ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w10 5/1 ojú ìwé 3
  • Ibo Ni Ọlọ́run Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Ni Ọlọ́run Wà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2003
  • Kí Ló Ń Fa Ìṣòro Àìrílégbé?
    Jí!—2005
  • Àjálù Ojoojúmọ́ Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù?
    Jí!—2005
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
w10 5/1 ojú ìwé 3

Ibo Ni Ọlọ́run Wà?

September 11, 2001: Ní aago mẹ́sàn-án ku ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá àárọ̀, ọkọ̀ òfuurufú akérò kan kọ lu ilé gogoro, ìyẹn Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé tó wà ní ìlú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èyí ni àkọ́kọ́ lára ìgbéjàkoni tí àwọn aṣekúpani fi ṣọṣẹ́ níbẹ̀. Lẹ́yìn wákàtí kan ó lé ìṣẹ́jú méjìlélógójì, ẹ̀mí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ti ṣòfò.

December 26, 2004

Ìsẹ̀lẹ̀ alágbára kan, ìyẹn ilẹ̀ ríri tó wáyé nínú Òkun Íńdíà fa ìgbì omi aṣekúpani, èyí tó mú kí omi ya lu orílẹ̀-èdè mọ́kànlá, tó fi mọ́ ilẹ̀ Áfíríkà tó fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún kìlómítà jìnnà síbẹ̀. Ìsẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ìwọ̀n 9.0 lórí òṣùwọ̀n Richter. Láàárín ọjọ́ kan péré, àròpọ̀ iye àwọn èèyàn tó kú tàbí tí wọ́n sọ nù jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000], tí àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan sì di aláìnílé lórí.

August 1, 2009: Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógójì àti ọmọkùnrin rẹ̀ ọmọ ọdún márùn-ún ń sáré orí yìnyín, ni wọ́n bá lọ ta lu ibi ìgbọ́kọ̀sí kan. Bàbá náà kú. Ọmọ rẹ̀ kò kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ó kú lọ́jọ́ kejì. Àwọn ẹbí wọn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò sọ pé: “A rò pé iṣẹ́ ìyanu kan máa ṣẹlẹ̀ ni, tá á sì yè é.”

Nígbà tó o bá kà nípa àwọn aṣekúpani tàbí àwọn àjálù lóríṣiríṣi tàbí kẹ̀, nígbà tí àjálù bá bá ìwọ alára, ǹjẹ́ o máa ń béèrè pé, ṣé Ọlọ́run ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Ǹjẹ́ o máa ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run ti pa wá tì? Bíbélì fúnni ní ìdáhùn tó ń tuni nínú, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

© Àwọn fọ́tò tí Dieter Telemans/Panos yà

Àwọn fọ́tò tí PRAKASH SINGH/AFP/Getty yà

© Àwọn fọ́tò tí Dieter Telemans/Panos yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́