Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tá Ò Tíì Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
1. Ṣé gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà tá a bá kọ́kọ́ pàdé wọn? Ṣàlàyé.
1 Kí ẹnì kan tó lè máa jọ́sìn Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àmọ́, àwọn kan kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni látilẹ̀, wọn ò sì gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Àwọn míì ò tiẹ̀ gbà pé Ọlọ́run wà, torí náà wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì. Àwọn ìtẹ̀jáde wo làwọn kan ti lò láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí kò kọ́kọ́ fẹ́ gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni? Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí wá láti ọ̀dọ̀ àwọn akéde láti nǹkan bí orílẹ̀-èdè ogún [20].
2. Bí ẹnì kan bá sọ pé òun kò gbà pé Ọlọ́run wà, kí ló yẹ ká wádìí, kí sì nìdí?
2 Àwọn Tí Kò Gbà Pé Ọlọ́run Wà: Bí ẹnì kan bá sọ pé òun kò gbà pé Ọlọ́run wà, ó máa dáa ká béèrè ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀. Ṣé torí pé ó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ ni? Ṣé ìwà àìṣòótọ́ tó pọ̀ láyé àbí ìwà àgàbàgebè tó kúnnú ẹ̀sìn ni kò jẹ́ kó gbà pé Ọlọ́run wà? Ṣé ibi tí wọn ò ti gbà pé Ọlọ́rùn wà ló gbé dàgbà? Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé onítọ̀hún kò yarí kanlẹ̀ pé kò sí Ọlọ́run, àmọ́ kò tíì rídìí tó fi yẹ kó gba Ọlọ́run gbọ́. Ọ̀pọ̀ akéde ti rí i pé táwọn bá bi ẹnì kan pé, “Ṣé bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára rẹ látilẹ̀ nìyẹn?” ó máa ń mú kí ẹni náà ṣàlàyé ara rẹ̀. Tẹ́tí sílẹ̀, má sì dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Tá a bá lóye ìdí tí ẹni náà kò fi gbà pé Ọlọ́run wà, a máa mọ bó ṣe yẹ ká fèsì àti ìwé tó yẹ ká fún un.—Òwe 18:13.
3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹnì kan àti ohun tó gbà gbọ́?
3 Tó o bá ń fèsì, ṣọ́ra kí onítọ̀hún má bàa rò pé ò ń gbá èrò òun dànù. Akéde kan láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dábàá pé: “Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn torí pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí wọ́n máa gbà gbọ́. Dípò kó o máa bá wọn jiyàn kó o lè borí wọn, ó máa dáa kó o bi wọ́n ní ìbéèrè tó máa mú kí wọ́n ronú, kí wọ́n lè fúnra wọn ṣèpinnu.” Lẹ́yìn tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan bá ti gbọ́ ohun tí onílé fẹ́ sọ, ó sábà máa ń béèrè pé, “Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́?”
4. Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹlẹ́sìn Búdà lọ́wọ́?
4 Ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà. Àwọn akéde kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa ń fẹ́ lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Lasting Peace and Happiness—How to Find Them tí wọ́n bá ń wàásù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jíròrò àwọn ìpínrọ̀ tá a fi nasẹ̀ ìwé náà, wọ́n á wá jíròrò apá tí àkòrí rẹ̀ sọ pé: “Is There Really a Most High Creator?” Lẹ́yìn náà, wọ́n á jíròrò apá tó sọ pé, “A Guidebook for the Blessing of All Mankind.” Wọ́n lè wá fún onílé náà ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, wọ́n á sì sọ fún un pé: “Bí o kò bá tiẹ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, o ṣì máa jàǹfààní tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nítorí wàá rí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó wúlò nínú rẹ̀.” Aṣáájú-ọ̀nà kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń sìn ní ibi tí àwọn ará Ṣáínà pọ̀ sí sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló fẹ́ràn láti máa kàwé. Nítorí náà, wọ́n ti sábà máa ń ka ìwé náà tán ká tó pa dà wá. Síbẹ̀ wọ́n lè máà rídìí tó fi yẹ káwọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí náà, mo máa ń fẹ́ fún wọn ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀ nígbà àkọ́kọ́ tí mo bá lọ sọ́dọ̀ wọn torí a kọ ìwé náà lọ́nà tó máa fi wu àwọn èèyàn láti jíròrò rẹ̀.” Alábòójútó àyíká kan tó ń sìn ní àyíká kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Ṣáínà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ròyìn pé ó ṣeé ṣe láti fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni lọni nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́, ó máa dáa kéèyàn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ láti orí 2 tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, dípò kéèyàn bẹ̀rẹ̀ ní orí 1 tó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run.
