Ọ̀kan Lára Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ni kò mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, ní pàtàkì àwọn tí kì í ṣe oníṣọ́ọ̀ṣì. Tó bá jẹ́ pé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ni àwọn akéde kan ń lò láti kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, wọ́n tún máa ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè ní òye díẹ̀ nípa àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lo apá 1 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà nígbà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ orí 3 nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Lẹ́yìn náà, ó máa ń jíròrò apá kọ̀ọ̀kan lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́. Ǹjẹ́ ò ń kọ́ ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ Bíbélì tàbí tí kò tiẹ̀ mọ Bíbélì rárá lẹ́kọ̀ọ́? Kó o lè ràn án lọ́wọ́ láti ‘mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà,’ ronú nípa lílo àwọn ìsọfúnni látinú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? láfikún sí àwọn ohun tí o kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.—2 Tím. 3:15.