ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • Ìsíkíẹ́lì ń gba inú odò tó ń ṣàn kọjá, ọkùnrin tó ní ìrísí bàbà ń wò ó láti etí odò náà.

      ORÍ 19

      ‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi Tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’

      ÌSÍKÍẸ́LÌ 47:9

      OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Bí ìran odò tó ń ṣàn látinú tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́, bó ṣe ń ṣẹ lóde òní àti bó ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú

      1, 2. Bí Ìsíkíẹ́lì 47:​1-12 ṣe sọ, kí ni Ìsíkíẹ́lì rí, ẹ̀kọ́ wo ló sì kọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

      ÌSÍKÍẸ́LÌ tún rí ohun àrà míì nínú ìran tẹ́ńpìlì náà: Ó rí omi tó ń ṣàn jáde látinú ibi mímọ́! Ẹ fojú inú wo bí Ìsíkíẹ́lì ṣe ń tọpasẹ̀ omi tó mọ́ lóló náà lọ kó lè mọ ibi tó ti ń ṣàn wá. (Ka Ìsíkíẹ́lì 47:​1-12.) Omi náà rọra ń sun látẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì; ó sì ṣàn jáde gba inú àgbàlá tẹ́ńpìlì tó wà nítòsí ẹnubodè ìlà oòrùn. Áńgẹ́lì tó ń fi ìran han Ìsíkíẹ́lì mú un jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó sì ń wọn ìrìn wọn àti jíjìn omi náà bí wọ́n ṣe ń lọ. Áńgẹ́lì náà ń sọ fún Ìsíkíẹ́lì léraléra pé kó gba inú omi náà kọjá, wòlíì náà sì ń rí i pé ṣe lomi náà ń yára kún sí i bí wọ́n ṣe ń lọ, kò pẹ́ tómi yìí fi di alagbalúgbú tí kò ṣeé fi ẹsẹ̀ là kọjá, àfi kéèyàn lúwẹ̀ẹ́!

      2 Áńgẹ́lì náà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé omi yẹn ṣàn lọ sínú Òkun Òkú, ó sì ń wò ó sàn. Kò sí ohun alààyè kankan nínú òkun yẹn tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí ẹja ti wá pọ̀ rẹpẹtẹ níbẹ̀. Ìsíkíẹ́lì rí àwọn igi lóríṣiríṣi ní etí odò náà. Oṣooṣù làwọn igi yìí ń mú èso aṣaralóore jáde, wọ́n sì tún ń yọ àwọn ewé tó ń woni sàn. Ó dájú pé gbogbo ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí máa mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀, ó sì tún máa fún un nírètí. Àmọ́ kí ni tẹ́ńpìlì tó rí nínú ìran yìí túmọ̀ sí fún òun àti àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn? Báwo ló sì ṣe kan àwa náà lónìí?

      Kí Ni Ìran Nípa Odò Túmọ̀ Sí fún Àwọn Tó Wà Nígbèkùn?

      3. Kí nìdí tí àwọn Júù àtijọ́ ò fi ka odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran sí odò gidi?

      3 Àwọn Júù àtijọ́ ò wo ìran nípa odò náà bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí apá ibi tí wọ́n kà nínú Ìwé Mímọ́ yìí rán wọn létí àsọtẹ́lẹ̀ míì tí Ọlọ́run sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, èyí tó ṣeé ṣe kí wòlíì Jóẹ́lì ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. (Ka Jóẹ́lì 3:18.) Nígbà táwọn Júù tó wà nígbèkùn ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí tí Jóẹ́lì kọ yẹn, wọn ò retí pé kí ‘wáìnì dídùn máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè’ ní tààràtà; tàbí pé kí ‘wàrà máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,’ bẹ́ẹ̀ ni wọn ò retí pé kí odò máa ṣàn jáde “láti ilé Jèhófà.” Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn gbà pé kì í ṣe odò gangan ni ohun tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ń tọ́ka sí.a Ó dáa, kí wá ni Jèhófà ń fi èyí sọ fún wọn? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn apá kan nínú ìran yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta pàtàkì kan tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí mú kó dá wa lójú.

      Odò.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19A: Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà

      4. (a) Àwọn ìbùkún wo ni àwọn Júù á máa retí látọ̀dọ̀ Jèhófà bí wọ́n ṣe gbọ́ nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? (b) Báwo ni bí Bíbélì ṣe ń lo “odò” àti “omi” ṣe fi dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀? (Wo àpótí náà, “Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà.”)

      4 Odò ìbùkún. Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi odò àti omi ṣàpèjúwe bí ìbùkún Jèhófà tó ń fúnni ní ìyè ṣe ń ṣàn. Irú odò yìí ni Ìsíkíẹ́lì rí tó ń ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì, torí náà, ìran yìí á ti mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa retí pé ìbùkún Jèhófà tó ń fúnni ní ìyè máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn tí wọn ò bá yéé ṣe ìjọsìn mímọ́. Àwọn ìbùkún wo nìyẹn? Wọ́n á tún máa gba ìtọ́ni tẹ̀mí látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà. Bí wọ́n sì ṣe ń rúbọ ní tẹ́ńpìlì, á tún dá wọn lójú pé ètùtù yẹn máa ṣiṣẹ́ fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Ìsík. 44:​15, 23; 45:17) Torí náà, wọ́n á tún wà ní mímọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, bíi pé wọ́n fi omi tó mọ́ lóló tó ń tú jáde látinú tẹ́ńpìlì wẹ̀.

      5. Tí ẹnì kan bá ń ṣiyèméjì pé bóyá ni ìbùkún Jèhófà máa tó fún gbogbo èèyàn, báwo ni ìran nípa odò tó ń ṣàn ṣe máa fi onítọ̀hún lọ́kàn balẹ̀?

      5 Ṣé gbogbo ìgbà ni ìbùkún tó pọ̀ tó á máa wà fún gbogbo èèyàn? Ó dájú pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà máa mú kí ọkàn ẹni tó bá ń ṣiyèméjì balẹ̀, iṣẹ́ ìyanu gbáà ni bó ṣe rí i tí omi náà ń kún sí i, látibi odò tó rọra ń ṣàn débi tó fi di odò tó ń ya mùúmùú, bẹ́ẹ̀ sì rèé, díẹ̀ ló fi ṣàn ju máìlì kan lọ! (Ìsík. 47:​3-5) Òótọ́ ni pé iye àwọn Júù tó pa dà sílẹ̀ wọn á máa pọ̀ sí i; bákan náà ìbùkún Jèhófà á máa pọ̀ sí i kí wọ́n lè ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Odò yìí ṣàpẹẹrẹ ohun tó pọ̀ rẹpẹtẹ!

      6. (a) Ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ló wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí? (b) Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      6 Omi ìyè. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò náà ṣàn lọ sínú Òkun Òkú, ó sì wo àwọn apá tó pọ̀ lára òkun náà sàn. Kíyè sí i pé omi náà mú kí àwọn ẹja wà láàyè, àwọn ẹja lónírúurú bíi tàwọn tó wà nínú Òkun Ńlá tàbí Òkun Mẹditaréníà. Kódà iṣẹ́ ẹja pípa ń gbèrú sí i nítòsí Òkun Òkú, ìyẹn láàárín ìlú méjì tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síra. Áńgẹ́lì náà sọ pé: “Gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.” Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé apá ibi gbogbo nínú Òkun Òkú náà ni omi tó ń ṣàn bọ̀ láti ilé Jèhófà ṣàn dé? Rárá o. Nínú àlàyé tí áńgẹ́lì náà ṣe, ó sọ pé àwọn ibi àbàtà kan wà tí omi ìyè náà ò ṣàn dé. Ibẹ̀ máa “di ilẹ̀ iyọ̀.”b (Ìsík. 47:​8-11) Torí náà, ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn mímọ́ máa mú kí àwọn èèyàn sọ jí, á sì mú kí wọ́n gbilẹ̀. Àmọ́ ìkìlọ̀ tó ń ró gbọnmọgbọnmọ nínú ọ̀rọ̀ yìí ni pé: Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa rí ìbùkún Jèhófà, kì í sì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa rí ìwòsàn.