5. Kí nìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì?
5 Ó máa ń ṣe díẹ̀ káwọn èèyàn kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, torí náà a gbọ́dọ̀ mú sùúrù fún wọn. Ìjíròrò wa àkọ́kọ́ lè máà tó láti jẹ́ kí ẹnì kan gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà. Àmọ́, tó bá yá ó lè wá gbà pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run kan wà lóòótọ́, tàbí kó sọ pé òun ti wá rí ìdí tí àwọn kàn fi gbà pé Ọlọ́run wà.
6. Kí ló lè fà á tí àwọn kan ò fi nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì?
6 Àwọn Tí Kò Nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì Tàbí Tí Wọn Ò Fọkàn Tán An: Àmọ́, nígbà míì ẹnì kan lè sọ pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run wà àmọ́ kó máà fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ torí kò gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Ó lè jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí àwọn Kristẹni ò fi bẹ́ẹ̀ sí ni onítọ̀hún ń gbé, ó sì lè máa rò pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni Bíbélì wà fún. Tàbí kó jẹ́ pé àwọn ilẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ti ń pe ara wọn ní Kristẹni àmọ́ tí wọ́n kò fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn ló ń gbé, ó sì lè ronú pé kò sí àǹfààní kankan tí Bíbélì máa ṣe fún òun. Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, kí wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tó bá yá?
7. Ọ̀nà wo ló sábà máa ń dára gan-an láti gbà mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì?
7 Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Gíríìsì sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ran àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì lọ́wọ́ ni pé kéèyàn ka ohun tó wà nínú Bíbélì ọ̀hún fúnra ẹ̀ fún wọn kí wọ́n lè mọ ohun tó sọ. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ti rí i pé ọ̀rọ̀ Bíbélì máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ju ohunkóhun táwọn lè sọ. (Héb. 4:12) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì ló tó bẹ̀rẹ̀ sí í wù wọ́n láti ka Bíbélì.” Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ló máa ń fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀mí àti ikú. Bákan náà, wọ́n máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ìlérí Bíbélì nípa ayé kan tí ìṣòro kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ ò ti ní sí mọ́.” Tí àwọn akéde bá sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣòro táwọn èèyàn máa ń fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, èyí sábà máa ń fún wọn láǹfààní láti fi ohun tí Bíbélì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro náà hàn wọ́n.
8. Kí la lè sọ fún àwọn tí wọ́n ní èrò tí kò tọ́ nípa Bíbélì torí ìwà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
8 Tó bá jẹ́ nítorí ìwà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ẹnì kan ò ṣe nífẹ̀ẹ́ Bíbélì, jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò lóye ohun tó wà nínú Bíbélì, ẹ̀kọ́ wọn ò sì bá ti Bíbélì mu. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan pé ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kọ́ ló ni Bíbélì.” Wọ́n sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí apá 4 ìwé pẹlẹbẹ náà, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? torí pé ó ṣàlàyé bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ti gbìyànjú láti ṣe àdàlù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ pa á rẹ́. Aṣáájú-ọ̀nà kan ní orílẹ̀-èdè Brazil máa ń sọ fáwọn èèyàn pé: “O ò ṣe ṣèwádìí púpọ̀ sí i nípa ohun tó wà nínú Bíbélì? Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò sí nínú ẹ̀sìn kankan ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí ẹ̀tanú. Ohun tó o máa kọ́ lè yà ẹ́ lẹ́nu.”
9. Kí nìdí tá a kò fi ni jẹ́ kó sú wa tí ẹnì kan ò bá kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni?
9 Jèhófà ń wo ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan. (1 Sám. 16:7; Òwe 21:2) Ó ń fa àwọn tí wọ́n ní ọkàn títọ́ wá sínú ìjọsìn tòótọ́. (Jòh. 6:44) Ọ̀pọ̀ lára wọn kò gbọ́ nípa Ọlọ́run rí tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ mọ Bíbélì. Iṣẹ́ ìwàásù wa ń mú ká lè “gba [irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀] là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Nítorí náà, bí ẹnì kan ò bá kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Lo ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lédè rẹ láti mú kí onítọ̀hún fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Tó bá yá, ó ṣeé ṣe kó o lè darí ìjíròrò yín síbi tẹ́ ẹ fi máa lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Ohun tó o lè ṣe bí onílé bá sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà:
• Bi í pé, “Ṣé bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa ń rí lára rẹ nìyí látilẹ̀?” kó o lè mọ ohun tó fà á tó fi sọ bẹ́ẹ̀.
• Tó bá jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà, lo ìwé náà Lasting Peace and Happiness—How to Find Them, ojú ìwé 9 sí 12.
• Bó bá gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, o lè lo àwọn ìtẹ̀jáde yìí:
“Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó máa ń jáde nínú Jí!
