ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp16 No. 1 ojú ìwé 11-14
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌṢÒRO BÍ WỌ́N ṢE TỌ́ Ẹ DÀGBÀ
  • ỌLỌ́RUN FẸ́ RÀN WÁ LỌ́WỌ́
  • OHUN MẸ́TA TÓ LÈ MÚ KÁ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN
  • ÌGBÀ TÍ GBOGBO ÈÈYÀN MÁA NÍ ÌFỌ̀KÀNBALẸ̀
  • Ìgbésí Ayé Tó Ní Ààbò Pípẹ́ Títí
    Jí!—1998
  • Bí Kò Bá Nífẹ̀ẹ́ Mi Bí Mo Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ Ńkọ́?
    Jí!—1998
  • Fọkàn Balẹ̀, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
wp16 No. 1 ojú ìwé 11-14
Bàbá kan gbé ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré dání

Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé O Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan

ÀWỌN ọmọ ìkókó máa ń nílò kí àwọn òbí wọn dáàbò bò wọ́n torí pé wọn kò lè dáàbò bo ara wọn. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, ńṣe ni àwọn èèyàn tá a bá rí máa ń ga gògòrò lójú wa. Ẹ̀rù máa ń bà wá tá a bá rí wọn àyàfi tí àwọn òbí wa bá wà nítòsí. Ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ tí bàbá tàbí ìyá wa bá gbé wa lọ́wọ́.

Bá a ṣe ń dàgbà sí i, ara máa ń tù wá tí àwọn òbí wa bá ń fi ìfẹ́ hàn sí wa. Bá a bá sì rí bí àwọn òbí wa ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ọkàn wa máa ń balẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá. Bí wọ́n bá tún wá ń gbóríyìn fún wa, ńṣe ni inú wa máa ń dùn pé à ń ṣe dáadáa.

Tá a bá tún dàgbà díẹ̀ sí i, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tá a bá ní máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Ara máa ń tù wá tá a bá wà láàárín wọn, wọ́n sì máa ń mú kí iléèwé gbádùn mọ́ni.

Irú àwọn ipò tó yẹ kí èèyàn dàgbà sí nìyẹn, àmọ́ ká sòótọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ni kò gbádùn irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Àwọn òbí kan kò rí tàwọn ọmọ wọn rò, àwọn ọmọ míì ò sì ní ọ̀rẹ́ gidi. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Melissaa sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá rí fọ́tò àwọn ìdílé tó ń gbádùn ara wọn, mo máa ń rò ó lọ́kàn ara mi pé, ‘Báwo ni ì bá ṣe rí ká ní èmi náà gbádùn irú èyí ní kékeré.’” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ní irú èrò yìí.

ÌṢÒRO BÍ WỌ́N ṢE TỌ́ Ẹ DÀGBÀ

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀rù sábà máa ń bà ẹ́ nígbà tó o ṣì kéré. Bóyá torí pé àwọn òbí rẹ kò fi ìfẹ́ hàn sí ẹ dáadáa tàbí kó o rántí bí àwọn òbí rẹ ṣe máa ń bá ara wọn jà títí tó fi yọrí sí pé wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé torí tìẹ ni wọ́n ṣe kọ ara wọn sílẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn òbí rẹ máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹ tàbí kó máa lù ẹ́ nílùkulù.

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ọmọ tí wọ́n bá hùwà sí lọ́nà yìí? Àwọn kan tí kò tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró tàbí kí wọ́n máa mu ọtí ní àmuyíràá. Àwọn míì máa ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́ kí wọ́n lè rẹ́ni fojú jọ. Àwọn míì sì lè lọ wá àfẹ́sọ́nà kí wọ́n ṣáà lè rẹ́ni tó máa fìfẹ́ hàn sí wọn. Àmọ́ kì í pẹ́ tí wọ́n fi máa ń tú ká, èyí sì máa ń mú kí ipò wọn burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn ọmọ míì wà tí kì í lọ́wọ́ sí irú àwọn nǹkan wọ̀nyí, síbẹ̀ ó ṣì máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ana sọ́ pé: “Ó máa ń ṣe mi bíi pé mi ò wúlò fún nǹkan kan torí ohun tí ìyá mi máa ń sọ fún mi ní gbogbo ìgbà nìyẹn. Mi ò rántí ọjọ́ tí wọ́n gbóríyìn fún mi rí tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ṣaájò mi.”

Bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà nìkan kọ́ ló máa ń mú kó dà bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Nígbà míì, ó lè jẹ́ bí ọkọ tàbí aya wa ṣe já wa jù sílẹ̀ tàbí àwọn ìṣòro tá a máa ń ní tí ara bá ti ń di ara àgbà. Ó sì lè jẹ́ ìrísí wa ló mú ká ní irú èrò yìí. Ohun yòówù kó jẹ́, èrò pé a ò já mọ́ nǹkan kan lè mú ká máa kárí sọ, ó sì lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú àwọn míì jẹ́. Kí la lè ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé a kò já mọ́ nǹkan kan?