      7. Tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn bá ń ronú nípa àwọn igi tó wà létí odò náà, báwo nìyẹn ṣe máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

      7 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Kí wá ni ti àwọn igi tó wà ní etí odò náà? Àwọn igi náà bu ẹwà kún odò náà. Wọ́n tún mú kó fani mọ́ra. Ó dájú pé inú Ìsíkíẹ́lì àtàwọn ará ìlú rẹ̀ á máa dùn bí wọ́n ṣe ń ronú lórí èso aládùn tírú àwọn igi bẹ́ẹ̀ máa ń mú jáde, oṣooṣù ló sì máa ń mú èso tuntun jáde! Ó dájú pé ìran yìí á túbọ̀ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa bọ́ wọn yó nípa tẹ̀mí. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o. Ewé àwọn igi yẹn tún máa “wà fún ìwòsàn.” (Ìsík. 47:12) Jèhófà mọ̀ pé àwọn tó dé láti ìgbèkùn máa nílò ìwòsàn tẹ̀mí ju ohunkóhun míì lọ, ohun tó sì ṣèlérí pé òun máa fún wọn nìyẹn. Ọ̀nà tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, bá a ṣe rí i ní Orí 9 ìwé yìí.

      8. Kí ló fi hàn pé ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò?

      8 Àmọ́ ṣá o, bá a tún ṣe sọ ní Orí 9, kì í ṣe gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà ló ṣẹ lójú àwọn tó dé láti ìgbèkùn. Àwọn èèyàn náà fúnra wọn ló ṣe ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n rí ìmúṣẹ gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà. Báwo ni Jèhófà ṣe máa bù kún wọn nígbà tó jẹ́ pé ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ni wọ́n tún gbé wọ̀, tí wọ́n ń ṣàìgbọràn, tí wọ́n sì pa ìjọsìn mímọ́ tì? Ohun táwọn apẹ̀yìndà yẹn ṣe dun àwọn Júù olóòótọ́. Àmọ́, àwọn adúróṣinṣin tó ń sin Jèhófà mọ̀ pé àwọn ìlérí rẹ̀ ò lè lọ láìṣẹ; dandan ni kó ṣẹ. (Ka Jóṣúà 23:14.) Torí náà, ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran máa ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò. Àmọ́ ìgbà wo nìyẹn máa jẹ́?

      Odò Yẹn Ń Ṣàn Lónìí!

      9. Ìgbà wo ni ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò?

      9 Bá a ṣe rí i ní Orí 14 ìwé yìí, ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí máa ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run máa gbé ìjọsìn mímọ́ ga ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Àìsá. 2:2) Ọ̀nà wo ni apá tá à ń jíròrò nínú ìran Ìsíkíẹ́lì yìí gbà ń ṣẹ lákòókò wa yìí?

      10, 11. (a) Àwọn ìbùkún wo ló ń ṣàn wá sọ́dọ̀ wa bí odò lónìí? (b) Báwo ni ìbùkún Jèhófà tó ń ṣàn bí odò ṣe pọ̀ tó láti kájú ohun tá a nílò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

      10 Odò ìbùkún. Ìbùkún wo ni omi tó ń ṣàn jáde láti ilé Jèhófà rán wa létí rẹ̀ lónìí? Ó rán wa létí gbogbo ohun tó ń mú ká ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí àtàwọn nǹkan aṣaralóore tí Jèhófà pèsè fún wa. Èyí tó gbawájú jù lọ ni ti ẹbọ ìràpadà Kristi tó ní agbára láti wẹni mọ́, ìyẹn ló sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. A tún lè fi òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé omi ìyè, tó ń wẹni mọ́. (Éfé. 5:​25-27) Báwo làwọn ìbùkún yẹn ṣe ń ṣàn lákòókò wa yìí?

      11 Lọ́dún 1919, iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, àmọ́ ṣe ni inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò gbà. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i. Lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. Ṣé a lè sọ pé omi òtítọ́ tó mọ́ lóló ń yára ṣàn? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òtítọ́ inú Bíbélì ni ètò Ọlọ́run ti ṣàlàyé fún wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ àti àṣàrò kúkúrú ni wọ́n tẹ̀ jáde fáwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́gọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Bíi ti odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti yára ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn tí òùngbẹ tẹ̀mí ń gbẹ kárí ayé, kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde. Ní báyìí, ìkànnì jw.org ti mú kó ṣeé ṣe láti wa àwọn ìwé jáde ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) sórí fóònù tàbí ẹ̀rọ míì! Ipa wo ni omi òtítọ́ yìí ń ní lórí àwọn èèyàn tó lọ́kàn tó tọ́?

      12. (a) Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe ń fún àwọn èèyàn ní ìyè àti ìlera? (b) Ìkìlọ̀ tó bọ́ sásìkò wo ló wà nínú ìran yẹn fún wa lónìí? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      12 Omi ìyè. Ọlọ́run sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.” Ẹ wo ọ̀nà tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ gbà ṣàn bí odò dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó wà ní ilẹ̀ tẹ̀mí tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ti fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní ìyè, ó sì ti mú kí wọ́n ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí. Àmọ́ o, ìkìlọ̀ kan wà nínú ìran náà tó bọ́ sásìkò gan-an, òun ni pé: Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà. Bíi ti irà àti àbàtà tó wà nínú Òkun Òkú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, àwọn kan wà tí ọkàn wọn ti yigbì, wọn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́, wọn ò sì fi sílò.c Ó dájú pé a ò ní jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa láé!​—Ka Diutarónómì 10:​16-18.

      13. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lónìí látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa àwọn igi?

      13 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Ṣé a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn igi tó wà létí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? Bẹ́ẹ̀ ni! Rántí pé, àwọn igi yẹn ń mú èso tuntun jáde lóṣooṣù, ewé wọn sì ń woni sàn. (Ìsík. 47:12) Ìyẹn rán wa létí pé ọ̀làwọ́ ni Ọlọ́run tá à ń sìn, ó ń bọ́ wa, ó sì ń wò wá sàn lọ́nà tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn nípa tẹ̀mí. Àìsàn tẹ̀mí ń ṣe ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí, bẹ́ẹ̀ lebi tẹ̀mí ń pa wọ́n. Àmọ́ tiwa ò rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti pèsè fún wa. Ó ṣeé ṣe kó o ti ka àpilẹ̀kọ kan nínú àwọn ìwé ìròyìn wa tàbí kó o kọ orin ìparí nígbà àpéjọ àyíká tàbí ti agbègbè, bóyá ṣe lo sì wo ọ̀kan lára fídíò wa tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n, tára wá tù ẹ́ pé oúnjẹ tẹ̀mí nìyí! Ká sòótọ́, Jèhófà ń bọ́ wa yó nípa tẹ̀mí. (Àìsá. 65:​13, 14) Ǹjẹ́ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń jẹ ń mú ká ní ìlera tó dáa nípa tẹ̀mí? Ìmọ̀ràn rere tá à ń gbà, èyí tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń jẹ́ ká lè gbógun ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀, irú bí ìṣekúṣe, ojúkòkòrò àti àìnígbàgbọ́. Jèhófà tún ní ètò kan tó ń jẹ́ káwa Kristẹni lè borí àìsàn tẹ̀mí tí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń fà. (Ká Jémíìsì 5:14.) Lóòótọ́, à ń gbádùn ìbùkún rẹpẹtẹ, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa àwọn igi.

