ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 6 ojú ìwé 10-11
  • Desiderius Erasmus

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Desiderius Erasmus
  • Jí!—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀KỌ́ ÀTI ÌGBÀGBỌ́
  • MÁJẸ̀MÚ TUNTUN LÉDÈ GÍRÍÌKÌ
  • Bíbélì Elédè Púpọ̀ Ti Complutensian—Ohun Èlò Pàtàkì Nínú Ìtàn Ìtumọ̀ Èdè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bíbélì—Wọ́n Gbé E Gẹ̀gẹ̀, Wọ́n Tún Tẹ̀ Ẹ́ Rì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Àkòrí
    Jí!—2016
  • Wessel Gansfort “Ẹni Tó Ti Bẹ̀rẹ̀ Àtúnṣe Ìsìn Káwọn Alátùn-únṣe Tó Dé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Jí!—2016
g16 No. 6 ojú ìwé 10-11

Ìtàn Àtijọ́

Desiderius Erasmuss

Desiderius Erasmus

NÍGBÀ ayé Desiderius Erasmus (nǹkan bí ọdún 1469-1536), àwọn èèyàn kọ́kọ́ gbà pé òun ló mọ̀wé jù lọ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé nílẹ̀ Yúróòpù. Àmọ́ nígbà tó yá wọ́n sọ pé ojo àti alátakò àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ni. Nígbà kan tí àríyànjiyàn tó gbóná wáyé lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ó tú àṣírí ohun tó ń lọ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì àtàwọn tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ṣe àtúnṣe ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì. Lóde òní, ẹni pàtàkì ni wọ́n kà á sí lára àwọn èèyàn tó ṣàtúnṣe ẹ̀sìn nílẹ̀ Yúróòpù. Lọ́nà wo?

Ẹ̀KỌ́ ÀTI ÌGBÀGBỌ́

Erasmus mọ èdè Gíríìkì àti èdè Látìn dáadáa. Èyí ló jẹ́ kó lè fi Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Látìn, irú bí Bíbélì Latin Vulgate, wéra pẹ̀lú àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ ti èdè Gíríìkì tí wọ́n kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Àfiwé yìí ló mú kó dá a lójú pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní ìmọ̀ Bíbélì. Torí náà, ó sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ nígbà ayé rẹ̀.

Erasmus wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣagbátẹrù bí wọ́n ṣe máa ṣàtúnṣe àwọn ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Torí ó gbà pé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni gbọ́dọ̀ tún ìgbésí ayé èèyàn ṣè, dípò tí á fi jẹ́ pé ààtò ẹ̀sìn kan tí kò nítumọ̀ léèyàn á kàn máa tẹ̀ lé. Fún ìdí yìí, nígbà tí àwọn alátùn-únṣe ẹ̀sìn yarí pé wọ́n gbọ́dọ̀ yí àwọn ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ìlú Róòmù pa dà, àwọn Kátólíìkì bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí Erasmus pé òun ló wà lẹ́yìn wọn.

Ó tú àṣírí ohun tó ń lọ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì àtàwọn tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ṣe àtúnṣe ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì

Nínú ìwé tí Erasmus kọ, ó bẹnu àtẹ́ lu àwọn àlùfáà fún bí wọ́n ṣe ń lo agbára wọn nílòkulò, tí wọ́n ń jayé ìjẹkújẹ àti báwọn póòpù ṣe ń fọwọ́ sí ogun. Ó tako àwọn àlùfáà tó ń lo àṣà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, irú bí ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìjọsìn àwọn ẹni mímọ́, gbígbààwẹ̀ àti rírin ìrìn àjò ẹ̀sìn, láti gba tọwọ́ àwọn ọmọ ìjọ. Bákan náà, kò fara mọ́ àṣà gbígba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti fífipá múni láti má ṣègbéyàwó.

MÁJẸ̀MÚ TUNTUN LÉDÈ GÍRÍÌKÌ

Lọ́dún 1516, Erasmus tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé Májẹ̀mú Tuntun jáde lédè Gíríìkì, èyí ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó máa kọ́kọ́ jáde. Ó sì tún láwọn àlàyé míì nínú. Erasmus tún túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni sí èdè Látìn, àmọ́ èyí yàtọ̀ sí Bíbélì Vulgate. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Erasmus ń ṣé àwọn àtúnṣe kọ̀ọ̀kan sí Bíbélì náà, ó sì wá mú ẹ̀dà tó kẹ́yìn jáde, ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló sì wà nínú rẹ̀ àti Bíbélì Latin Vulgate.

