ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 3 ojú ìwé 12-13
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sún Mọ́ Ọlọ́run
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌRÈTÍ
  • ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
  • Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
    Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
  • Ohun Míì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
    Jí!—2018
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run? Ṣé Mo Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Bí Mi Ò Bá Ṣe Ẹ̀sìn Kankan?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Òbí
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 3 ojú ìwé 12-13
Obìnrin kan jókòó lórí àga inú ọgbà, ó ń ronú

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìwé mímọ́ ni Bíbélì. Wọ́n ti rí i pé báwọn ṣe ń kà á, táwọn sì ń fi ohun tó wà nínú rẹ̀ sílò, ńṣe làwọn túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn lójú.

Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kò ní “ẹ̀mí Ọlọ́run,” ńṣe ló ń tọ́ka sí àwọn tí kò fi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó dáa. (Júùdù 18, 19) Àmọ́ àwọn tó ní ẹ̀mí Ọlọ́run mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé e. Wọn ò dà bí àwọn ẹni tara tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa tẹ́ ara wọn lọ́rùn nìkan ni wọ́n máa ń rò.​—Éfésù 5:1.

ÌRÈTÍ

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.”​—Òwe 24:10, àlàyé ìsàlẹ̀.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ìrẹ̀wẹ̀sì kì í jẹ́ ká lókun láti kojú àwọn ìṣòro wa. Àmọ́, tá a bá ní ìrètí, àá ní ìgboyà láti máa fara dà á nìṣó láìbẹ̀rù. Tá a bá ń fi sọ́kàn pé láìròtẹ́lẹ̀ nǹkan lè yí pa dà sí rere, ọkàn wa máa balẹ̀; kódà, ohun rere lè tinú àwọn ìṣòro náà jáde.

OHUN TÓ O LÈ ṢE: Gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Dípò kó o máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀, tàbí kó o máa dúró de àkókò tí gbogbo nǹkan máa pé pérépéré kó o tó ṣe nǹkan, á dáa kó o máa gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí àwọn àfojúsùn rẹ kọ̀ọ̀kan, torí pé àwọn nǹkan tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nígbàkígbà. (Oníwàásù 9:11) Ká sòótọ́, nǹkan lè pa dà wá dáa ju bá a ṣe rò lọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, nítorí o ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa, bóyá èyí tàbí ìyẹn, ó sì lè jẹ́ àwọn méjèèjì ló máa ṣe dáadáa.”​—Oníwàásù 11:6.

ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: ‘Fún mi ní òye, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.’​—Sáàmù 119:144, 160.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló máa ń béèrè. Bí àpẹẹrẹ, ó dáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

  • Ibo la ti wá?

  • Kí nìdí tá a fi wà láyé yìí?

  • Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?

  • Ṣé ìgbésí ayé ẹ̀dá ò jù báyìí náà lọ?

Àìmọye èèyàn kárí ayé ni ìgbésí ayé wọn ti dára gan-an, torí pé wọ́n ti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè pàtàkì míì.

OHUN TÓ O LÈ ṢE: Ṣèwádìí fúnra ẹ kó o lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá mọ̀ pé kó kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo, tàbí kó o wá sí ìpàdé wa. Gbogbo èèyàn la pè, a kì í gbowó ìwọlé.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

Obìnrin kan ń wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí jw.org

Wo fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lórí jw.org/yo. Ó wà ní ohun tó ju 880 èdè lọ

MÁA WÁ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌ́RUN.

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”​—MÁTÍÙ 5:3.

MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA ỌLỌ́RUN NÍNÚ BÍBÉLÌ.

“Wá Ọlọ́run . . . wàá sì rí i ní ti gidi . . . kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”​—ÌṢE 17:27.

KA BÍBÉLÌ, KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀ NÍPA OHUN TÓ WÀ NÍNÚ RẸ̀.

“Òfin Jèhófàa máa ń mú inú rẹ̀ dùn, ó sì ń ṣe àṣàrò lórí òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru. . . . Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.”​—SÁÀMÙ 1:2, 3, àlàyé ìsàlẹ̀.

a Nínú Bíbélì, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́