      14, 15. (a) Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ ká kọ́ látinú ibi irà tí kò ṣeé wò sàn nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (b) Báwo ni odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe ń ṣe wá láǹfààní lónìí?

      14 Bákan náà, a tún lè rí ohun kan kọ́ nípa àwọn ibi irà tí omi náà ò wò sàn. Ìbùkún Jèhófà dà bí odò tó ń ṣàn, torí náà a ò ní fẹ́ ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó ṣàn dénú ayé wa. Ó máa burú gan-an tẹ́nì kan bá lọ ya aláìṣeéwòsàn, bíi ti ọ̀pọ̀ nínú ayé aláìsàn yìí. (Mát. 13:15) Ní tiwa, ṣe ni inú wa ń dùn bá a ṣe ń jàǹfààní látinú odò ìbùkún tó ń ṣàn. Bá a ṣe ń fìtara mu omi òtítọ́ tó mọ́ lóló látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń sọ òtítọ́ tá a kọ́ fún àwọn míì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bá a ṣe ń gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́, ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tí ẹrú olóòótọ́ ti dá lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ń rán wa létí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Odò yẹn ń fúnni ní ìyè, ó sì ń woni sàn ní gbogbo ibi tó bá ṣàn dé!

      15 Báwo ni ìran nípa odò yìí ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú? Bá a ṣe máa rí i, odò náà máa ṣàn lọ́nà tó gbòòrò jù lọ nínú Párádísè tó ń bọ̀.

      Ohun tí Ìran Náà Máa Túmọ̀ Sí Nínú Párádísè

      16, 17. (a) Ọ̀nà wo ni omi ìyè máa gbà ṣàn lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò nínú Párádísè? (b) Àwọn àǹfààní wo la máa jẹ látinú odò ìbùkún tá a bá dénú Párádísè?

      16 Ṣé o máa ń fojú inú wò ó pé o wà nínú Párádísè, pé ẹbí àti ọ̀rẹ́ yí ẹ ká, tẹ́ ẹ jọ ń gbádùn ara yín? Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó máa jẹ́ kó o lè túbọ̀ rí ohun tó ò ń rò náà kedere. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká tún gbé apá mẹ́ta yẹ̀ wò lára ìran náà, apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ṣe kedere tó sì fi ìfẹ́ hàn.

      17 Odò ìbùkún. Odò ìṣàpẹẹrẹ tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí máa ṣàn gan-an nínú Párádísè, ìbùkún tí odò náà sì máa mú wá ò ní jẹ́ ìbùkún tẹ̀mí nìkan, ó tún máa mú ìbùkún tara wá. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù, Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù lọ́nà tó ga. Díẹ̀díẹ̀ la máa di ẹni pípé! Àìsàn ò ní sí mọ́, kò ní sí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì mọ́, kódà kò ní sí ilé ìwòsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní nílò ètò ìlera táwọn èèyàn ṣe mọ́! Omi ìyè yẹn máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jáde wá látinú “ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:​9, 14) Nígbà tí odò ìbùkún yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn, ó máa jọni lójú gan-an, àmọ́ kò ní tó nǹkan kan tá a bá fi wé bó ṣe máa ṣàn tó nígbà tó bá yá. Bó ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò yẹn máa ṣàn káàkiri kó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nílò rẹ̀.

      Àwọn èèyàn tí ara wọn le, tí wọ́n sì ní okun ọ̀dọ́ ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń gbádùn ara wọn nínú Párádísè. Odò tó ń ṣàn wà lẹ́yìn wọn.

      Nínú Párádísè, odò ìbùkún máa mú kí àwọn àgbàlagbà di ọ̀dọ́, kí ara wọn sì le (Wo ìpínrọ̀ 17)

      18. Ọ̀nà wo ni “odò omi ìyè” náà máa gbà di alagbalúgbú omi nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

      18 Omi ìyè. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, “odò omi ìyè” náà máa di alagbalúgbú omi. (Ìfi. 22:1) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú máa jíǹde, wọ́n á sì láǹfààní láti gbé títí láé nínú Párádísè! Lára ìbùkún tí Jèhófà máa mú wá nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ni pé ó máa jí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ti kú dìde, àwọn tí ikú ti pa tipẹ́tipẹ́ ní ayé. (Àìsá. 26:19) Àmọ́, ṣé gbogbo àwọn tó bá jíǹde ló máa wà láàyè títí láé?

      19. (a) Kí ló fi hàn pé òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bí omi tuntun máa wà nínú Párádísè? (b) Báwo ni àwọn kan ṣe máa di “ilẹ̀ iyọ̀” lọ́jọ́ iwájú?

      19 Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu. Àwọn àkájọ ìwé tuntun máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà yẹn. Torí náà, lára ohun tí odò ìtura tó ń ṣàn jáde látọ̀dọ̀ Jèhófà máa mú wá ni àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde, ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ẹ ò rí i pé ìyẹn máa dáa gan-an! Síbẹ̀ náà, àwọn kan ò ní tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà yẹn, wọ́n á yàn láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Òótọ́ ni pé àwọn kan lè ya ọlọ̀tẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn, àmọ́ Ọlọ́run ò ní gbà wọ́n láyè láti ba Párádísè jẹ́. (Àìsá. 65:20) Ìyẹn lè rán wa létí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, á sì mú ká ronú lórí àwọn ibi ẹrẹ̀ tí kò ṣeé wò sàn, ìyẹn àwọn ibi tó ti di “ilẹ̀ iyọ̀.” Ẹ ò rí i pé òmùgọ̀ ni àwọn tó ṣorí kunkun pé àwọn ò ní mu omi ìyè yẹn! Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan máa kóra jọ sẹ́yìn Sátánì. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà, wọ́n máa pa run títí láé.​—Ìfi. 20:​7-12.

      20. Ètò tó máa ṣe wá láǹfààní wo ni Ọlọ́run máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún tó máa rán wa létí àwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí?

      20 Àwọn igi tó wà fún oúnjẹ àti ìwòsàn. Jèhófà ò fẹ́ kí ìkankan nínú wa pàdánù ìyè ayérayé. Torí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gba àǹfààní ńlá tó nawọ́ ẹ̀ sí wa yìí, ó máa rí i dájú pé òun ṣe ètò kan bíi tàwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí. Nínú Párádísè, Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún tara àti tẹ̀mí sorí aráyé. Ní ọ̀run ńkọ́? Jésù Kristi àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá a jọba máa ṣàkóso fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà yìí máa lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi láti ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di pípé. (Ìfi. 20:6) Ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìwòsàn tara àti tẹ̀mí yìí rán wa létí àwọn igi tí Ìsíkíẹ́lì rí létí odò, ìyẹn àwọn igi tó ń mú èso aṣaralóore jáde, tí àwọn ewé rẹ̀ sì ń woni sàn. Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí jọ àsọtẹ́lẹ̀ míì tó ń tuni lára nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sílẹ̀. (Ka Ìfihàn 22:​1, 2.) Àwọn ewé tí Jòhánù rí “wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè lára dá.” Ọ̀kẹ́ àìmọye olóòótọ́ èèyàn ló máa jàǹfààní látinú iṣẹ́ àlùfáà táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣe.

      Odò tí Ìsíkíẹ́lì rí tó rọra ń ṣàn di alagbalúgbú omi.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19B: Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

      21. Kí ló wá sí ọkàn rẹ bó o ṣe ń ronú nípa odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí tó tẹ̀ lé e? (Wo àpótí náà, “Omi Kékeré Di Odò Ńlá!”)

