KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Lóye Bíbélì?
“Bíbélì gbayì gan-an nínú àwọn ìwé ìsìn. Àmọ́ ìwé àjèjì ni, kò sì wúlò fún àwa ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà.”—LIN, ṢÁÍNÀ.
“Mi ò lóye ohun tó wà nínú ìwé ìsìn Híńdù tí mò ń ṣe. Báwo ni màá ṣe wá lóye Bíbélì?”—AMIT, INDIA.
“Mo gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì, torí ó lọ́jọ́ lórí, ó sì ń tà gan-an. Àmọ́, mi ò ríkan rí.”—YUMIKO, JAPAN.
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì. Síbẹ̀, wọn ò mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ tàbí kó jẹ́ díẹ̀ ni ohun tí wọ́n mọ̀ níbẹ̀. Ìṣòro yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà, ó sì tún wà láwọn àgbègbè tí Bíbélì pọ̀ sí pàápàá.
O lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tó fi yẹ kí n lóye Bíbélì?’ Tó o bá lóye ohun tó wà nínú Bíbélì:
Wàá ní ìtẹ́lọ́rùn, wàá sì láyọ̀
Wàá lè kojú àwọn ìṣòro ìdílé
Wàá lè gbé àwọn àníyàn ìgbésí ayé kúrò lọ́kàn
Àárín ìwọ àtàwọn èèyàn máa túbọ̀ gún
Wàá mọ bí èèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná
Wo àpẹẹrẹ Yoshiko tó ń gbé ní Japan. Ó ti máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó wà nínú Bíbélì, ló bá pinnu láti kà á. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó sọ pé: “Bíbélì ti jẹ́ káyé mi nítumọ̀, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.” Ó wá fí kún un pé: “Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀.” Amit tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá sọ pé: “Ohun tí mo bá nínú rẹ̀ yà mí lẹ́nu. Mo rí i pé àwọn nǹkan tó máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní ló wà nínú Bíbélì.”
Bíbélì ti tún ayé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ṣe kárí ayé. Ìwọ náà lè yẹ̀ ẹ́ wò, kó o sì rí bó ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní.