tá a bá kó ẹgbàafà lé irínwó àti mẹ́tàlélógún èèyàn [12,423] jọ, ẹnì kan ṣoṣo ló ní ọkọ̀. Àmọ́, lọ́dún 2003, iye ọkọ̀ tó wà ti pọ̀ débi pé nínú ẹni mẹ́fà, a óò rí ẹni kan tó ní ọkọ̀. Àwọn ọkọ̀ táwọn olùgbé Ìlú Mẹ́síkò tí iye wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù méjìdínlógún ń rà sí i pọ̀ débi pé lọ́dún 2002 iye ọkọ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn rà ju iye ọmọ tuntun tó wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n bí lọ. Ìṣòro tó wá tìdí ìyẹn yọ ni pé ọkọ̀ ló ń fa ìdámẹ́rin nínú márùn-ún ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́ ní Ìlú Mẹ́síkò. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn kan lára àwọn tó máa ń wakọ̀ lọ síbi iṣẹ́ lè rin ìrìn àjò fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta nínú ọkọ̀ kí wọ́n tó lè dé ibi iṣẹ́ wọn, ohun tó sì ń fà á ò ṣẹ̀yìn súnkẹẹrẹ fàkẹẹrẹ ọkọ̀ láwọn ojú ọ̀nà márosẹ̀. Wọ́n ṣírò rẹ̀ pé tó bá fi máa di ọdún 2010, iye ọkọ̀ tó máa wà nígboro Ìlú Mẹ́síkò á ti fi àádọ́ta ọ̀kẹ́ pọ̀ sí i.
Àwọn Ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Ń Ki Ọrùn Bọ Gbèsè Ṣáá
Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph tìlú London sọ pé: “Báwọn èèyàn ṣe ń tọrùn bọ gbèsè nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti fẹ́ máa jin ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà lẹ́sẹ̀, ó sì ń kó ìdámẹ́rin àwọn ará ibẹ̀ sí ìṣòro ìṣúnná owó tó gogò.” Ó fi kún un pé: “Orílẹ̀-èdè náà ti sọra ẹ̀ di orílẹ̀-èdè ‘rà á láwìn,’ tó ti tọrùn bọ gbèsè ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀rin ó dín méjì [878] owó pọ́n-ùn [ìyẹn bíi tírílíọ̀nù mọ́kànlénígba àtààbọ̀ náírà], látàrí báwọn èèyàn ṣe ń rajà àwìn.” Yàtọ̀ sí owó tí wọ́n ń san díẹ̀díẹ̀ lórí dúkìá, gbèsè tó wà lọ́rùn ọmọ orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ̀ọ̀kan tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin [3,383] pọ́n-ùn [ìyẹn iye tó tó ẹgbẹ̀rún méjìlénígba náírà] lórí àwọn ọjà tí wọ́n fi káàdì ìrajà láwìn rà, owó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yá, àti ẹ̀yáwó báńkì. Látàrí èyí, “àìmọye àwọn àgbààgbà tó ti wọko gbèsè ló ń bẹ̀rù gbèsè tí wọn ò ní lè san padà bó ṣe yẹ kí wọ́n máa san án,” pàápàá tí èlé orí rẹ̀ bá ga sí i tàbí bí iṣẹ́ bá dín kù nígboro. Frances Walker láti Ilé Iṣẹ́ Ìgbaninímọ̀ràn Lórí Rírajà Láwìn sọ pé: “Tí gbèsè tó ò ń san lóṣù, yàtọ̀ sí owó tó ò ń san díẹ̀díẹ̀ lórí dúkìá, bá ti pọ̀ ju ìdámárùn-ún owó tó ń wọlé fún ọ lóṣù lọ, o ti ń ṣe kọjá bó o ti mọ nìyẹn.” Láìka gbogbo ìkìlọ̀ yìí sí, a retí pé lákòókò ìsinmi, àwọn ara ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa jẹ gbèsè tó pọ̀ tó bílíọ̀nù mẹ́ta pọ́n-ùn [bílíọ̀nù ọ̀rìnlélẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́rin náírà] kún gbèsè tí wọ́n ti jẹ tẹ́lẹ̀ lọ́dún 2003.
Ṣé Màlúù Ṣe Pàtàkì Ju Èèyàn Lọ Ni?
Báwọn olówó ṣe ń lówó sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn akúṣẹ̀ẹ́ ń kúṣẹ̀ẹ́ sí i. Tá a bá fi iye ọjà táwọn èèyàn ń rà kárí ayé láti ogún ọdún sẹ́yìn dá ọgọ́rùn-ún, iye táwọn èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí ò tí ì gòkè àgbà rárá (níbi táwọn èèyàn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin mílíọ̀nù ń gbé) rà níbẹ̀ kò tó ìdá kan. Ọmọ ilẹ̀ Faransé tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé, Philippe Jurgensen, sọ nínú ìwé ìròyìn Challenges pé: “Àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń gbé nílẹ̀ Adúláwọ̀ ni wọ́n ti kúṣẹ̀ẹ́ ju ìran tó ti kọjá lọ.” Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Etiópíà, mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́rin èèyàn ló jẹ́ pé àpapọ̀ ohun tí wọ́n ní ò ju ìdámẹ́ta ohun táwọn ogún ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń gbé nílùú Luxembourg ní lọ. Jurgensen ṣàkíyèsí pé àgbẹ̀ kan nílẹ̀ Yúróòpù, lẹ́tọ̀ọ́ láti gba Yúrò méjì àbọ̀ owó ilẹ̀ Yúróòpù [nǹkan bíi náírà márùnlénírínwó] gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́ láti fi tọ́jú màlúù kan lójúmọ́, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bílíọ̀nù méjì àbọ̀ ní ò rí tó báyẹn ná lójúmọ́. Ìdí nìyí tí Jurgensen fi sọ pé lápá ibi tó pọ̀ láyé, “ẹnì kan tó jẹ́ tálákà ò níye lórí tó màlúù kan.”