      21 Bó o ṣe ń ronú lórí odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó dájú pé àlàáfíà àti ìrètí ló máa gba ọkàn rẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìgbà ọ̀tun ló ń dúró dè wá lọ́jọ́ iwájú! Rò ó wò ná, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí Párádísè ṣe máa rí, ó sì ń fìfẹ́ rọ̀ wá pé ká rí i pé a wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà bá ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò, tá a sì fojú rí àwọn ìlérí tó ṣe nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà. Ṣé wàá wà níbẹ̀? O lè máa rò ó pé bóyá ni àyè máa wà fún ẹ nínú Párádísè. Nínú orí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí apá tó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe fọkàn wa balẹ̀.

      a Ohun míì ni pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn, tí wọ́n rántí bí ilẹ̀ wọn ṣe rí mọ̀ pé odò náà kì í ṣe odò gangan, torí ó sọ pé odò náà ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì tó wà lórí òkè kan tó ga fíofío, òkè yẹn ò sì sí níbi tó ń sọ yẹn rárá. Bákan náà, ohun tó rí nínú ìran yẹn fi hàn pé odò náà ṣàn tààràtà láìsí ìdíwọ́ kankan títí lọ dé inú Òkun Òkú, ìyẹn ò sì ṣeé ṣe torí bí ilẹ̀ náà ṣe rí.

      b Èrò àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì ni pé ohun tó dáa ni gbólóhùn yẹn gbé yọ, wọ́n ní tipẹ́tipẹ́ ni bí àwọn èèyàn ṣe ń kó iyọ̀ kí wọ́n lè fi máa pa nǹkan mọ́ ti ń mú èrè gọbọi wá fáwọn oníṣòwò tó wà ní agbègbè Òkun Òkú. Àmọ́ ẹ kíyè sí i pé, apá tá a tọ́ka sí nínú Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn ibi ẹrẹ̀ náà “kò . . . ní rí ìwòsàn.” Wọ́n á wà láìlẹ́mìí, wọn ò ní ṣeé wò sàn, torí omi ìyè tó ń ṣàn jáde láti ilẹ̀ Jèhófà kò ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn. Torí náà, ó dà bíi pé pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, ohun tí kò dáa ni àwọn iyọ̀ tó wà níbi ẹrẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí.​—Sm. 107:​33, 34; Jer. 17:6.

      c Jésù sọ ohun tó fara jọ èyí nínú àpèjúwe nípa àwọ̀n ńlá. Àwọ̀n náà kó ẹja tó pọ̀ gan-an, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹja ọ̀hún ló “dáa.” Ṣe ni wọ́n máa da àwọn ẹja tí kò dáa nù. Jésù tipa báyìí kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó ń wá sínú ètò Jèhófà ya aláìṣòótọ́ nígbà tó bá yá.​—Mát. 13:​47-50; 2 Tím. 2:​20, 21.

      BÍ ÌJỌSÌN MÍMỌ́ ṢE KÀN Ẹ́

      1. Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa odò ṣe ṣẹ nígbà àtijọ́?

      2. Àwọn ọ̀nà wo la gbà ń rí ìmúṣẹ ìran yẹn lónìí?

      3. Báwo ni odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe máa ṣàn lọ́nà tó gbòòrò jù lọ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

  • “Pín Ilẹ̀ Náà Bí Ogún”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • Odò tó ṣàn lọ sínú òkun, ilẹ̀ tí wọ́n pín wà ní etí odò náà.

      ORÍ 20

      “Pín Ilẹ̀ Náà bí Ogún”

      ÌSÍKÍẸ́LÌ 45:1

      OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìtumọ̀ ilẹ̀ tí wọ́n pín

      1, 2. (a) Kí ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

      ÌSÍKÍẸ́LÌ ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìran kan tó dájú pé á mú kó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ọdún sẹ́yìn, ìyẹn nígbà ayé Mósè àti Jóṣúà. Lákòókò yẹn, Jèhófà sọ bí ààlà Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí fún Mósè, ó sì tún sọ fún Jóṣúà nígbà tó yá nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. (Nọ́ń. 34:​1-15; Jóṣ. 13:7; 22:​4, 9) Àmọ́, lọ́dún 593 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn pé kí wọ́n tún pín Ilẹ̀ Ìlérí náà fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì!​—Ìsík. 45:1; 47:14; 48:29.

      2 Kí ni Ọlọ́run fi ìran yìí sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn? Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìran yẹn ń fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí lóde òní? Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìran yìí máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú?

      Ìran Tó Mú Kí Ohun Mẹ́rin Dájú

      3, 4. (a) Ohun mẹ́rin wo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí kẹ́yìn mú kó dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú? (b) Nínú orí yìí, èwo nínú àwọn ìlérí tó mú kó dá wọn lójú la máa gbé yẹ̀ wò?

      3 Ìran tó kẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì rí ló wà nínú odindi orí mẹ́sàn-án nínú ìwé tó kọ. (Ìsík. 40:1–48:35) Ìran yìí mú kí ohun mẹ́rin dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa pa dà bọ̀ sípò. Kí làwọn ohun tó mú kó dá wọn lójú yẹn? Àkọ́kọ́ ni pé, ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Ìkejì, àwọn àlùfáà àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olódodo lá máa darí orílẹ̀-èdè tó pa dà bọ̀ sípò náà. Ìkẹta, gbogbo àwọn tó máa pa dà sí Ísírẹ́lì máa ní ilẹ̀ tiwọn. Ìkẹrin sì ni pé, Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, á sì máa bá wọn gbé bíi ti tẹ́lẹ̀.

      4 Orí 13 àti 14 ìwé yìí sọ bí méjì àkọ́kọ́ lára ìlérí yẹn ṣe máa ṣẹ, ìyẹn bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò àti bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olódodo á ṣe máa darí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nínú orí yìí, ohun kẹta tó mú kó dá wọn lójú la máa fún láfiyèsí, ìyẹn ìlérí nípa bí àwọn èèyàn ṣe máa jogún ilẹ̀ náà. Ní orí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tó dá lórí bí Jèhófà ṣe máa wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.​—Ìsík. 47:​13-21; 48:​1-7, 23-29.

      ‘Mo Pín Ilẹ̀ Yìí fún Yín Láti Jẹ́ Ogún Yín’

      5, 6. (a) Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ilẹ̀ wo ni wọ́n máa pín? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí lohun tí ìran nípa pínpín ilẹ̀ náà wà fún?

      5 Ka Ìsíkíẹ́lì 47:14. Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì rí ilẹ̀ kan nínú ìran, ìyẹn ilẹ̀ tó máa tó dà bí “ọgbà Édẹ́nì.” (Ìsík. 36:35) Jèhófà wá sọ pé: “Ilẹ̀ tí ẹ máa yàn bí ogún fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá (12) nìyí.” (Ìsík. 47:13) “Ilẹ̀” tí wọ́n máa pín ni ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó ti pa dà bọ̀ sípò, èyí tí àwọn tó wà nígbèkùn máa pa dà sí. Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ààlà tó wà ní eteetí ilẹ̀ náà, bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 47:​15-21.

      6 Kí lohun tí ìran nípa pínpín ilẹ̀ yìí wà fún? Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn ibi tí ààlà ilẹ̀ náà dé mú kó dá Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn lójú pé ilẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn máa pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Fojú inú wo bí ìdánilójú tí Jèhófà fún àwọn tó wà nígbèkùn ṣe máa rí lára wọn, ó dájú pé inú wọn máa dùn sí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Jèhófà ṣe lọ́nà tó ṣe kedere! Ṣé àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́ gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn pé kí wọ́n jogún lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n gbà á.

      Odò tó ṣàn lọ sínú òkun, ilẹ̀ tí wọ́n pín wà ní etí odò náà.

      7. (a) Àwọn nǹkan wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kí nìyẹn sì rán wa létí? (b) Ìbéèrè wo la máa kọ́kọ́ dáhùn?

