ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 8-10
  • Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn “Ọjọ́ Ìkẹyìn” Kí Ni?
  • Kí Ni Jésù Sọ Nípa Ìgbà Ìkẹyìn?
  • Ipá Tó Pọn Dandan Ká Sà
  • Àwùjọ Àwọn Èèyàn Tó Ń Hùwà Rere
  • Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Bi A Ṣe Mọ̀ Pe A Wà ni “Ìkẹhin Ọjọ”
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mẹ́rin Nípa Òpin Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ayé Yìí Yóò Ha Là á Já Bí?
    Ayé Yìí Yóò Ha Là Á Já Bí?
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 8-10

Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?

Ó PẸ́ tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìwàkiwà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí, ohun tó sì sọ nípa ẹ̀ rèé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, . . . òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”—2 Tímótì 3:1-5.

Ìwọ náà lè gbà pé báyé wa yìí ṣe rí gẹ́lẹ́ lónìí ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ yìí. Síbẹ̀, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì! Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà kà pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Kí ni gbólóhùn náà, “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” túmọ̀ sí ná?

Àwọn “Ọjọ́ Ìkẹyìn” Kí Ni?

“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti di èdè tó gbajúmọ̀. Lédè Gẹ̀ẹ́sì nìkan, ó ti wà lára orúkọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé. Bí àpẹẹrẹ, gbólóhùn náà wà lára orúkọ ìwé kan tí wọ́n kọ láìpẹ́ yìí, ìyẹn ni ìwé The Last Days of Innocence—America at War, 1917-1918. Ìfáárà ìwé náà mú kó ṣe kedere pé nígbà tí ìwé náà lo gbólóhùn náà “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ńṣe ló ń sọ nípa àkókò pàtó kan, nígbà táwọn èèyàn á máa hùwà burúkú bùrùjà.

Ìfáárà náà sọ síwájú sí i pé: “Lọ́dún 1914, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà lemọ́lemọ́ ju ti ìgbàkigbà rí lọ látọjọ́ táláyé ti dáyé.” Kódà, ọdún 1914 laráyé kó wọnú irú ogun tí ò tíì sírú ẹ̀ rí. Ìwé náà sọ pé: “Ogún tó ju ogun lọ ni, ó kọjá ogún láàárín ọmọ ogun àtọmọ ogún; ogun láàárín orílẹ̀-èdè àti orílẹ̀-èdè ni.” Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i, ogun yìí jà ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Ẹ̀kọ́ tó bá Bíbélì mu ni pé àkókò pàtó kan táá máa jẹ́ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” á wà káyé yìí tó pa run. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé ayé kan ti wà rí, tó sì ti kọjá lọ tàbí tó ti dópin báyìí. Ó ṣàlàyé pé: “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” Ìgbà wo nìyẹn náà, ayé wo ló sì pa run? “Ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” tó wà nígbàanì ni, ìyẹn nígbà tí ọkùnrin tó ń jẹ́ Nóà wà láyé. Bákan náà, ayé òde òní máa pa run. Síbẹ̀, àwọn tó ń sin Ọlọ́run máa la òpin ayé náà já, bí Nóà àti ìdílé ẹ̀ ṣe la ayé tìgbà yẹn já.—2 Pétérù 2:5; 3:6; Jẹ́nẹ́sísì 7:21-24; 1 Jòhánù 2:17.

Kí Ni Jésù Sọ Nípa Ìgbà Ìkẹyìn?

Jésù Kristi tún sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọjọ́ Nóà,” nígbà tí “ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Ó fi báwọn nǹkan ṣe rí ṣáájú Ìkún Omi, kí ayé ìgbà yẹn tó pa run, wé báwọn nǹkan á ṣe rí lákòókò tó pè ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3, 37-39) Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn lo gbólóhùn náà, “ìpari igbeaye yìí” tàbí “opin aiye.”—Bibeli Yoruba Atọka àti Bibeli Mimọ.

Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ báwọn nǹkan á ṣe rí kó tó di pé ayé yìí wá sópin. Ó sọ nípa ogun pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” Àwọn òpìtàn ti rí i pé láti ọdún 1914 wá ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. Torí náà, ìfáárà ìwé tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ yẹn fi hàn pé ọdún 1914 ni “ogún tó ju ogun lọ” bẹ̀rẹ̀ àti pé “ó kọjá ogún láàárín ọmọ ogun àtọmọ ogún; ogun láàárín orílẹ̀-èdè àti orílẹ̀-èdè ni.”

Jésù tún mẹ́nu kàn án nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé: “Àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” Ó tún ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé pípọ̀ sí i ìwà àìlófin” máa wà lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀. (Mátíù 24:7-14) Èyí pẹ̀lú ń ṣẹlẹ̀ lójú wa kòrókòró. Ìwà rere tí ò sí mọ́ lákòókò wá yìí burú jáì débi pé ó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ!

Irú ìgbésí ayé wo ló yẹ ká máa gbé nírú àkókò táwọn èèyàn ń hùwàkiwà yìí? Kíyè sí lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwàkiwà. Kò ṣàì mẹ́nu ba “ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini” tí wọ́n ń hù, ó wá sọ pé: “Àwọn obìnrin wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá padà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá; bákan náà, àní àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà lílenípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin, ń ṣe ohun ìbàjẹ́.”—Róòmù 1:26, 27.

