ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 7/1 ojú ìwé 3
  • Àjálù Gbòde Kan!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjálù Gbòde Kan!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ń Jẹ́ Ká Jìyà?
    Jí!—2004
  • Ṣé Ọlọ́run Ló Fa Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 7/1 ojú ìwé 3

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ NǸKAN BURÚKÚ FI Ń ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÈÈYÀN RERE?

Àjálù Gbòde Kan!

Ìlú Dhaka tó wà lórílẹ̀-èdè Bangladesh ni obìnrin ẹni ọdún márùndínlógójì [35] kan tó ń jẹ́ Smitaa ń gbé. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an nítorí pé onínúure ni, ó kóòyàn mọra, ó sì láájò àwọn èèyàn. Obìnrin rere ni lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, ó sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ṣàdédé ni Smita bẹ̀rẹ̀ àìsàn, ọ̀sẹ̀ yẹn ò sì kolẹ̀ tó fi gbẹ́mìí mì! Nígbà tí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbọ́, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an.

Bíi ti Smita, èèyàn dáadáa làwọn èèyàn mọ James àti ìyàwó rẹ̀ sí. Àwọn méjèèjì ti lé díẹ̀ ní ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún. Wọ́n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ń gbé létíkun Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Orí ìrìn àjò yẹn ni wọ́n wà tí wọ́n ti ṣe kòńgẹ́ ìjàǹbá ọkọ̀ tó burú jáì, bí wọn ò ṣe pa dà délé mọ́ nìyẹn. Àwọn olólùfẹ́ àti alábàáṣiṣẹ́ wọn kò lè gbàgbé oró tí ikú yìí dá wọn.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ibi gbogbo ni ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ti ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bí ogun ṣe ń pa sójà ló ń pa aráàlú. Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá ń fojú àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ rí màbo. Ìjàǹbá àti àìsàn onírúurú kò mọ ọmọdé bẹ́ẹ̀ ni kò mọ àgbà tàbí ipò téèyàn wà láwùjọ. Àwọn àjálù gbankọgbì ń runlé rùnnà. Ẹ̀tanú àti ìwà ìrẹ́jẹ sì gbòde kan. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti fara gbá ọ̀kan lára àwọn nǹkan yìí.

O lè wá máa bi ara rẹ pé:

  • Kí nìdí tí aburú fi ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rere?

  • Ṣé ẹ̀bi Ọlọ́run ni gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ yìí?

  • Ṣé àfọwọ́fà àwa èèyàn ni àbí wọ́n kàn ń ṣàdédé ṣẹlẹ̀?

  • Ṣé òfin Kámà, ìyẹn òfin àṣesílẹ̀-làbọ̀wábá táwọn èèyàn sọ pé ó ní í ṣe pẹ̀lú àkọ́wáyé ló fa àwọn ìṣòro tó ń bá wa fínra lónìí?

  • Tó bá jẹ́ lóòótọ́ ni Olódùmarè wà, kí nìdí tí kì í fi gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ewu?

  • Ǹjẹ́ ìwà ibi àti ìyà máa dópin?

Tá a bá fẹ́ rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ohun méjì kan wà tó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀. A gbọ́dọ̀ mọ ìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀, àti ohun tí Ọlọ́run máa ṣe sí i.

a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́