ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 3
  • O Lè Ní Ojúlówó Ayọ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Ní Ojúlówó Ayọ̀!
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ohun Tó Máa Fún Wọn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ilera ati Ayọ—Bawo ni Iwọ Ṣe Lè Rí Wọn?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
    Jí!—2017
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 3

O Lè Ní Ojúlówó Ayọ̀!

ŃṢE ló dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri ayé ló gbà pé ohun tó lè mú kéèyàn láyọ̀ ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì, owó rẹpẹtẹ ní báńkì, iṣẹ́ tó ní láárí, ilé ńlá, àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn ìgbàlódé, ẹwà ara tó jojú ní gbèsè tàbí ara tó taagun. Àmọ́, ṣé òótọ́ ni pé àwọn ohun ìní tara àti búrùjí bí irú èyí ló ń mú kéèyàn máa láyọ̀?

Àkànṣe ìròyìn kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ìwádìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i nípa bí èèyàn ṣe lè láyọ̀, béèyàn ṣe lè ní ẹ̀mí pé nǹkan-yóò-dára, béèyàn ṣe lè ní èrò rere àti ìwà ọmọlúwàbí.” Ìyàlẹ́nu gbáà ni àbájáde irú àwọn ìwádìí bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Gbogbo àbájáde náà ló sì fi hàn pé bá a bá ráwọn èèyàn tó gbọ́kàn lé e pé owó, òkìkí, tàbí ẹwà ló lè mú káwọn láyọ̀, wọ́n wulẹ̀ ń tanra wọn jẹ lásán ni. Kódà, orí ìpìlẹ̀ tó lè kó wọn sínú àìbalẹ̀ ọkàn ni wọ́n ń kọ́ ìgbésí ayé wọn lé.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni owó wọn túbọ̀ ń yamùrá. Síbẹ̀, ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Àmọ́ ìyẹn ò kúkú sọ pé kí ayọ̀ tá a ní pọ̀ sí i.” Bó sì ṣe rí fáwọn èèyàn ní ilẹ̀ ibòmíì náà nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Ṣáínà ń búrẹ́kẹ́ sí i, síbẹ̀ ó ń kọni lóminú bí iye àwọn tí kò láyọ̀ níbẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Access Asia tó ń jáde lẹ́ẹ̀kan lóṣù mẹ́ta, sọ pé ohun tó ń fa ikú jù lọ ní báyìí “fáwọn èèyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n” ni ìpara-ẹni. Ohun kan tó fà á tọ́ràn sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni kíkó tí wọ́n ń kó gìrìgìrì bá àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n mókè kí wọ́n lè máa figbá buwó bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Ó dájú pé rírí towó ṣe kì í dín àníyàn àti másùnmáwo kù; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń mú kó pọ̀ sí i. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní yunifásítì kan sọ pé: “Ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa nísinsìnyí gan-an ló fà á tí àníyàn fi ń pọ̀ sí i tí ìdààmú sì ń bá ọpọlọ.” Ọ̀mọ̀ràn kan tó mọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí láwùjọ, Van Wishard, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ló ń sanwó ìbánigbófò ìlera fáwọn òṣìṣẹ́ wọn. Èyí tó pọ̀ jù nínú gbogbo owó náà ni wọ́n sì ń san nítorí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìdààmú ọkàn.”

Kódà, ayé tó ń yára yí padà tá à ń gbé yìí ń nípa tiẹ̀ lórí àwọn ọmọdé. Wishard sọ pé ìwé ti wà fáwọn ọmọ ọlọ́dún-mẹ́jọ tó ń gbà wọ́n níyànjú lórí “bí wọ́n ṣe lè mọ̀ bí wọ́n bá fẹ́ ní ìdààmú ọkàn àti ohun tí wọ́n lè ṣe sí i.” Àti pé gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ṣe sọ, àyẹ̀wò fi hàn pé ṣe ni àwọn ọmọdé tó ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà. Ìpín mẹ́tàlélógún nínú ọgọ́rùn-ún tan-n-tán ni wọ́n fi ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Síwájú sí i, “àwọn ọmọléèwé jẹ́lé-ó-sinmi ló sì pọ̀ jù tó wá ń ra àwọn egbòogi tí kì í jẹ́ kéèyàn ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn báyìí.”

Ìbẹ̀rù tún ń pọ̀ sí i, kì í wá ṣe ti ọrọ̀ ajé tí kò dáni lójú ló fà á ṣá o. Níwọ̀n bí àṣejù ti wá wọ ọ̀ràn ìṣèlú àti ọ̀ràn ẹ̀sìn, ńṣe lẹ̀rù túbọ̀ ń ba àwọn èèyàn tí jìnnìjìnnì sì ń bò wọ́n nítorí àìmọ ilẹ̀ tó máa mọ́ ọ̀la. Kí lọ̀nà àbáyọ?

Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Jésù Kristi kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà máa gbé irú ìgbésí ayé tó ń tuni lára yàtọ̀, tó sì máa ń dín ìdààmú ọkàn kù. Òtítọ́ yíyéni yékéyéké kan tó fara hàn gbangba nínú ohun tó kọ́ni ni pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, Jésù gba àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí ohun tí aráyé ṣaláìní jù lọ, ìyẹn ni ti mímọ̀ tí wọn ò mọ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ẹlẹ́dàá wa àti ohun tí Ó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa.

Gẹ́gẹ́ bá a ti máa rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ to tẹ̀ lé èyí, òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni lè ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ ohun tó ṣe pàtàkì ní ti gidi, mímọ̀ tá a bá sì mọ̀ ọ́n á lè mú ká máa gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ jẹ́ aláyọ̀ tó sì túbọ̀ nítumọ̀. Irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ tí Bíbélì fi kọ́ni tún ń jẹ́ ká nírètí tó jẹ́ àgbàyanu.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Ṣé àwọn ohun ìní tara ló ń mú kéèyàn láyọ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́