Àwọn òpìtàn sọ pé gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń ti orí ìwàkiwà kan bọ́ sórí òmíràn yìí, “ńṣe ni ìtara àwùjọ àwọn èèyàn kéréje tí wọ́n jẹ́ Kristẹni àti bí wọ́n ṣe hùwà bíbójú mu dá àwọn abọ̀rìṣà àti olùfẹ́ adùn tí wọ́n ń gbé nígbà náà lẹ́bi.” Ó yẹ kí èyí mú káwa náà dúró díẹ̀ ká sì bi ara wa pé: ‘Èmi àtàwọn tí mo yàn láti máa bá kẹ́gbẹ́ ńkọ́ o? Ṣé ìwà tiwa yàtọ̀ sí ti ará yòókù, ṣe a ò máa hùwàkiwà bíi táwọn tó ń ṣèṣekúṣe?’—1 Pétérù 4:3, 4.

Ipá Tó Pọn Dandan Ká Sà

Bíbélì kọ́ wa pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó yí wa ká ń ṣèṣekúṣe, àwa gbọ́dọ̀ jẹ́ “aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́-mímọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run láìní àbààwọ́n láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó.” Ká bàa lè jẹ́ irú ẹni tí Bíbélì ní ká jẹ́ yìí, á gbọ́dọ̀ “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.” (Fílípì 2:15, 16) Nínú ohun tí Bíbélì sọ yìí la ti lè rí ìdáhùn sí ọ̀nà táwa Kristẹni lè gbé e gbà táwọn èèyàn ò fi ní kó ìwà jágbajàgba tí wọ́n ń hù ràn wá. Ó pọn dandan ká rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ wa ká sì lóye pé ìlànà tó gbé kálẹ̀ lórí ọ̀ràn ìwà rere lèyí tó dára jù lọ láti máa tẹ̀ lé nínú ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa.

Sátánì Èṣù, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” ń gbìyànjú láti fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bíbélì sọ fún wa pé ó ń bá a nìṣó láti “máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” Báwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ nípa híhùwà bíi tiẹ̀ náà sì ṣe ń ṣe nìyẹn. (2 Kọ́ríńtì 11:14, 15) Wọ́n ṣèlérí òmìnira àti ìgbádùn kẹlẹlẹ, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “àwọn fúnra wọn wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdíbàjẹ́.”—2 Pétérù 2:19.

Jẹ́ kó yé ẹ pé kò sí bojúbojú kankan níbẹ̀ o. Gbogbo ẹní bá kùnà láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run á jìyà ẹ̀. Nínú Bíbélì, onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ìgbàlà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú, nítorí pé wọn kò wá àwọn ìlànà [Ọlọ́run].” (Sáàmù 119:155; Òwe 5:22, 23) Ṣé a gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn? Bá a bá gbà bẹ́ẹ̀, nígbà náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gba ìpolongo èké tó bá ń gbé ìwàkiwà lárugẹ láyè nínú ọkàn wa.

Àmọ́ ṣá o, ìwà òmùgọ̀ máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ronú pé, ‘Bí ohun tí mò ń ṣe ò bá ti lòdì sófin a jẹ́ pé ó dára nìyẹn.’ Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ yẹn rárá. Kì í ṣe nítorí kí ayé bàa lè sú ẹ tàbí nítorí àti ká ẹ lọ́wọ́ kò ni Baba wa ọ̀run ṣe ń tọ́ ẹ sọ́nà pé kó o máa hùwà rere. Nítorí kó bàa lè dáàbò bò ẹ́ ni. Ó “ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Kò fẹ́ kó o kó sínú ìyọnu, ṣe ló fẹ́ kó o gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀. Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi kọ́ni, sísin Ọlọ́run “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” Èyí gan-an sì ni “ìyè tòótọ́,” ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí!—Aísáyà 48:17, 18; 1 Tímótì 4:8; 6:19.

Nítorí náà, fi àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni sílò wé wàhálà tó máa ń pàpà dé bá àwọn tó bá kùnà láti fi sílò. Kò sírọ́ ńbẹ̀, rírí ojú rere Ọlọ́run nípa títẹ́tí sí i ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ! Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”—Òwe 1:33.

Àwùjọ Àwọn Èèyàn Tó Ń Hùwà Rere

Bíbélì sọ pé nígbà tí ayé yìí bá kọjá lọ, àwọn “ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” Ó tún sọ pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:10, 11; Òwe 2:20-22) Nítorí náà, gbogbo ìwàkiwà tó bá ṣẹ́ kù pátá ni Ọlọ́run á mú kúrò lórí ilẹ̀ ayé, gbogbo àwọn tó bá sì kọ̀ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tó jíire tí Ẹlẹ́dàá wa fi ń kọ́ni, á dàwátì. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run á wá mú kí Párádísè, tó dà bí èyí tí Ọlọ́run fi ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ sí gẹ́lẹ́, gbòòrò kárí gbogbo ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9.

Ìwọ náà ronú nípa bó ṣe máa gbádùn mọ́ni tó láti máa gbé nínú irú orí ilẹ̀ ayé tá a ti fọ̀ mọ́ tó sì rẹwà jìngbìnnì bẹ́ẹ̀! Lára àwọn tó máa láǹfààní láti rí Párádísè ẹlẹ́wà yìí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú tí yóò jíǹde. Máa láyọ̀ nítorí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Nígbà tí ayé kan wá sópin, àwọn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run là á já

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lẹ́yìn tí ayé yìí bá wá sópin, ilẹ̀ ayé á di Párádísè

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́