Ǹjẹ́ O Rántí?
Ṣó o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé irun Sámúsìnì ló mú kó lágbára?
Kì í ṣe irun Sámúsìnì gan-an ló mú kó ní agbára. Irun rẹ̀ dúró fún àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ Násírì. Nígbà tí Dẹ̀lílà gé irun orí Sámúsìnì, èyí ṣe àkóbá fún àjọṣe yẹn.—4/15, ojú ìwé 9.
Ní ìfiwéra pẹ̀lú ọkàn wa, àwọn ohun mẹ́ta wo ló máa jẹ́ kí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa?
(1) Oúnjẹ. Bí ọkàn wa ṣe nílò oúnjẹ aṣaralóore, bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ ní àjẹtẹ́rùn. (2) Eré Ìmárale. Tá a bá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí á mú kí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa. (3) Àwọn Tó Yí Wa Ká. A lè dín pákáǹleke kù tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa tí ọ̀rọ̀ wa jẹ lógún.—4/15, ojú ìwé 16.
Báwo ni tọkọtaya ṣe lè pa dà máa fọkàn tán ará wọn lẹ́yìn tí ọ̀kan nínú wọn bá ti hùwà àìṣòótọ́?
Wọ́n gbọ́dọ̀ máa (1) finú han ara wọn; (2) fọwọ́ sowọ́ pọ̀; (3) fi ìwà tuntun rọ́pò ògbólógbòó; kí wọ́n sì (4) mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n gbọ́kàn kúrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè wá bí wọ́n ṣe máa mú kí àjọṣe wọn sunwọ̀n sí i.—5/1, ojú ìwé 12 sí 15.
Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹni tó ń sọ àsọyé ìsìnkú lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 116:15 fún ẹni tó kú náà?
Ẹsẹ náà kà pé: “Iyebíye ní ojú Jèhófà ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” Èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ka ikú gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí àdánù ńlá tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé kò ní gbà kí irú rẹ̀ wáyé. Kò ní gbà kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lódindi pa run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.—5/15, ojú ìwé 22.
Àwọn wo ni àwọn apínwèé-ìsìn-kiri?
Ṣáájú ọdún 1931, “apínwèé-ìsìn-kiri” là ń pe àwọn tá a wá mọ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà ní báyìí.—5/15, ojú ìwé 31.
Kí ni díẹ̀ lára ohun tó fi hàn pé Bíbélì yàtọ̀ sí ìwé yòókù táwọn èèyàn kọ?
Ọ̀pọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ní ìmúṣẹ ló wà nínú Bíbélì. Òótọ́ ni àwọn ìtàn inú rẹ̀, kì í ṣe àlọ́. Ohun tó sọ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, gbogbo ìwé inú rẹ̀ sì wà ní ìṣọ̀kan. Ó wúlò fún wa lóde òní.—6/1, ojú ìwé 4 sí 8.
Àwọn wo ló para pọ̀ di àwọn “ìjọba wọ̀nyí” tí ìwé Dáníẹ́lì 2:44 sọ̀rọ̀ nípa wọn?
Ère tí Dáníẹ́lì ṣàlàyé rẹ̀ pín sí onírúurú apá. Àwọn ìjọba tí onírúurú apá yẹn ṣàpẹẹrẹ ló para pọ̀ di àwọn “ìjọba wọ̀nyí.”—6/15, ojú ìwé 17.
Ìgbà wo ni Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà di agbára ayé keje inú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì?
Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà di agbára ayé keje nígbà tí àwọn méjèèjì jọ gbé ohun pàtàkì ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní.—6/15, ojú ìwé 19.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tó sì máa ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wọn?
Jèhófà sọ nípa àwọn tó ṣe ojú rere sí pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.” (Jer. 31:34) Ó lè dárí jini lọ́la ẹbọ ìràpadà Kristi. Tí Ọlọ́run bá ti dárí jini, ó máa ń gbàgbé rẹ̀, ìyẹn ni pé kò ní máa ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà láti tún torí rẹ̀ jẹni níyà.—7/1, ojú ìwé 18.
Kí nìdí tá a fi lè gbà pé òótọ́ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì ròyìn rẹ̀?
Àwọn iṣẹ́ ìyanu náà sábà máa ń wáyé ní gbangba, kì í ṣe ní bòókẹ́lẹ́. Wọ́n kàn máa ń ṣẹlẹ̀ wẹ́rẹ́ ni láìsí àkànṣe ètò kankan. Ọlọ́run làwọn iṣẹ́ ìyanu náà fògo fún kì í ṣe èèyàn. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ló wáyé, àwọn tó ń ṣàtakò nígbà yẹn ò sì jiyàn pé òótọ́ ni wọ́n ṣẹlẹ̀. Ìdí nìyí tá a fi gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì ròyìn rẹ̀.—8/1, ojú ìwé 7 àti 8.