Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 30, 2012. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ March 5 sí April 30, 2012, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó wà nínú ìwé Jeremáyà? [Mar. 5, w07 3/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 2]
2. Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà dá wa nídè nígbà inúnibíni lóde òní? (Jer. 1:8) [Mar. 5, w05 12/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 18]
3. Ìgbà wo ni àwọn ẹni àmì òróró pa dà sí “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,” ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ṣe bẹ́ẹ̀? (Jer. 6:16) [Mar. 12, w05 11/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 12]
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ‘básámù wà ní Gílíádì’ lóde òní? (Jer. 8:22) [Mar. 19, w10 6/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4]
5. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà “pèrò dà” lẹ́yìn tó bá ti kéde ìdájọ́ rẹ̀? (Jer. 18:7, 8) [Apr. 2, jr ojú ìwé 151, àpótí]
6. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà tan Jeremáyà, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ nínú èyí? (Jer. 20:7) [Apr. 2, jr ojú ìwé 36 ìpínrọ̀ 8]
7. Ǹjẹ́ àṣẹ tó wà nínú ìwé Jeremáyà 22:30 fagi lé ẹ̀tọ́ Jésù Kristi láti gorí ìtẹ́ Dáfídì? (Mát. 1:1, 11) [Apr. 9, w07 3/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 9]
8. Kí nìdí tó fi tọ̀nà bí Jèhófà ti sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì pé, ‘mo fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́’? (Jer. 31:3) [Apr. 23, jr ojú ìwé 142 sí 145 ìpínrọ̀ 8 sí 11]
9. Báwo ni a ṣe lè kọ òfin Ọlọ́run sínú ọkàn ẹnì kan? (Jer. 31:33) [Apr. 23, w07 3/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 2]
10. Kí ni ìwé àdéhùn méjì tí Jeremáyà ṣe nítorí ọjà kan ṣoṣo tó rà wà fún? (Jer. 32:10-15) [Apr. 30, w07 3/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3]