Àwọn Àgbà Á Lókun bí Èwe Títí Láé!
ỌKÙNRIN kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù tí ò ní pẹ́ kú. Ó bẹ Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:42, 43) Lóòótọ́, àìsàn ọjọ́ ogbó kọ́ ló ń pa ọkùnrin tí Bíbélì kò dárúkọ rẹ̀ yìí lọ; wọ́n gbé e kọ́gi torí ọ̀ràn tó dá ni. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tó ti ń darúgbó lè rí ìtùnú ńlá látinú bọ́ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó.
Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká kan sáárá sí ọkùnrin yẹn torí ìgboyà tó ní! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lórí òpó ìdálóró kò ní pẹ́ kú, ó dá ọkùnrin yẹn lójú hán-ún hán-ún pé Jésù á ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nínú Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì tún ronú pé Jésù lè rántí òun sí rere lọ́jọ́ kan. Rò ó wò ná—ẹni tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún yẹn á tún jíǹde lọ́jọ́ kan sí Párádísè ológo, Jésù á sì ti di Ọba nígbà yẹn!
Ipò táráyé wà jọ tí ọkùnrin ọ̀daràn tó ń kú lọ náà. Lọ́nà wo? Láìka ọjọ́ orí wa sí, gbogbo wa là ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa tá a sì nílò ìgbàlà. (Róòmù 5:12) Bíi ti ọ̀daràn yẹn, a lè ní ìgbọ́kànlé nínú Kristi Jésù, àní a tiẹ̀ lè máa retí pé Jésù á mú àwọn ìṣòro tó máa ń bá èèyàn lọ́jọ́ ogbó kúrò! Dájúdájú, Jésù ti mú kó ṣeé ṣe fún aráyé láti nírètí pé wọ́n lè máa gbé títí láé pẹ̀lú ìlera ara àti ti ọpọlọ pípé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 3:16, 36.
Gbogbo Nǹkan Á Di Tuntun fún Tọmọdé Tàgbà
Lábẹ́ Ìjọba Kristi, àwọn olùgbé ayé yóò “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Kò sẹ́ni tó máa sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí” mọ́. (Aísáyà 33:24) Ohunkóhun tó bá jẹ́ àìlera tó ń bá wa fínra báyìí yóò di ohun ìgbàgbé, torí pé “ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:6) Àwọn àgbàlagbà yóò padà ní okun wọn bíi tìgbà tí wọ́n wà ní ọ̀dọ́; ara wọn á “jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe.”—Jóòbù 33:25.
Àmọ́, ṣó bọ́gbọ́n mu láti máa retí ìgbà tí irú nǹkan yẹn máa ṣẹlẹ̀? Ó dáa, ronú nípa Ẹni tó ṣèlérí Párádísè fún ọ̀gbẹ́ni tó ń kú lọ yẹn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ogunlọ́gọ̀ èèyàn gbé àwọn tí wọ́n yarọ, àwọn aláàbọ̀ ara, afọ́jú àti adití lọ sọ́dọ̀ Jésù. Kíá mọ́sá ló “ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara.” (Mátíù 9:35, 36; 15:30, 31; Máàkù 1:40-42) Ó fi ẹ̀rí tó ṣeé rí hàn nípa ohun tí Ìjọba rẹ̀ máa ṣe. Kódà ó níye àwọn tó ti kú tí Jésù jíǹde padà sí ìyè. (Lúùkù 7:11-17; Jòhánù 11:38-44) Ohun tó ṣe yẹn jẹ́ ẹ̀rí tó túbọ̀ lágbára tá a fi lè gba ìlérí tó ṣe gbọ́ pé “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá.”— Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Rò ó wò ná, pé wàá máa rìn nínú Párádísè pẹ̀lú ara tuntun, ojú tó ríran kedere, etí tó ń gbọ́ ohùn àwọn ẹyẹ àti àwọn èèyàn tínú wọn ń dùn, apá àti ẹsẹ̀ tí kò roni mọ́ àti ọpọlọ tó jí pépé. A ó ti ṣe ó dìgbóṣe sí “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn. (Oníwàásù 12:1-7; Aísáyà 35:5, 6) Kódà “ikú ni a ó sọ di asán,” ìyẹn ni pé a óò “gbé ikú mì títí láé.”—1 Kọ́ríńtì 15:26, 54.
Tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí, tá a fi wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a ó rí i pé à ń yára sún mọ́ àkókò táwọn ìṣòro tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn máa dópin. (Mátíù 24:7, 12, 14; Lúùkù 21:11; 2 Tímótì 3:1-5) Ó ti fẹ́ tó àkókò báyìí táwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí wọ́n sì ti sìn ín yóò padà wá gbádùn okun ìgbà èwe wọn lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, títí láé ló máa jẹ́!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Máa Fún Ọpọlọ Rẹ Níṣẹ́ Ṣe!
Bí eré ìdárayá ṣe ń mú kí ara le, bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọ máa ń jí pépé béèyàn bá fún un níṣẹ́ ṣe. Láti mú kí ọpọlọ jí pépé, ó yẹ kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan tuntun. Díẹ̀ rèé lára ọ̀nà téèyàn lè gbà mú kí ọpọlọ máa ṣiṣẹ́ láìdáwọ́dúró pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà ara tó kù.
◼ Nífẹ̀ẹ́ sí kíkọ́ àwọn nǹkan tuntun bí iṣẹ́ ọnà tó jẹ mọ́ yíyàwòrán, gbígbẹ́gi lére àti títayò, bí ayò ọlọ́pọ́n, díráàfù àti lúdò tó fi mọ́ kíkọ́ èdè míì.
◼ Máa bá ọ̀pọ̀ èèyàn ṣeré; má máa dádì, sì máa báwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ kó o má bàa máa nìkan jẹ̀, kó o sì lè mú kí ọpọlọ rẹ̀ máa jí pépé.
◼ Máa ṣe àwọn nǹkan tó lè máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. “Má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ . . . máa sọ àwọn ohun tí [ò] ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [rẹ] àti agbára èrò orí [rẹ] nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.
◼ Máa kàwé tó bójú mu; sọ ohun tó o bá kà fẹ́nì kan.
◼ Máa rántí ìròyìn tó o gbọ́ lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n kó o sì máa sọ ọ́ fún ẹlòmíì, èyí á mú kó o lè máa rántí nǹkan fúngbà díẹ̀ tàbí fúngbà gígùn.
◼ Máa lo ọwọ́ tí o kò mọ̀ ọ́n lò dáadáa (bó o bá jẹ́ ọlọ́wọ́-ọ̀tún, gbìyànjú àtilo ọwọ́ òsì, tó o bá sì jẹ́ alòsì, gbìyànjú àtilo ọ̀tún) láti pààrọ̀ ìkànnì tẹlifíṣọ̀n tàbí láti tẹ nọ́ńbà tẹlifóònù tàbí láti fọyín.
◼ Máa lo ara ẹ bó ṣe tọ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Máa fójú lóúnjẹ, má máa fetí palàbà ọ̀rọ̀, máa gbóòórùn, sì máa fi ìtọ́wò mọ adùn.
◼ Máa wádìí àwọn ibi tó wu èèyàn láti lọ kó o sì máa lọ síbẹ̀, ì báà jẹ́ tòsí tàbí ọ̀nà jíjìn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Ìlérí Jésù ni pé àwọn ìrora ọjọ́ ogbó kò ní pẹ́ pòórá, okun inú ti ìgbà èwe ń bọ̀ wá rọ́pò rẹ̀ títí láé