Májẹ̀mú Tuntun Lédè Gíríìkì tí Erasmus ṣe

Májẹ̀mú Tuntun Lédè Gíríìkì tí Erasmus ṣe

Ọ̀kan lára irú ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ wà nínú 1 Jòhánù 5:7. Níbẹ̀, wọ́n fi àwọn ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú Bíbélì tí wọ́n ń pè ní comma Johanneum kún Bíbélì Vulgate, kí wọ́n lè ti ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan lẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ náà kà pé: “Ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ọ̀kan.” Àmọ́, Erasmus yọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn kúrò nínú ẹ̀dà Májẹ̀mú Tuntun méjì tó kọ́kọ́ ṣe torí pé kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ èdè Gíríìkì tó ṣèwádìí nínú rẹ̀. Àmọ́, ṣọ́ọ̀ṣì fipá mú un pé kó fi ọ̀rọ̀ náà kún ẹ̀dà kẹta tó ṣe jáde.

Májẹ̀mú Tuntun ní èdè Gíríìkì tí Erasmus tún ṣe, mú kí títúmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè míì tí wọ́n ń sọ nílẹ̀ Yúróòpù túbọ̀ dára sí i. Martin Luther, William Tyndale, Antonio Brucioli, àti Francisco de Enzinas lò wọ́n láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sí èdè Jámánì, Gẹ̀ẹ́sì, Ítálì, àti Sípáníìṣì.

Àkókò tí rúkèrúdò ẹ̀sìn pọ̀ gan-an ni Erasmus gbáyé, àwọn alátùn-únṣe ẹ̀sìn tí wọ́n ń pè ní Protestant Reformers sì ka iṣẹ́ ìtúmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun Lédè Gíríìkì tí Erasmus ṣe sí pàtàkì. Àwọn kan ka Erasmus fúnra rẹ̀ sí ọ̀kan lára àwọn alátùn-únṣe ẹ̀sìn, àmọ́ èrò wọn yí pa dà nígbà tí àtúnṣe náà bẹ̀rẹ̀ lójijì. Torí pé Erasmus kọ̀ láti bá wọn lọ́wọ́ sí àríyànjiyàn lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tó wáyé lẹ́yìn náà. Ohun tó wá gba àfiyèsí ni pé, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn, ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ David Schaff, kọ̀wé pé Erasmus “kò gbè sẹ́yìn ẹnì kankan títí tó fi kú. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kò lè sọ pé mẹ́ńbà àwọn ni, bákan náà làwọn Protestant kò lè sọ bẹ́ẹ̀.”

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

  • Lọ́dún 1516, Erasmus tẹ Májẹ̀mú Tuntun jáde lédè Gíríìkì. Èdè Gíríìkì wà lápá kan, èdè Látìn àtàwọn àlàyé míì sì wà lápá kejì.

  • Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí Erasmus sọ nípa Májẹ̀mú Tuntun, ó ní: “Mi ò fara mọ́ àwọn èèyàn tí wọn ò fẹ́ káwọn mẹ̀kúnnù ka Ìwé Mímọ́, tí wọ́n ò sì fẹ́ kí wọ́n túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ.”

  • Àwọn alátakò dáná sun ìwé rẹ̀ láwọn apá ibì kan nílẹ̀ Yúróòpù. Ọ̀pọ̀ ọdún sì làwọn ìwé rẹ̀ fi wà lára àwọn ìwé táwọn póòpù nílẹ̀ Róòmù fòfin dè.

Wọ́n Mọ̀ Ọ́n Jákèjádò Ayé

Erasmus jẹ́ ọ̀mọ̀wé táwọn èèyàn mọ̀ jákèjádò ayé. Ó gbé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nílẹ̀ Yúróòpù, ó sì tún ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ó ní àwọn ọ̀rẹ́ tó lẹ́nu láwùjọ, bí àwọn òṣìṣẹ́ láàfin ọba àtàwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì. Àwọn ọ̀mọ̀wé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ máa ń kàn sí i. Bí àwọn èèyàn sì ṣe ń ka àwọn ìwé tó ṣe mú kó di ìlúmọ̀ọ́ká. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé tìlù torin ni àwọn ọba, àwọn àlùfáà àtàwọn ọ̀mọ̀wé máa ń kí i káàbọ̀ níbikíbi tó bá lọ. Òǹkọ̀wé kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí tiẹ̀ sọ pé “a lè fi wé àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lóde òní.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́