      7 Lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wà nígbèkùn bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn ohun mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn yẹn rán wa létí pé irú ohun kan náà ti ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. Lọ́nà kan, àwọn náà gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Jèhófà jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ilẹ̀ tẹ̀mí kan, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Torí náà, Ilẹ̀ Ìlérí ayé àtijọ́ tó pa dà bọ̀ sípò kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí ilẹ̀ tẹ̀mí àwọn èèyàn Ọlọ́run òde òní ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Àmọ́ ká tó gbé àwọn ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèré yìí, “Kí nìdí tá a fi gbà pé ilẹ̀ tẹ̀mí kan wà lóde òní lóòótọ́?”

      8. (a) Orílẹ̀-èdè wo ni Jèhófà fi rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tara? (b) Kí ni ilẹ̀ tẹ̀mí tàbí párádísè tẹ̀mí túmọ̀ sí? (d) Ìgbà wo ló wáyé, àwọn wo ló sì ń gbé lórí ilẹ̀ náà?

      8 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí, Jèhófà jẹ́ kó rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Ísírẹ́lì ṣe máa pa dà bọ̀ sípò máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lẹ́yìn tí “Dáfídì ìránṣẹ́” rẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi, bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba. (Ìsík. 37:24) Ọdún 1914 Sànmánì Kristẹni ni èyí ṣẹlẹ̀. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tara tí wọ́n jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. (Ka Mátíù 21:43; 1 Pétérù 2:9.) Àmọ́, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí nìkan ni Jèhófà fi rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tara, ó tún fi ilẹ̀ tẹ̀mí tàbí párádísè tẹ̀mí rọ́pò ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. (Àìsá. 66:8) Bá a ṣe rí i ní Orí 17 ìwé yìí, ilẹ̀ tẹ̀mí yẹn ni àyíká tẹ̀mí tó ní ààbò tàbí ibi tá a ti ń gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, níbi tí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti ń sin Jèhófà látọdún 1919. (Wo àpótí 9B, “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919”) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tó nírètí láti gbé láyé, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn,” bẹ̀rẹ̀ sí í gbé orí ilẹ̀ tẹ̀mí yìí. (Jòh. 10:16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé párádísè tẹ̀mí ń tura sí i, ó sì ń gbèrú, ó di ẹ̀yìn Amágẹ́dọ́nì ká tó gbádùn ìbùkún ibẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

      Wọ́n Pín Ilẹ̀ Náà Lọ́gbọọgba, Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ

      9. Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà sọ nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà?

      9 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:​1, 28. Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ ibi tí ààlà ilẹ̀ náà lódindi máa dé, ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe pín in. Ó ní kí ogún tí wọ́n máa pín fún ẹ̀yà méjìlá (12) náà jẹ́ ọgbọọgba, kó sì jẹ́ láti àríwá sí gúúsù. Kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ pínpín náà látorí ẹ̀yà Dánì tó wà ní ìkángun àríwá ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì parí rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹ̀yà Gádì ní ìkángun ààlà gúúsù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ogún méjìlá (12) náà ló ní ilẹ̀ tó tẹ́jú pẹrẹsẹ, ó lọ láti ààlà ilẹ̀ náà tó wà ní ìlà oòrùn títí dé Òkun Ńlá tàbí Òkun Mẹditaréníà, ní ìwọ̀ oòrùn.​—Ìsík. 47:20.

      10. Kí ló wà nínú apá tá a gbé yẹ̀ wò nínú ìran yìí tó ṣeé ṣe kó fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?

      10 Ó ṣeé ṣe kí apá tá a jíròrò nínú ìran yìí fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀, lọ́nà wo? Ó dájú pé kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà máa mórí àwọn tó wà nígbèkùn wú gan-an, wọ́n á rí i pé ètò tó dáa ti wà lórí bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ náà. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe sọ ìpín tó máa kan ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà mú kó dá wọn lójú pé gbogbo àwọn tó dé láti ìgbèkùn ló máa gba ogún lórí ilẹ̀ tí wọ́n pa dà sí. Gbogbo wọn ló máa ní ilẹ̀ àti ilé tiwọn.

      Ọkùnrin tó ní ìrísí bàbà ń fi ilẹ̀ táwọn èèyàn Ọlọ́run máa jogún han Ìsíkíẹ́lì.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 20A: Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

      11. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìran tó sọ bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà? (Wo àpótí náà, “Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà.”)

      11 Ẹ̀kọ́ tó ń fúnni lókun wo la lè kọ́ látinú ìran yẹn lónìí? Kì í ṣe àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn olórí nìkan ló jadùn Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò, gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀yà méjìlá (12) ló jadùn rẹ̀. (Ìsík. 45:​4, 5, 7, 8) Bákan náà ló rí lónìí, kì í ṣe àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn tó ń múpò iwájú lára “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” nìkan ló ń jadùn párádísè tẹ̀mí, gbogbo àwọn tó wà nínú ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ń jadùn rẹ̀.a (Ìfi. 7:9) Kò sí bí ipa tá à ń kó nínú ètò Ọlọ́run ṣe rẹlẹ̀ tó, àyè wà fún wa lórí ilẹ̀ tẹ̀mí náà, iṣẹ́ tó ṣeyebíye sì wà fún wa láti ṣe. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

      Àwòrán: 1. Arábìnrin kan ń bá ìyà rẹ̀ tó ti darúgbó wo oògùn tó máa lò. 2. Míṣọ́nnárì kan ń kọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan bó ṣe máa wàásù lóde ẹ̀rí. Wọ́n jọ ń wàásù ní etíkun. 3. Òbí anìkàntọ́mọ kan ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. 4. Arákùnrin Gerrit Lösch ń darí ìjọsìn òwúrọ̀ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì. 5. Arábìnrin àgbàlagbà kan ń gbàdúrà. Bíbélì kan wà lórí itan rẹ̀ àti orúkọ àwọn ará tó wà lẹ́wọ̀n. 6. Arákùnrin kan ń tún ilé ìtura ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. 7. Arákùnrin kan ń darí ọkọ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. 8. Àwọn arákùnrin tó ń gbohùn sílẹ̀ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè.

      Ohun yòówù kó jẹ́ ojúṣe wa nínú ètò Ọlọ́run, Jèhófà mọyì ìsapá wa (Wo ìpínrọ̀ 11)

      Báwo Ni Ìlànà Méjì Tó Yàtọ̀ Síra Ṣe Kàn Wá?

      12, 13. Ìtọ́ni tó ṣe pàtó wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì?

      12 Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára ohun tí Jèhófà sọ nípa bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ náà rú Ìsíkíẹ́lì lójú, torí wọ́n yàtọ̀ sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kó ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára ìyàtọ̀ yẹn. Ọ̀kan jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀; èkejì sì ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa gbé ibẹ̀.

      13 Àkọ́kọ́, ilẹ̀ náà. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kí ilẹ̀ tó máa pín fún àwọn ẹ̀yà tó tóbi pọ̀ ju èyí tó máa pín fún àwọn ẹ̀yà tí kò tóbi. (Nọ́ń. 26:​52-54) Àmọ́, nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà ní kí wọ́n pín ilẹ̀ fún gbogbo ẹ̀yà, kí “ìpín kálukú . . . sì dọ́gba [“kálukú bí arákùnrin rẹ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀].” (Ìsík. 47:14) Torí náà, nínú gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) tí wọ́n pín ogún fún, kò sí ẹni tí ogún tiẹ̀ kéré sí tẹni kejì, ọgbọọgba ni, láti ààlà tó wà ní àríwá títí dé ààlà tó wà ní gúúsù. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì pátá, láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí, gbogbo wọn ló jọ máa nípìn-ín nínú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tó ń jáde láti Ilẹ̀ Ìlérí tó jẹ́ ilẹ̀ tó lómi dáadáa.