Fídíò The Wonders of Creation Reveal God’s Glory
Àwọn ìwé pẹlẹbẹ A Satisfying Life—How to Attain It, apá 4; Was Life Created?; àti The Origin of Life—Five Questions Worth Asking
• Tó bá jẹ́ pé ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà tó ń jẹ aráyé ló mú kó má gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, àwọn ìwé tó lè ṣèrànwọ́ nìyí:
Ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You?, orí 10
Ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, apá 6, àti Ki Ni Ète Igbesi-Aye?, apá 6
• Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí onílé kan bá ti ń yí èrò rẹ̀ pa dà pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run wà ni kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ó máa ṣàǹfààní tó o bá bẹ̀rẹ̀ láti orí 2 tàbí orí míì tó bá a mu.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ohun tó o lè ṣe tí onílé kò bá gba Bíbélì gbọ́:
• Ẹ jíròrò orí 17 àti 18 nínú ìwé náà Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?
• Tó bá jẹ́ Híńdù, lo ìwé pẹlẹbẹ náà Why Should We Worship God in Love and Truth?
• Tó bá jẹ́ Júù, lo ìwé pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War?, ojú ìwé 3 sí 11.
• Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀ téèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Àwọn ìwé tó o lè lò láti jẹ́ kẹ́nì kan rí bí Bíbélì ṣe wúlò tó ni:
Ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ́ “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” tó wà nínú Jí!
Fídíò The Bible—Its Power in Your Life
Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Ẹ̀kọ́ 9 àti 11; Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 22 sí 26; àti A Satisfying Life—How to Attain It, apá 2
Tó bá jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà, lo ìwé pẹlẹbẹ náà The Pathway to Peace and Happiness, ojú ìwé 3 sí 7.
Tó bá jẹ́ Mùsùlùmí, ẹ lo ìwé pẹlẹbẹ náà Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀, apá 3.
Tó o bá ń wàásù ládùúgbò tó jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì, ó lè bọ́gbọ́n mu kó o má sọ ibi tó o ti mú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó ò ń sọ fún wọn títí tó o fi máa pa dà lọ síbẹ̀ nígbà mélòó kan.
• Ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ṣe ní ìmúṣẹ. Àwọn ìtẹ̀jáde tó o lè lò ni:
Fídíò náà, The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy
Ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 27 sí 29
• Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí onítọ̀hún bá ti béèrè nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí àwọn kókó kan ni kó o bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Bí onílé bá sọ pé: “Mi ò gbà pé Ọlọ́run wà,” o lè sọ pé:
• “Ṣé mo lè ṣàlàyé fún ẹ ní ṣókí ohun tó jẹ́ kó dá mi lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà?” Lẹ́yìn náà, kó o jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Reasoning lójú ìwé 84 sí 86 pẹ̀lú rẹ̀, tàbí kó o sọ fún un pé wàá mú ìwé kan tí ìwọ náà gbádùn wá fún un.
• “Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, irú ẹni wo lo máa fẹ́ kó jẹ́?” Ọ̀pọ̀ àwọn onílé ló máa ń dáhùn pé àwọn máa fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, onídàájọ́ òdodo, tó jẹ́ aláàánú tí kì í sì í ṣègbè. Fi hàn án nínú Bíbélì pé Ọlọ́run ní àwọn ìwà dáadáa yìí. (O tiẹ̀ lè lo orí 1 ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó o bẹ̀rẹ̀ láti ìpínrọ̀ 6.)
Bí onílé bá sọ pé: “Mi ò gba Bíbélì gbọ́,” o lè sọ pé:
• “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ bẹ́ẹ̀. Àwọn kan rò pé ohun tí Bíbélì sọ kò bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu tàbí pé àwọn ìlànà Bíbélì kò ṣeé tẹ̀ lé. Ǹjẹ́ o ti ka Bíbélì rí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà ní ojú ìwé 3 ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn hàn án kí o sì fún un.] Ọ̀pọ̀ ò ka Bíbélì mọ́ torí pé àwọn ẹ̀sìn ti lọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ lójú. Nígbà míì tí mo bá pa dà wá màá sọ̀rọ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà lójú ìwé 4 àti 5.”
• “Ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló máa sọ ohun tó o sọ yìí. Ṣé mo lè fi ohun kan tó wọ̀ mí lọ́kàn nípa Bíbélì hàn ẹ́? [Ka Jóòbù 26:7 tàbí Aísáyà 40:22, tó fi hàn pé ohun tí Bíbélì sọ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu.] Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó lè ran ìdílé lọ́wọ́ tún wà nínú Bíbélì. Tí mo bá pa dà wá, màá fẹ́ fi àpẹẹrẹ kan hàn ẹ́.”
• “O ṣé tó o sọ èrò ẹ fún mi. Tí Ọlọ́run bá kọ ìwé kan fún àwọn èèyàn, kí lo rò pé ó máa wà nínú ìwé náà?” Lẹ́yìn náà fi ibi tó dáhùn ìbéèrè onítọ̀hún hàn án nínú Bíbélì.