ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 4 ojú ìwé 9
  • ‘Orúkọ Rere Dára Ju Ọ̀pọ̀ Yanturu Ọrọ̀ Lọ’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Orúkọ Rere Dára Ju Ọ̀pọ̀ Yanturu Ọrọ̀ Lọ’
  • Jí!—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọ̀dẹ̀ Lẹní Bá Níwà Ìrẹ̀lẹ̀ àbí Ọlọgbọ́n?
    Jí!—2007
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • “Kí Orúkọ Rẹ Di Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Báwo Lo Ṣe Lè Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—2017
g17 No. 4 ojú ìwé 9
Mẹkání ìkì kan tó ní orúkọ rere

Tí ẹnì kan bá ní orúkọ rere, àwọn èèyàn á fọkàn tán an, wọ́n á sì bọ̀wọ̀ fún un

‘Orúkọ Rere Dára Ju Ọ̀pọ̀ Yanturu Ọrọ̀ Lọ’

ORÚKỌ rere ṣe pàtàkì débi pé ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ńṣe ni àwọn èèyàn máa ń fi òfin dáàbò bo orúkọ wọn. Tí ẹnì kan bá bà wọ́n lórúkọ jẹ́ bóyá lórí afẹ́fẹ́, nínú ìwé ìròyìn tàbí láwọn ọ̀nà míì, wọ́n lè pe onítọ̀hún lẹ́jọ́. Èyí fi hàn pé òótọ́ ni òwe àtijọ́ kan tó sọ pé: “Orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.” (Òwe 22:1) Báwo la ṣe lè ní orúkọ rere tí àwọn èèyàn á sì bọ̀wọ̀ fún wa? Àwọn àbá tó wúlò gan-an wà nínú Bíbélì.

Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Bíbélì sọ nínú Sáàmù 15. Onísáàmù náà béèrè pé: “Ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ [Ọlọ́run]?” Ó wá dáhùn pé: “Ẹni tí . . . ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀. Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́, kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ní ojú rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí a kọ̀ . . . Ó ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà. . . . Kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Sáàmù 15:​1-5) Tó o bá mọ ẹnì kan tó ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, ǹjẹ́ kò ní wù ẹ́ láti bọ̀wọ̀ fún onítọ̀hún?

Àwọn èèyàn tún máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹni tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Òwe 15:33 sọ pé: “Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ògo.” Rò ó wò ná: Àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń rí ibi tó ti yẹ kí wọ́n ṣe àtúnṣe, wọ́n sì máa ń sapá gidigidi láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n tún máa ń tọrọ àforíjì tọkàntọkàn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ ẹnì kan. (Jákọ́bù 3:2) Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn agbéraga ò rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń tètè bínú. Òwe 16:18 sọ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”

Ká sọ pé ẹnì kan bà ẹ́ lórúkọ jẹ́ ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó o gbé e gbóná fún onítọ̀hún lójú ẹsẹ̀? Bi ara rẹ pé, ‘Tí n bá ní kí n gbèjà ara mi, ǹjẹ́ kì í ṣe pé ńṣe ni mò tún ń tan ìrọ́ náà kálẹ̀ báyìí?’ Òótọ́ ni pé tí ẹnì kan bá bani lórúkọ jẹ́, kò burú láti pe onítọ̀hún lẹ́jọ́ nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, àmọ́ Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n kan pé: “Má fi ìkánjú jáde lọ ṣe ẹjọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “ro ẹjọ́ tìrẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ.” (Òwe 25:​8, 9)a Tó o bá fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà, èyí ò ní jẹ́ kí o kó ara rẹ sí ìnáwó lórí ẹjọ́.

Bíbélì kì í ṣe ìwé ẹ̀sìn kan lásán. Tó o bá tẹ̀ le àwọn ìtọ́ni tó wà nínú rẹ̀ nínú ìgbé ayé rẹ, wàá ṣàṣeyọrí. Tó o bá ń lo ọgbọ́n tó wà nínú rẹ̀, wàá ní àwọn ìwà tó wuyì gan-an tó máa jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ẹ, wàá sì ní orúkọ rere.

a O lè rí àwọn ìlànà Bíbélì míì nípa bá a ṣe lè yanjú èdèkòyédè ní Mátíù 5:​23, 24; 18:​15-17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́