Àǹfààní Tí Ìhìn Rere Náà Lè Ṣe Àwùjọ Yín
NÍ AYÉ òde òní, a sábà máa ń gbọ́ tí àwọn èèyàn máa ń sọ èrò wọn pé: “Àwọn ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni kò ṣeé tẹ̀ lé rárá ni. Wọn ò tiẹ̀ lè gbéṣẹ́ láwùjọ wa ìwòyí tó jẹ́ irú wá ògìrì wá ni.” Àmọ́ ṣá, èrò tó yàtọ̀ sí èyí ló jẹ yọ nínú ìjíròrò kan tí wọ́n ní ó wáyé láàárín aṣáájú ilẹ̀ Íńdíà náà, Mohandas K. Gandhi, àti Lord Irwin, Ajẹ́lẹ̀ fún ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní Íńdíà nígbà kan rí. Wọ́n ní Lord Irwin bi Gandhi léèrè pé kí ló rò pé ó máa yanjú àwọn ìṣòro àárín ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Íńdíà. Ni Gandhi bá gbé Bíbélì, ó ṣí i sí Mátíù orí karùn-ún, ó sì sọ pé: “Nígbà tí orílẹ̀-èdè tìrẹ àti tèmi yóò bá fi foríkorí lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi fi lélẹ̀ nínú Ìwàásù orí Òkè, àwọn ìṣòro ti orílẹ̀-èdè wa nìkan kọ́ la ó yanjú, a ó yanjú ti àgbáyé lápapọ̀ pẹ̀lú.”
Ìwàásù náà sọ nípa jíjẹ́ kí ohun tẹ̀mí jẹni lọ́kàn àti jíjẹ́ onínú tútù, ẹlẹ́mìí àlàáfíà, aláàánú àti olùfẹ́ òdodo. Kì í ṣe pé ó bẹnu àtẹ́ lu ìpànìyàn nìkan ni, ó tún dẹ́bi fún ẹ̀mí kíkún fún ìrunú sí ẹlòmíràn, kò fi mọ sórí bíbẹnu àtẹ́ lu ìwà àgbèrè, ó tún dẹ́bi fún jíjẹ́ kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe pẹ̀lú. Ó dẹ́bi fún ìkọ̀sílẹ̀ tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu, èyí tó ń fọ́ àwọn ìdílé tó sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ. Ó sọ fún wa pé: ‘Kí ẹ tiẹ̀ fẹ́ràn àwọn tó kórìíra yín pàápàá, ẹ pèsè fún àwọn aláìní, ẹ ṣíwọ́ dídá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lọ́nà àìláàánú, irú ìwà tí ẹ ń fẹ́ kí àwọn èèyàn máa hù sí yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà hù sí wọn.’ Bí a bá fi gbogbo ìmọ̀ràn yìí sílò, àǹfààní ńláǹlà ni yóò mú wá. Bí àwọn èèyàn bá ṣe ń fi wọ́n ṣèwà hù tó ládùúgbò yín náà ni àdúgbò yín yóò ṣe sunwọ̀n sí i tó!
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà a máa súnni ṣe èyí. Bíbélì kọ́ wọn nípa bí wọn yóò ṣe bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó. Àwọn ìlànà ìwà híhù títọ́ ni wọ́n fi tọ́ àwọn ọmọ wọn. Wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ṣíṣe tí ìdílé ṣe pàtàkì. Ìbùkún gidi ni àwọn ìdílé tó bá wà ní ìṣọ̀kan jẹ́ fún ìlú rẹ àti orílẹ̀-èdè rẹ pàápàá. Bí a bá yẹ ìwé ìtàn wò, a óò rí àwọn àpẹẹrẹ tó pọ̀ lọ súà nípa bí àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára jù lọ láyé yìí ṣe fọ́ lásìkò tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ kò sí láàárín àwọn ìdílé wọn, tí ìṣekúṣe sì gbilẹ̀. Bí iye àwọn èèyàn àti àwọn ìdílé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá lè sún láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristẹni bá ṣe pọ̀ tó ni ìwà ìpáǹle, ìṣekúṣe, àti ìwà ọ̀daràn yóò ṣe dín kù tó láwùjọ yín.
Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro ńlá tó ń yọ àwọn àwùjọ àti orílẹ̀-èdè lẹ́nu ni ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àmọ́, ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ ni pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé pé: “Kò sí Júù tàbí Gíríìkì, kò sí ẹrú tàbí òmìnira, kò sí akọ tàbí abo; nítorí ẹnì kan ṣoṣo ni gbogbo yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (Ìṣe 10:34, 35; Gálátíà 3:28) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni gbogbo ẹ̀yà àti àwọn tó jẹ́ onírúurú àwọ̀ jọ ń gbé tí wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní orílé iṣẹ́ wọn, ní àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wọn, àti nínú àwọn ìjọ wọn.
Ní Áfíríkà, àwọn ẹ̀yà kan ò lè wà pa pọ̀ láìsí ìjà láìsí ìta. Àmọ́, nínú àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀, ńṣe ni àwọn èèyàn látinú onírúurú ẹ̀yà jọ ń jẹun, wọ́n jọ ń sùn, tí wọ́n sì jọ ń jọ́sìn pa pọ̀, nínú ìṣọ̀kan gidi àti àjọṣepọ̀ ọlọ́yàyà. Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n bá ti rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Ìwé ìròyìn New York Amsterdam News ti August 2, 1958 sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ kan tó fi hàn bí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ṣe máa ń mú ìṣọ̀kan wá. Ohun tó rí nínú ìpàdé àgbáyé táa mẹ́nu kàn níṣàájú níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ju ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ tí péjọ pọ̀ ní Ìlú New York, ló fa ọ̀rọ̀ tó sọ yìí.
“Ní gbogbo ibi tóo bá wò, ńṣe ni àwọn èèyàn dúdú, àwọn aláwọ̀ funfun àti àwọn ará Ìlà Oòrùn ayé, yálà tálákà tàbí ọlọ́rọ̀, láti apá ibi gbogbo láyé yìí, jọ dà pọ̀ mọ́ra fàlàlà tìdùnnú-tìdùnnú. . . . Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti ọgọ́fà ilẹ̀ láti wá ṣèjọsìn yìí gbé pa pọ̀, wọ́n sì jọ́sìn pa pọ̀ lálàáfíà, ní fífi han àwọn ará Amẹ́ríkà pé ohun tó rọrùn láti ṣe wẹ́rẹ́ ni. . . . Ìpàdé yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ tó hàn kedere nípa bí àwọn èèyàn ṣe lè ṣiṣẹ́ pọ̀ kí wọ́n sì gbé pọ̀.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn lè sọ pé àwọn ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni kò gbéṣẹ́ lóde ìwòyí. Àmọ́, ohun mìíràn wo ló ti gbéṣẹ́ tàbí èwo ló máa gbéṣẹ́ bíi tiẹ̀? Àwọn ìlànà Kristẹni jẹ́ ohun tí yóò wúlò gidigidi, bó bá di lílò láàárín àwùjọ tí o ń gbé nísinsìnyí, ìlànà yẹn ni yóò sì jẹ́ ìpìlẹ̀ fún mímú kí ìṣọ̀kan wà nínú gbogbo ‘àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ènìyàn’ kárí ayé bí Ìjọba Ọlọ́run bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso aráyé.—Ìṣípayá 7:9, 10.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà àti àwọ̀ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
Ẹ̀sìn Kristẹni gbéṣẹ́. Ohun mìíràn wo ló ti gbéṣẹ́?