ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 2 ojú ìwé 4-5
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NI ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU?
  • KÍ NÌDÍ TÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU FI ṢE PÀTÀKÌ?
  • BÍ A ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ NÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU
  • Mímú Eso Ikora-ẹni-Nijaanu Dàgbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Kó Ara Rẹ Níjàánu Kí o Lè Gba Èrè Náà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ikora-ẹni-nijaanu—Eeṣe Ti Ó Fi Ṣe Pataki Tobẹẹ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 2 ojú ìwé 4-5
Ìyá kan kò gbà kí ọmọkùnrin rẹ̀ mú súìtì nílé ìtajà kan

Ẹ̀KỌ́ 1

Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu

KÍ NI ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU?

Ẹni tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu:

  • kì í wá ìgbádùn ojú ẹsẹ̀

  • máa ń ronú jinlẹ̀ kó tó ṣe nǹkan

  • máa ń parí ohun tó bá bẹ̀rẹ̀, tí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún un

  • máa ń fi àǹfààní àwọn míì ṣáájú ti ara rẹ̀

KÍ NÌDÍ TÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU FI ṢE PÀTÀKÌ?

Àwọn ọmọ tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu máa ń dúró lórí ìpinnu wọn pé àwọn ò ní ṣe ohun tí kò dáa, kódà tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n fẹ́ràn gan-an. Àmọ́, àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ tí kì í kó ara wọn níjàánu:

  • wọ́n máa ń tètè bínú

  • wọ́n máa ń ní ìdààmú ọkàn

  • wọ́n máa ń mu sìgá àti ọtí líle, wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró

  • wọ́n máa ń jẹ pàrùpárù oúnjẹ

Ìwádìí kan fi hàn pé tí àwọn ọmọ tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu bá dàgbà, wọn kì í sábà rú òfin, wọn kì í sábà ní ìṣòro àìlera tàbí kí wọ́n máa kanra torí pé wọn ò lówó lọ́wọ́. Ìwádìí yẹn ló mú kí ọ̀jọ̀gbọ́n Angela Duckworth tó wá láti Yunifásítì Pennsylvania gbà pé: “Ìkóra-ẹni-níjàánu kì í pọ̀ jù.”

BÍ A ṢE LÈ KỌ́ ỌMỌ NÍ ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

Máa dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.’​—Mátíù 5:37.

Àwọn ọmọdé máa ń dìídì ṣe ìjàngbọ̀n nígbà míì, kí wọ́n lè wò ó bóyá àwọn òbí wọn á ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n tiẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbangba. Táwọn òbí bá ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, àwọn ọmọ yẹn á wá rí i pé táwọn bá ṣe ìjàngbọ̀n àwọn òbí àwọn á ṣe ohun tí wọn ò fẹ́ ṣe.

Àmọ́ tí àwọn òbí bá dúró lórí ọ̀rọ̀ wọn, ńṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọwọ́ èèyàn máa ń tẹ ohun tó ń fẹ́. Èyí bá ohun tí Dókítà David Walsh sọ mu pé: “Ẹni tó bá gbà pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọwọ́ èèyàn máa ń tẹ ohun tó bá ń fẹ́ ló máa ń láyọ̀ jù lọ. A ò ṣe àwọn ọmọ wa láǹfààní kankan, tá a bá ń kọ́ wọn pé gbogbo ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ lọwọ́ wọn máa tẹ̀.”a

Tó o bá ń dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ, ó máa ṣe ọmọ rẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó máa rọrùn fún un láti kọ̀ jálẹ̀ tí wọ́n bá ní kó lo oògùn olóró, kó ṣe ìṣekúṣe, tàbí tí wọ́n bá ní kó lọ́wọ́ sí àwọn ìwà burúkú míì.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé kò sí ohun tó ṣe tí kò lérè.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”​—Gálátíà 6:7.

Ó yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ pé gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ṣe ni wọ́n máa jèrè. Torí náà tí wọn ò bá kí ń kó ara wọn níjàánu, ohun tó máa gbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá ń bínú jù táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́, àwọn èèyàn lè máa sá fún un. Àmọ́ tó bá ń kó ara rẹ̀ níjàánu táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́, tó sì ń ṣe sùúrù, àwọn èèyàn á sún mọ́ ọn. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ó máa láyọ̀ tó bá ń kó ara rẹ̀ níjàánu.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

Ìkóra-ẹni-níjàánu kọjá pé kéèyàn yẹra fún ohun tí kò dáa, ó tún máa ń jẹ́ kéèyàn ṣe ohun tó yẹ kó ṣe, kódà tí ohun náà kò bá gbádùn mọ́ni. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ló yẹ kó kọ́kọ́ máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ilé ìwé rẹ̀ kó tó lọ ṣeré.

Jẹ́ àpẹẹrẹ rere.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.”​—Jòhánù 13:15.

Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí i pé o máa ń kó ara rẹ níjàánu tí inú bá ń bí ẹ tàbí tó o bá ń kojú ìṣòro, kí wọ́n lè mọ̀ pé àǹfààní wà nínú kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ bá ṣe nǹkan tó bí ẹ nínú, ṣé o máa ń fara ya ni àbí o máa ń ṣe sùúrù?

a Látinú ìwé náà No: Why Kids​—of All Ages—​Need to Hear It and Ways Parents Can Say It.

Ìyá kan kò gbà kí ọmọkùnrin rẹ̀ mú súìtì nílé ìtajà kan

TÈTÈ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í KỌ́ ỌMỌ RẸ

Tó o bá ń dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ, ó máa ṣe ọmọ rẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ó máa rọrùn fun un láti kọ̀ jálẹ̀ tí wọ́n bá ní kó lo oògùn olóró, kó ṣe ìṣekúṣe, tàbí tí wọ́n bá ní kó lọ́wọ́ sí àwọn ìwà burúkú míì

Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere

  • Ṣé ọmọ mi mọ̀ mí sí ẹni tí kì í bínú jù tí nǹkan ò bá rí bí mo ṣe rò?

  • Ṣé mo ti ṣàlàyé fún ọmọ mi ìdí tí mo fi máa ń fi sùúrù yanjú ìṣòro tí mo bá ní?

  • Irú ẹni wo ni ọmọ mi mọ̀ mí sí? Ṣé oníwàdùwàdù àti ẹni tó tètè máa ń bínú ni mí àbí ẹni tó mọ ohun tó ń ṣe, tó sì máa ń kápá ìbínú rẹ̀?

Ohun Tá A Ṣe . . .

“Tí ọmọbìnrin wa bá bínú tàbí tí nǹkan bá tojú sú u, a máa ń fi yé e pé kò gbọ́dọ̀ torí ìyẹn múnú bí àwọn tó wà láyìíká rẹ̀. Tí kò bá lè ṣe sùúrù kó sì kápá ìbínú rẹ̀, ńṣe la máa ń mú un lọ sínú yàrá títí tí ìbínú rẹ̀ fi máa rọlẹ̀.”​—Theresa.

“Èmi àti ìyàwó mi ti pinnu pé àá máa gbóríyìn fún àwọn ọmọ wa nígbàkigbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó wú wa lórí. A máa ń gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá fi sùúrù borí ìṣòro kan tó le.”​—Wayne.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́