ỌLỌ́RUN FẸ́ RÀN WÁ LỌ́WỌ́

Ó yẹ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lágbára láti ràn wá lọ́wọ́, ó sì wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ fún wa pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 41:10, 13) Ó mà tuni lára o láti mọ̀ pé Ọlọ́run ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́! Torí náà, kò sí ìdí fún wa láti máa bẹ̀rù!

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tí wọ́n ṣàníyàn àmọ́ tí wọ́n jẹ́ kí Ọlọ́run ràn àwọn lọ́wọ́. Hánà tó jẹ́ ìyá Sámúẹ́lì fìgbà kan rí ronú pé òun ò wúlò tórí kò rí ọmọ bí. Orogún rẹ̀ tiẹ̀ máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé àgàn ni. Fún ìdí èyí, Hánà kò lè jẹun, ó sì máa ń wa ẹkún mu. (1 Sámúẹ́lì 1:6, 8) Àmọ́ ara tù ú lẹ́yìn tó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run, kò sì kárí sọ mọ́.—1 Sámúẹ́lì 1:18.

Àwọn ìgbà kan wà tí ẹ̀rù ba onísáàmù náà Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Sọ́ọ̀lù Ọba fi lépa ẹ̀mí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì yè bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á, ńṣe làwọn ìṣòro yìí kó ìdààmú bá a. (Sáàmù 55:3-5; 69:1) Láìka èyí sí, Dáfídì sọ pé: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.”—Sáàmù 4:8.

Hánà àti Dáfídì sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn fún Jèhófà, wọ́n sì rí i pé Jèhófà dúró ti àwọn. (Sáàmù 55:22) Báwo ni àwa náà ṣe lè ṣe bíi tiwọn lóde òní?

OHUN MẸ́TA TÓ LÈ MÚ KÁ NÍ ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

1. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́.

Ọkùnrin kan ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ń kà nínú Bíbélì

Jésù rọ̀ wá pé ká sapá láti mọ Bàbá òun tó jẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” (Jòhánù 17:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Kódà, Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.

Bá a ṣe mọ̀ pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó bìkítà fún wa máa ń jẹ́ ká lè gbé àníyàn kúrò lọ́kàn wa. Òótọ́ ni pé ó máa ń gba àkókò kí ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Ọlọ́run tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ ti rí i pé bí àwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn àwọn máa ń balẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Caroline sọ pé: “Nígbà tí mo fi Jèhófà ṣe Bàbá mi, mo rí i pé mo lè sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún un. Èyí sì mú kí ara tù mí!”

Obìnrin míì tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Jèhófà ló fi mí lọ́kàn balẹ̀ nígbà táwọn òbí mi pa mí tì. Mo máa ń bá a sọ̀rọ̀, mo sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ìṣòro mi. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.”b

2. Sún mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Àwọn kan ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba

Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ka ara wọn sí ọmọ ìyá kan náà. Ó sọ fún wọn pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) Ó fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bá ara wọn lò bí ọmọ ìyá kan náà.—Mátíù 12:48-50; Jòhánù 13:35.

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe bí ọmọ ìyá, èyí sì máa ń mú kí ara tu gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. (Hébérù 10:24, 25) Ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe ló máa ń dà bíi pé wọ́n da omi tútù sí àwọn lọ́kàn torí ọkàn àwọn máa ń fúyẹ́.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Eva sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ àtàtà kan nínú ìjọ tó mọ ohun tí mò ń bá yí. Ó máa ń tẹ́tí sí mi, ó máa ka Bíbélì fún mi, a sì jọ máa ń gbàdúrà pa pọ̀. Ó máa ń rí i dájú pé mi ò dá wà. Bá a ṣe jọ máa ń sọ̀rọ̀ máa ń jẹ́ kí ọkàn mi fúyẹ́. Bó ṣe dúró tì mí jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.” Rachel náà sọ pé: “Mo rí àwọn tó dà bíi ‘Bàbá àti ìyá’ fún mi nínú ìjọ. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi dénú, wọ́n sì mú kí ara tù mí.”

3. Máa fi ìfẹ́ àti inúure hàn sí àwọn míì.

Bá a bá ń fi ìfẹ́ àti inúure hàn sáwọn míì, ńṣe ló máa jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn míì túbọ̀ gún. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Òótọ́ kan sì ni pé bá a bá ṣe ń fìfẹ́ hàn sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èèyàn á túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sí wa. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.”—Lúùkù 6:38.

Tá a bá ń fìfẹ́ hàn, táwọn èèyàn sì ń fìfẹ́ hàn sí wa, ọkàn wa máa túbọ̀ balẹ̀. Ó ṣe tán Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Obìnrin kan tó ń jẹ́ María sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn èrò òdì kan tí mo ní nípa ara mi kì í ṣe òótọ́. Àmọ́ èrò burúkú yẹn máa ń kúrò lọ́kàn tí mo bá gbé ìṣòro tèmi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí mo sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ṣe nǹkan kan fáwọn míì.”

