ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 3 ojú ìwé 8-9
  • Ìdílé Aláyọ̀ àti Ọ̀rẹ́ Àtàtà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdílé Aláyọ̀ àti Ọ̀rẹ́ Àtàtà
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁ ṢE MÁA RO TARA Ẹ NÌKAN
  • FỌGBỌ́N YAN Ọ̀RẸ́
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
  • Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora- Ẹni-Wò—Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
    Jí!—2020
  • Ṣé Ọlọ́run Mọ Bí Nǹkan Ṣe Máa Ń Rí Lára Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 3 ojú ìwé 8-9
Ìdílé kan ń gbádùn ara wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn

Ìdílé Aláyọ̀ àti Ọ̀rẹ́ Àtàtà

Ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú ẹbí àti ọ̀rẹ́. Àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn.

MÁ ṢE MÁA RO TARA Ẹ NÌKAN

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Ẹ wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’​—Fílípì 2:4.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Tó o bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì, ńṣe ni kó o máa ṣoore fáwọn èèyàn dípò kó o máa retí pé kí wọ́n máa ṣoore fún ẹ. Tó bá jẹ́ tara ẹ nìkan lo mọ̀, ó lè ṣòro fún ẹ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ló máa ń jẹ́ kí àwọn tọkọtaya dalẹ̀ ara wọn, ìyẹn sì máa ń da ìgbéyàwó rú. Tẹ́nì kan bá sì fẹ́ràn kó máa fọ́nnu nípa ohun tó ní tàbí ohun tó mọ̀, àwọn èèyàn ò ní fẹ́ máa bá a ṣọ̀rẹ́. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Road to Character tiẹ̀ sọ pé: “Àwọn tí kò mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ sábà máa ń ní ọ̀pọ̀ ìṣòro.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE:

  • Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọyì ara wọn máa ń finú tán ara wọn, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn tó máa ń ran ẹlòmíì lọ́wọ́ máa ń ní ìbàlẹ̀ ọkàn, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ní ìrẹ̀wẹ̀sì.

  • Máa gba tàwọn míì rò. Ẹni tó ní ìgbatẹnirò máa ń fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ̀ wò. Tó o bá ń gba tàwọn míì rò, á jẹ́ kó o lè máa fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí wọn, àwọn ọ̀rọ̀ tó ń gúnni bí idà tó sì ń tani bí agbọ́n kò ní máa jáde lẹ́nu ẹ.

    Tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò, á jẹ́ kó o ní àmúmọ́ra, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ṣojúsàájú, á sì mú kó rọrùn fún ẹ láti máa sọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ẹ̀yà àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìẹ.

  • Máa wáyè gbọ́ táwọn èèyàn. Bó o bá ṣe ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn èèyàn tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa mọ̀ wọ́n. O ní láti máa wáyè fún àwọn èèyàn, kẹ́ ẹ sì jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè ní ọ̀rẹ́ gidi. Torí náà, máa fetí sílẹ̀ tẹ́nì kan bá ń sọ tinú ẹ̀ fún ẹ, kó o sì ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí pàtàkì. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé èèyàn máa láyọ̀ tó bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún ẹlòmíì.

FỌGBỌ́N YAN Ọ̀RẸ́

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà ọmọlúwàbí jẹ́.”​—1 Kọ́ríńtì 15:​33, àlàyé ìsàlẹ̀.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́ lè kó bá ẹ tàbí kí wọ́n sọ ẹ́ dèèyàn gidi. Àwọn onímọ̀ nípa ìwà èèyàn sọ pé irú ọ̀rẹ́ téèyàn bá yàn lè pinnu bóyá ayé ẹni máa dáa tàbí kò ní dáa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé téèyàn bá ń ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń mu sìgá, ó ṣeé ṣe kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, tó bá sì jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó ń já ọkọ tàbí ìyàwó wọn jù sílẹ̀ lẹnì kan ń bá rìn, tó bá yá òun náà á fẹ́ máa ṣe bíi tiwọn.

OHUN TÓ O LÈ ṢE: Yan ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ní ìwà àtàtà tó o lè fara wé. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an tó o bá yan ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó máa ń fi ọgbọ́n ṣe nǹkan, tó máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, tó lawọ́, tó sì nífẹ̀ẹ́ àlejò.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

Obìnrin kan ń fi fídíò kọ́ ọmọbìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Wo àwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì, tó lè ṣèrànwọ́ fáwọn tọkọtaya, ọ̀dọ́ àti ọmọdé

YẸRA FÚN Ọ̀RỌ̀ ÈÉBÚ.

“Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni.”—ÒWE 12:18.

JẸ́ Ọ̀LÀWỌ́.

“Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí.”​—ÒWE 11:25.

OHUN TÓ O FẸ́ KÉÈYÀN ṢE SÍ Ẹ NI KÓ O MÁA ṢE SÍ WỌN.

“Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”​—MÁTÍÙ 7:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́