      14. Báwo lohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn àjèjì ṣe yàtọ̀ sí ohun tó sọ nínú Òfin Mósè?

      14 Èkejì, àwọn tó máa gbé ibẹ̀. Òfin Mósè dáàbò bo àwọn àjèjì, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, àmọ́ wọn ò pín ilẹ̀ fún wọn. (Léf. 19:​33, 34) Àmọ́, ohun tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀ sí ohun tó sọ nínú Òfin Mósè. Jèhófà sọ fún un pé: “Agbègbè tó jẹ́ ti ẹ̀yà tí àjèjì náà ń gbé ni kí ẹ ti fún un ní ogún.” Jèhófà lo àṣẹ yìí láti fòpin sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín “ọmọ Ísírẹ́lì” àti àjèjì tó ń gbé ilẹ̀ náà. (Ìsík. 47:​22, 23) Nínú ilẹ̀ tó pa dà bọ̀ sípò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó rí i pé ọgbọọgba làwọn ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì ń jọ́sìn níṣọ̀kan.​—Léf. 25:23.

      15. Òtítọ́ pàtàkì wo nípa Jèhófà ni ìtọ́sọ́nà nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀ jẹ́ ká mọ̀?

      15 Ó dájú pé àwọn ìtọ́sọ́nà pàtàkì méjì tí Ìsíkíẹ́lì gbà nípa ilẹ̀ náà àti àwọn tó máa gbé ibẹ̀ máa fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ gan-an. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa pín ilẹ̀ fún wọn lọ́gbọọgba, bóyá ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n, àbí àjèjì tó ń sin Jèhófà. (Ẹ́sírà 8:20; Neh. 3:26; 7:​6, 25; Àìsá. 56:​3, 8) Àwọn ìtọ́sọ́nà yìí tún jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà pé, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló ṣeyebíye lójú rẹ̀ bákan náà. (Ka Hágáì 2:7.) Lóde òní, a mọyì òtítọ́ kan náà yẹn, bóyá ìrètí láti gbé lọ́run la ní o, àbí ti orí ilẹ̀ ayé.

      16, 17. (a) Àǹfààní wo la rí nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò ní orí tó tẹ̀ lé e?

      16 Àǹfààní wo la rí nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀? Ohun tá a kọ́ ti rán wa létí pé ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará wa ṣe pàtàkì gan-an lóde òní àti pé a gbọ́dọ̀ máa fi hàn kedere pé kò sí ojúsàájú nínú ètò Ọlọ́run. Jèhófà kì í ṣojúsàájú. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà kì í ṣe ojúsàájú bíi ti Jèhófà? Ṣé mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, láìka ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà sí tàbí ipò tí wọ́n bá ara wọn nígbèésí ayé?’ (Róòmù 12:10) Inú wa dùn pé Jèhófà fún gbogbo wa ní àǹfààní kan náà láti máa gbádùn párádísè tẹ̀mí, ibẹ̀ la ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá sí Baba wa ọ̀run, tá a sì ń gbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀.​—Gál. 3:​26-29; Ìfi. 7:9.

      Àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ọjọ́ orí wọn sì yàtọ̀ síra ń ṣe ìjọsìn ìdílé lọ́dọ̀ arábìnrin kan tó jẹ́ aláàbọ̀ ara.

      Ṣé a máa ń fara wé Jèhófà tí kì í ṣojúsàájú, tó sì máa ń buyì fúnni? (Wo ìpínrọ̀ 15 àti 16)

      17 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ohun kẹrin tí Jèhófà mú kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú, ní apá tó parí ìran tó rí kẹ́yìn, ìyẹn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa wà pẹ̀lú àwọn tó wà nígbèkùn. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìlérí náà? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí ní orí tó tẹ̀ lé e.

      a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àyè àti iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ìjòyè ní ilẹ̀ tẹ̀mí, wo Orí 14 ìwé yìí.

      BÍ ÌJỌSÌN MÍMỌ́ ṢE KÀN Ẹ́

      1. Kí ló jẹ́ kó o gbà pé párádísè tẹ̀mí wà lóde òní?

      2. Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àyè wà fún ẹ àti pé o ní iṣẹ́ tó ṣeyebíye láti ṣe nínú párádísè tẹ̀mí?

      3. Kí ni ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

  • “Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • Àwòrán ìlú tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Jèhófà Wà Níbẹ̀.’

      ORÍ 21

      “Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”

      ÌSÍKÍẸ́LÌ 48:35

      OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tí ìlú náà àti ọrẹ túmọ̀ sí

      1, 2. (a) Apá wo ni wọ́n máa yà sọ́tọ̀ lákànṣe ní ilẹ̀ náà? (Wo àwòrán tó wà lára èèpo ìwé yìí.) (b) Ọ̀nà wo ni ìran yìí gbà fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?

      NÍNÚ ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí kẹ́yìn, ó rí apá kan ilẹ̀ náà tí wọ́n máa yà sọ́tọ̀ lákànṣe. Wọn ò ní pín ibẹ̀ fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì kankan, àmọ́ wọ́n máa yà á sọ́tọ̀, ó sì máa jẹ́ ọrẹ fún Jèhófà. Ìsíkíẹ́lì tún rí ìlú kan tó gbàfiyèsí tí orúkọ rẹ̀ sì ṣàrà ọ̀tọ̀. Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí ló ṣe pàtàkì jù nínú ohun tó ń fi àwọn tó wà nígbèkùn náà lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn sì ni pé: Jèhófà máa wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n bá pa dà sí ìlù ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.

      2 Ìsíkíẹ́lì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ọrẹ náà ṣe rí. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó sọ, torí pé ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ló ní fún àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́.

      Àwòrán ilẹ̀ tí wọ́n pè ní ‘ọrẹ’ àti ìlú tí wọ́n pè ní ‘Jèhófà Wà Níbẹ̀.’ Tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí lójú ìran ń tàn yanran, ògo Jèhófà sì wà lorí òkè gíga náà níbi tí odò ti ń ṣàn wá.

      “Ilẹ̀ Mímọ́ Pẹ̀lú . . . Ìlú Náà”

      Àwòrán ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀, èyí tí wọ́n pè ní ‘ọrẹ’ àti àpótí tó jẹ́ ká rí ‘gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ.’

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 21A: “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ.”

      3. Apá márùn-ún wo ni ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ pín sí? Kí sì ni apá kọ̀ọ̀kan wà fún? (Wo àpótí náà, “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ.”)

      3 Ilẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ (kìlómítà 13) láti àríwá sí gúúsù, ó sì tún jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Ilẹ̀ náà dọ́gba lẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Bíbélì sì pè é ní “Gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ.” Wọ́n pín in sí ọ̀nà mẹ́ta ní ìbú. Ibi tó wà lápá òkè jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì, wọ́n sì ya ibi tó wà ní àárín sọ́tọ̀ fún tẹ́ńpìlì àtàwọn àlùfáà. Apá méjèèjì yẹn ló para pọ̀ jẹ́ “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́.” Apá kékeré tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ tàbí “ibi tó ṣẹ́ kù,” jẹ́ ti “gbogbo ìlú.” Ó wà fún ìlú náà.​—Ìsík. 48:​15, 20.

      4. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà?

      4 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àkọsílẹ̀ nípa ọrẹ sí Jèhófà? Bó ṣe jẹ́ pé ilẹ̀ tó jẹ́ ọrẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n kọ́kọ́ yà sọ́tọ̀, tí wọ́n sì wá pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà lẹ́yìn náà, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ibi tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. (Ìsík. 45:1) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ làwọn tó wà nígbèkùn yìí kọ́ látinú bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ pínpín ilẹ̀ náà láti ibi tó ṣe pàtàkì jù. Ìjọsìn Jèhófà ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ láyé wọn. Bákan náà lónìí, àwọn nǹkan tẹ̀mí, irú bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wíwá sáwọn ìpàdé Kristẹni àti kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù la kà sí pàtàkì jù. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe fi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́, àá lè máa fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo lójoojúmọ́ ayé wa.