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ran bàbá àgbàlagbà kan tó ń fi ọ̀pá rìn lọ́wọ́

ÌGBÀ TÍ GBOGBO ÈÈYÀN MÁA NÍ ÌFỌ̀KÀNBALẸ̀

Àwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn yìí kì í ṣe ‘oògùn ajẹ́bíidán’ tó máa mú ìtura wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí gbogbo àníyàn wa sì máa fò lọ. Àmọ́ tá a bá fi wọ́n sílò, ó lè mú kí ara tù wá. Caroline sọ pé: “Ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ti túbọ̀ níyì lójú ara mi. Mo mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, mo sì ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó máa ń múnú mi dùn.” Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Rachel náà nìyẹn, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìbànújẹ́ máa ń dorí mi kodò. Àmọ́ mo láwọn arákùnrin àti arábìnrin tó máa ń fún mi ní ìmọ̀ràn, àwọn wọ̀nyí máa ń jẹ́ kí n gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo lè bá Bàbá mi ọ̀run sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Ìyẹn nìkan lásán máa ń mú kára tù mí.”

Bíbélì sọ pé ayé tuntun kan ń bọ̀ níbi tí ọkàn gbogbo wa ti máa balẹ̀

Láìpẹ́, kò sẹ́ni táá máa ṣàníyàn mọ́. Bíbélì sọ pé ayé tuntun kan ń bọ̀ níbi tí ọkàn gbogbo wa ti máa balẹ̀. Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4) Tó bá dìgbà yẹn, kò sẹ́ni tó máa ṣẹ̀rù bà wá, kò sì sẹ́ni tó máa ṣe wá ní jàǹbá. Kódà, àwọn àjálù tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ‘kì yóò wá sí ìrántí.’ (Aísáyà 65:17, 25) Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi máa mú kí “òdodo tòótọ́” gbilẹ̀. Àbájáde rẹ̀ sì ni pé ‘ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò máa wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’—Aísáyà 32:17.

a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn tó bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

Àwọn Tó Rò Pé Àwọn Kò Já Mọ́ Nǹkan Kan

“Nígbà tí bàbá mi tó jẹ́ ọ̀mùtí bá fàbínú yọ, ńṣe lojú rẹ̀ máa ń le koko. Yóò wá máa bú bí ìkòkò tó ń halẹ̀ mọ ẹranko tó fẹ́ pa jẹ. Èmi á sì máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí ọmọ àgùntàn tí ẹrù ń bà, màá máa pa kúbẹ́kúbẹ́ kó má baà rí mi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ lọ̀rọ̀ mi máa ń rí báyìí.”—Ìṣòro tí Caroline ní nígbà tó wà lọ́mọdé.

“Ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sẹ́ni tí mo lè finú hàn. Ó dà bí ìgbà tí mo sọnù sórí òkè kan, tí mo sì ń pariwo pé kẹ́nì kan gbà mí, àmọ́ kò sẹ́nì kankan tó gbọ́ igbe mi, mi ò rẹ́nì kankan tó lè ràn mí lọ́wọ́.”—Eva, obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ̀ sílẹ̀.

“Bàbá mi sábà máa ń jágbe mọ́ mi pé, ‘Ọmọ burúkú ni ẹ́. Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ràn ẹ láé!’ Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo máa fi ń sọ fún ara mi pé mi ò kì í ṣe ọmọ burúkú àti pé àwọn míì fẹ́ràn mi dáadáa. Mo wá dà bí ọmọ ajá tó ká ìrù rẹ̀ sínú, mò ń wá ẹni tó máa tù mí nínú, àmọ́ mi ò rẹ́nì kankan.”—Mark, tí bàbá rẹ̀ máa ń bà jẹ́ lójú àwọn míì.

“Nígbà míì tí mo bá rí obìnrin tó rẹwà, mo máa ń fi wé òdòdó rírẹwà tí àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbìn sílé. Àmọ́ ńṣe ni èmi dà bí koríko kan tí kò wúlò fún ẹnikẹ́ni.”—María, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ka ara rẹ̀ sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá péré, àwọn òbí mi kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì, wọ́n sì ní kí n máa tọ́jú àwọn àbúrò mi méjì. Ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sẹ́ni tó rí tèmi rò. Mo fẹ́ kí ẹnì kan máa tọ́jú èmi náà, kó sì máa sọ fún mi pé mò ń ṣe dáadáa. Àmọ́, ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé mo sọnù sínú igbó kìjikìji kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń forí rọ́ ọ nìṣó, síbẹ̀ mo ṣì ń wọ́nà láti jáde nínú ipò tó dà bí igbó kìjikìji náà. Mo fẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ kí n sì láyọ̀.”—Rachel, ọmọbìnrin kan tí àwọn òbí rẹ̀ wáṣẹ́ lọ sílẹ̀ òkèèrè.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́