KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÌJỌBA TÓ MÁA FÒPIN SÍ ÌWÀ ÌBÀJẸ́
Ìwà Ìbàjẹ́ Inú Ìjọba Èèyàn
Ìwà ìbàjẹ́ nínú ìjọba ni kí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ máa lo agbára tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti máa fi wá èrè sí àpò ara rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, òfin kan wà nínú Bíbélì tó sọ pé àwọn adájọ́ kò gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Èyí fi hàn pé ìwà ìbàjẹ́ yìí ti wà láti ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. (Ẹ́kísódù 23:8) Àmọ́, ìwà ìbàjẹ́ ju kéèyàn máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún kan bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba míì ṣe máa ń jí ẹrù ìjọba kó, tí wọ́n máa ń fi ipò wọn gba òun tí kò tọ́ sí wọn tàbí kí wọ́n kówó tó jẹ́ ti gbogbo aráàlú jẹ. Wọ́n tún máa ń lo agbára wọn láti fi àwọn èèyàn wọn sípò ńlá.
Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tí ìwà ìbàjẹ́ ò sí, àmọ́ ó dà bíi pé ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ìwé 2013 Global Corruption Barometer tí àjọ Transparency International tẹ̀ jáde sọ pé, ibi márùn-ún tí àwọn èèyàn gbà pé ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ sí jù ni àárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn ọlọ́pàá, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn aṣòfin àti ní ilé ẹjọ́. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìròyìn tó ṣàlàyé ìṣòro yìí.
ÁFÍRÍKÀ: Lọ́dún 2013, wọ́n fẹ̀sùn kan nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] òṣìṣẹ́ ìjọba ní orílẹ̀-èdè South Africa nítorí ìwà jẹgúdújẹrá.
GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ: Lọ́dún 2012, lórílẹ̀-èdè Brazil, èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ló jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n fi owó ìlú ra ìbò. Lára àwọn wọ̀nyí ni ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀gá àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba, òun sì lẹni tó ṣìkejì lẹ́yìn ààrẹ ìlú.
ÉṢÍÀ: Nílùú Seoul lórílẹ̀-èdè South Korea, èèyàn méjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [502] ló kú nígbà tí ilé ìtajà kan wó lọ́dún 1995. Ìwádìí fi hàn pé àwọn kọngílá tó gba iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ẹ̀gúnjẹ kí wọ́n lè lo ayédèrú kọnkéré kí ẹnikẹ́ni má sì yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò.
YÚRÓÒPÙ: Cecilia Malmström tó jẹ́ Kọmíṣọ́nnà tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ abẹ́lé fún Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Ibi tí ọ̀rọ̀ ìwà ìbàjẹ́ nílẹ̀ wa dé lónìí kọjá sísọ, àwọn olóṣèlú ò sì ṣe tán láti wá nǹkan ṣe sí i.”
Ìwà ìbàjẹ́ tí ìjọba ń hù ti kọjá ohun tẹ́nì kan lè tún ṣe. Ọ̀jọ̀gbọ́n Susan Rose-Ackerman, tó jẹ́ ògbóǹtarìgì nínú ìmọ̀ béèyàn ṣe lè gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ sọ pé: “Kí ìwà ìbàjẹ́ tó lè dópin, àtúnṣe gbọ́dọ̀ wáyé nínú bí àwa èèyàn ṣe ń ṣe ìjọba.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn fi hàn pé nǹkan ti bà jẹ́ jìnnà, síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà ìbàjẹ́ máa tó dópin.