      “Ìlú Náà Yóò Wà ní Àárín Rẹ̀”

      5, 6. (a) Àwọn wo ni ìlú náà wà fún? (b) Kí ni ìlú náà kò jẹ́, kí sì nìdí?

      5 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:15. Kí ni “ìlú náà” àti ilẹ̀ tó yí i ká wà fún? (Ìsík. 48:​16-18) Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì nínú ìran pé: Ìlú náà “yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” (Ìsík. 45:​6, 7) Torí náà, ìlú náà àti ilẹ̀ tó yí i ká kò sí lára “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́” tí wọ́n máa “yà sọ́tọ̀ . . . fún Jèhófà.” (Ìsík. 48:9) Ẹ jẹ́ ká fi ìyàtọ̀ yìí sọ́kàn, ká wá jọ wo ohun tá a rí kọ́ lóde òní nínú ètò tí wọ́n ṣe nípa ìlú náà.

      6 Ká tó lè mọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú ìlú náà, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí ìlú náà kò jẹ́. Ìlú náà kì í ṣe ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tí wọ́n tún kọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò sí tẹ́ńpìlì nínú ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yẹn. Bákan náà, ìlú náà kì í ṣe ìlú èyíkéyìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ìgbèkùn tó pa dà náà tàbí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ò fìgbà kankan kọ́ ìlú èyíkéyìí tó ní àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ìlú náà kì í ṣe ìlú tó wà ní ọ̀run. Kí nìdí? Torí pé orí ilẹ̀ “tó jẹ́ ti gbogbo èèyàn [tàbí tí kì í ṣe ilẹ̀ mímọ́]” ni wọ́n kọ́ ọ sí, ìyẹn sì yàtọ̀ sí ilé tí wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ tí wọ́n dìídì yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn mímọ́.​—Ìsík. 42:20.

      7. Kí ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà? Kí ló ṣeé ṣe kí ìlú náà ṣàpẹẹrẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

      7 Kí wá ni ìlú tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran náà? Ẹ má gbàgbé pé inú ìran tó ti rí ilẹ̀ náà ló ti rí ìlú yẹn. (Ìsík. 40:2; 45:​1, 6) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ilẹ̀ tẹ̀mí ni ilẹ̀ náà, torí náà ìlú náà ní láti jẹ́ ìlú tẹ̀mí. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá pe ibì kan ní “ìlú”? Ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ibi tí àwọn èèyàn jọ ń gbé, tí wọ́n ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan àti ètò tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Torí náà, ìlú tó wà létòlétò tí Ìsíkíẹ́lì rí, tí ààlà rẹ̀ dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ṣeé ṣe kó ṣàpẹẹrẹ ibùjókòó ìjọba kan tó wà létòlétò.

      Àwòrán ìlú tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Jèhófà Wà Níbẹ̀.’

      8. Ibo ni ìjọba yìí ń ṣàkóso lé lórí tàbí tó nasẹ̀ dé, kí sì nìdí?

      8 Ibo ni ìjọba yìí ń ṣàkóso lé lórí tàbí tó nasẹ̀ dé? Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé àwọn ohun tó ń wáyé ní ìlú náà ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ tẹ̀mí. Ìyẹn fi hàn pé, lóde òní, àárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ni ìjọba náà ti ń ṣàkóso. Kí ló wá túmọ̀ sí nígbà tí wọ́n sọ pé ilẹ̀ náà jẹ́ ti gbogbo èèyàn tàbí pé kì í ṣe ilẹ̀ mímọ́? Ìyẹn rán wa létí pé kì í ṣe ìjọba tó wà ní ọ̀run ni ìlú náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó ń tọ́ka sí ètò ìjọba tó wà lórí ilẹ̀ ayé, èyí tí gbogbo àwọn tó wà nínú párádísè tẹ̀mí ń jàǹfààní rẹ̀.

      9. (a) Àwọn wo ni alákòóso nínú ètò ìjọba orí ilẹ̀ ayé yẹn lóde òní? (b) Kí ni Jésù máa ṣe nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀?

      9 Àwọn wo ni alákòóso nínú ètò ìjọba orí ilẹ̀ ayé yẹn? Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ó pe ẹni tó ń múpò iwájú nínú ìjọba ìlú náà ní “ìjòyè.” (Ìsík. 45:7) Ìjòyè náà ń ṣe àbójútó àwọn èèyàn, àmọ́ kì í ṣe àlùfáà, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọmọ Léfì. Ìjòyè yìí rán wa létí àwọn alábòójútó ìjọ Ọlọ́run lóde òní tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí ń fìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ ara àwọn “àgùntàn mìíràn,” wọ́n sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ojúṣe wọn lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìjọba Kristi tó wà lọ́run. (Jòh. 10:16) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa yan àwọn alàgbà tàbí àwọn “olórí” tó kúnjú ìwọ̀n sípò “ní gbogbo ayé.” (Sm. 45:16) Ìjọba Ọlọ́run tó wà lọ́run máa darí wọn láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà.

      “Jèhófà Wà Níbẹ̀”

      10. Kí ni orúkọ ìlú náà? Kí nìyẹn mú kó dá wọn lójú?

      10 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:35. Orúkọ ìlú náà ni “Jèhófà Wà Níbẹ̀.” Orúkọ yìí mú kó dá wọn lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú náà. Bí Jèhófà ṣe fi ìlú tó wà ní àárín gbùngbùn yìí han Ìsíkíẹ́lì, ó ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fún àwọn tó wà nígbèkùn yẹn pé: ‘Màá tún wà pẹ̀lú yín lọ́tẹ̀ yìí!’ Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an!

      11. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìlú náà àti ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀?

      11 Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ yìí? Orúkọ ìlú tá a mẹ́nu bà yìí fi dá àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú lóde òní pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé báyìí, kò sì ní fi wá sílẹ̀ nígbà kankan. Orúkọ tó nítumọ̀ yìí tún tẹnu mọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan: Kì í ṣe láti fún ẹnikẹ́ni lágbára ni ìlú náà ṣe wà, àmọ́ láti mú káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tó bọ́gbọ́n mu, tó sì fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ò fún àwọn tó ń ṣàkóso ìlú náà láṣẹ láti pín ilẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ náà, bó ṣe lè dà bíi pé ó tọ́ lójú àwa èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà retí pé kí àwọn alákòóso yẹn tẹ̀ lé ètò pínpín ilẹ̀ náà, tàbí àǹfààní tí òun fún àwọn ìránṣẹ́ òun, títí kan àwọn “aláìní.”​—Òwe 19:17; Ìsík. 46:18; 48:29.

      12. (a) Nǹkan pàtàkì míì wo ló tún wà ní ìlú náà? Kí nìyẹn fi hàn? (b) Ohun pàtàkì wo lèyí ń rán àwọn Kristẹni alábòójútó létí?

      12 Nǹkan pàtàkì míì wo ló tún wà ní ìlú tá a pe orúkọ rẹ̀ ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀”? Wọ́n sábà máa ń mọ odi yí àwọn ìlú àtijọ́ ká, ẹnubodè wọn kì í sì í pọ̀ rárá, àmọ́ ní ti ìlú tá à ń sọ yìí, ẹnubodè méjìlá (12) ló ní! (Ìsík. 48:​30-34) Bí àwọn ẹnubodè ìlú náà ṣe pọ̀ dáadáa (ẹnubodè mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ògiri mẹ́rin tó yí ìlú náà ká) fi hàn pé àwọn alákòóso ìlú náà ṣeé sún mọ́, wọ́n sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnubodè méjìlá (12) náà tún jẹ́ kó ṣe kedere pé ó wà fún gbogbo èèyàn, ìyẹn “gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” (Ìsík. 45:6) Bí ìlú náà ṣe ní ẹnubodè tó pọ̀ fún àwọn èèyàn ń rán àwọn Kristẹni alábòójútó létí ohun pàtàkì kan. Jèhófà fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo àwọn tó ń gbé inú párádísè tẹ̀mí.

      Alàgbà kan ń bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó ń wo àwòrán tí wọ́n yà.

      Àwọn Kristẹni alábòójútó jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, wọ́n sì máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó (Wo ìpínrọ̀ 12)

      Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń “Wọlé Láti Jọ́sìn,” Wọ́n sì “Ń Ṣiṣẹ́ Nínú Ìlú Náà”

      13. Kí ni Jèhófà sọ nípa oríṣiríṣi iṣẹ́ tí àwọn èèyàn á máa ṣe?

      13 Ẹ jẹ́ ká pa dà sígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, ká sì wo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì tó kọ sínú ìran tó gbòòrò tó sọ nípa pínpín ilẹ̀ náà. Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ìsìn. Àwọn àlùfáà, ìyẹn “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́,” láá máa rúbọ, tí wọ́n á sì máa wá síwájú Jèhófà láti ṣiṣẹ́ fún un. Àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì,” ni wọ́n á “máa bójú tó ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú rẹ̀.” (Ìsík. 44:​14-16; 45:​4, 5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òṣìṣẹ́ á máa jára mọ́ṣẹ́ nítòsí ìlú náà. Àwọn wo làwọn òṣìṣẹ́ yìí?

      14. Kí ni àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní tòsí ìlú náà rán wa létí rẹ̀?

      14 Inú “gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì” ni àwọn òṣìṣẹ́ náà ti wá. Iṣẹ́ ìtìlẹ́yìn ni wọ́n ń ṣe. Ojúṣe wọn ni pé kí wọ́n dá oko tí wọ́n á fi máa pèsè oúnjẹ fún “àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ìlú náà.” (Ìsík. 48:​18, 19) Ǹjẹ́ ètò yìí rán wa létí àǹfààní kan tá a ní lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni. Lóde òní gbogbo àwọn tó wà nínú párádísè tẹ̀mí ló láǹfààní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn àti àwọn tí Jèhófà yàn láti máa múpò iwájú lára àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn.” (Ìfi. 7:​9, 10) Ọ̀nà pàtàkì kan tá à ń gbà tì wọ́n lẹ́yìn ni bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹrú olóòótọ́ náà tinútinú.

      15, 16. (a) Kúlẹ̀kúlẹ̀ míì wo ló tún wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (b) Kí la láǹfààní láti máa ṣe tó jọ tinú ìran yẹn?

      15 Kúlẹ̀kúlẹ̀ míì tún wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí tó lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan nípa iṣẹ́ ìsìn wa. Kí nìyẹn ná? Jèhófà sọ pé àwọn tó wà lára ẹ̀yà méjìlá (12) tí wọn kì í ṣe ọmọ Léfì máa wà lẹ́nu iṣẹ́ níbi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì àti níbi ìjẹko ìlú náà. Kí ni wọ́n á máa ṣe láwọn ibẹ̀ yẹn? Gbogbo ẹ̀yà máa ń “wọlé láti jọ́sìn” nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì, wọ́n máa ń rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀. (Ìsík. 46:​9, 24) Àwọn tó wà nínú gbogbo ẹ̀yà máa ń dáko lórí ilẹ̀ náà láti ṣètìlẹ́yìn fún ìlú náà. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn òṣìṣẹ́ yìí?

      16 Lóde òní, àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ èèyàn láǹfààní láti máa ṣe àwọn ohun tó jọ ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà “nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀” nípasẹ̀ ẹbọ ìyìn tí wọ́n ń rú. (Ìfi. 7:​9-15) Ìyẹn bí wọ́n ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti bí wọ́n ṣe ń sọ ìgbàgbọ́ wọn jáde láwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n gbà pé èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú ojúṣe àwọn ni pé káwọn máa sin Jèhófà ní tààràtà. (1 Kíró. 16:29) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣètìlẹ́yìn fún ètò Ọlọ́run ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé àti àbójútó àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ẹ̀ka ọ́fíìsì àti lẹ́nu àwọn iṣẹ́ míì tí ètò Jèhófà ń ṣe. Àwọn míì ń fi owó wọn ṣètìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ náà. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń dáko lórí ilẹ̀ náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, “fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Wọ́n ń fìtara ṣe iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ń ṣe é tayọ̀tayọ̀, torí wọ́n mọ̀ pé “inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.” (Héb. 13:16) Ṣé ìwọ náà kì í jẹ́ kí irú àwọn àǹfààní yìí bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?

      Àwọn èèyàn gbé ọkà dání, wọ́n ń bójú tó àwọn màlúù àti àgùntàn níbi ẹnubodè ìlú tí wọ́n pè ní ‘Jèhófà Wà Níbẹ̀.’

      Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àlàyé tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa oríṣiríṣi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú àti láyìíká àwọn ẹnubodè ìlú náà (Wo ìpínrọ̀ 14-16)

      “À Ń Retí Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun”

      17. (a) Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú? (b) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn wo ló máa jàǹfààní àkóso ibi tó dà bí ìlú náà?

      17 Ǹjẹ́ a máa rí bí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ọrẹ ṣe máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú? Bẹ́ẹ̀ ni! Wo àpẹẹrẹ yìí: Ìsíkíẹ́lì rí i pé àárín ilẹ̀ náà ni ibi tí wọ́n pè ní “ilẹ̀ [tàbí ọrẹ] mímọ́” wà. (Ìsík. 48:10) Lọ́nà kan náà, ibi yòówù ká máa gbé ní ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà á máa bá wa gbé. (Ìfi. 21:3) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà, ìyẹn àwọn tá a máa yàn sípò ní ayé láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run, máa nasẹ̀ àbójútó wọn dé ibi gbogbo láyé ní ti pé wọ́n á máa fìfẹ́ darí gbogbo àwọn tó máa wà nínú “ayé tuntun,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tuntun, wọ́n á sì máa tọ́ wọn sọ́nà.​—2 Pét. 3:13.

      18. (a) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà máa ṣàkóso lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́? (b) Kí ni orúkọ ìlú náà mú kó dá wa lójú?

      18 Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn alákòóso tó ń bójú tó ibi tó dà bí ìlú náà á máa ṣàkóso lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́? Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó ṣe kedere pé ìlú tó ní ẹnubodè méjìlá (12) ní ayé yẹn ń rán wa létí Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìlú tó ní ẹnubodè méjìlá (12) ní ọ̀run, ìyẹn Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n jọ máa ṣàkóso. (Ìfi. 21:​2, 12, 21-27) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ìpinnu tí àwọn alákòóso ìjọba náà bá ń ṣe láyé á máa bá ti Ìjọba Ọlọ́run mu ní ọ̀run, wọ́n á sì máa fara balẹ̀ tẹ̀ lé e. Àní sẹ́, orúkọ ìlú tí wọ́n pè ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀” fi dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú pé ìjọsìn mímọ́ á máa wà nìṣó, á sì máa gbèrú títí láé nínú Párádísè. Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú ológo ló ń dúró dè wá!

      BÍ ÌJỌSÌN MÍMỌ́ ṢE KÀN Ẹ́

      1. Kí ni ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ nípa fífi ohun tó yẹ sípò àkọ́kọ́ látinú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa ọrẹ sí Jèhófà?

      2. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣètìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ tí ẹrú olóòótọ́ ń ṣe?

      3. Èwo lo kà sí pàtàkì jù nínú àwọn ojúṣe tó o ní?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́